Ohun tawọn araalu ba n fẹ ni ki egbe oselu APC se___Tejuoso

Spread the love

Aṣofin ni Dokita Ọlanrewaju Tẹjuoṣo nile igbimọ aṣofin agba l’Abuja. Aarin-Gbungbun ipinlẹ Ogun lo n ṣoju fun lọhun-un, oun ni alaga igbimọ to n ri si ilera nile igbimọ  naa, ọmọ Kabiyesi Adedapọ Tẹjuoṣo, Ọṣilẹ-Ẹgba, si ni.

 Ọsan ọjọ Satide ijẹrin yii lo dahun awọn ibeere kan ti akọroyin ALAROYE nipinlẹ Ogun, ADEFUNKẸ ADEBIYI, bi i, bayii lo ṣe lọ.

ALAROYE: Ibo ipinlẹ Ọṣun to kọja yii mu ẹgbẹ APC lomi pupọ ki wọn too gbegba oroke, njẹ ko ni i ṣoro lọdun to n bọ bayii?

Sẹnẹtọ Tẹjuoṣo: Ọlọrun maa n ran awọn eeyan lọwọ lati jẹ ki wọn ri nnkan tọka si. Eyi to ṣẹlẹ yii ko ṣẹṣẹ niidi a n ka bibeli tabi kuraani lati mọ idi to fi ri bẹẹ, a ti mọ ohun to fa a.

To ba jẹ bi wọn ṣẹ ṣe l’Ọṣun yii ni wọn tun ṣe lawọn ipinlẹ mi-in, a jẹ pe ki i ṣe ohun tawọn eeyan n fẹ ni ẹgbẹ APC n ṣe. Ti wọn fẹẹ maa gbe ẹnikan le awọn eeyan lori, ti wọn ko jẹ ki aṣẹ mejọriti (ọpọ eeyan) ṣẹ, a dẹ ri i pe nnkan to ṣẹlẹ l’Ọṣun niyẹn.

Nitori naa, APC, ohun tawọn araalu ba n fẹ ni ki wọn ṣe.

ALAROYE: Gẹgẹ bii ọmọ ile igbimọ aṣofin to n ṣoju Aarin- Gbungbun ipinlẹ Ogun l’Abuja, ki lẹ ti ṣe fawọn eeyan ipinlẹ Ogun?

Sẹnẹtọ Tẹjuoṣo:Ki n too di sẹnetọ rara ni mo ti leto nilẹ ti mo fẹẹ maa ṣe fun wọn, mo dẹ ti ri i pe awọn to ṣiwaju mi ti gbe oriṣiiriṣii eto kalẹ ti wọn ko yanju ẹ. Nigba ti mo ti mọ awọn ohun to n jẹ wọn niya bii ina mọnamọna, omi ẹrọ atawọn nnkan bẹẹ yẹn, awọn nnkan bẹẹ naa la n gbe kalẹ bii ofin. Aimọye transifọma (ẹrọ apinnaka) ti mo ra, aimọye ẹrọ omi.

Mo tun n ṣagbekalẹ awọn ofin to le jẹ ki wọn gbowo jade fun ileeṣẹ ilera, ti owo oogun ati eyi ta a maa fi sanwo awọn oṣiṣẹ eto ilera yoo fi maa jade.

Ileewosan alabọọde lo yẹ kawọn eeyan maa lọ ju, ki i ṣe gbogbo ẹ naa ni jẹnẹra. Ṣugbọn nigba ti ko soogun nibẹ, ti ko si awọn oṣiṣẹ, lawọn eeyan ṣe n lọ si jẹnẹra nitori iba lasan.

Gbogbo ẹ ni mo n fi owo temi paapaa gbọ nitori awọn eeyan mi.

ALAROYE: Bo ṣe waa jẹ pe owo ara yin lẹ n na lọpọ igba gẹgẹ bi ẹ ṣe wi yii, ki lo de tẹ ẹ tun fẹẹ dupo aṣofin yii lẹẹkan si i?

Sẹnetọ Tẹjuoṣo: Nnkan to ṣe wu mi i lọ lẹẹkeji ni pe mo ri i pe awọn ẹgbẹ mi ti wọn wa nibẹ tẹlẹ ti wọn n ṣe daadaa, awọn ti wọn lọ lẹẹkeji ni.

Iru emi bayii nisinyii, igba ti mo kọkọ debẹ, ọdun meji ni mo fi kọ bi gbogbo nnkan ṣe n lọ, igba to di ọdun kẹta la ṣẹṣẹ mọ bi wọn ṣe n ṣe e.

Iyẹn lo ṣe jẹ pe awọn ipinlẹ kan wa to jẹ pe ti wọn ba fẹẹ gba nnkan kan lọwọ ijọba, kiakia ni wọn maa n ri i gba, nitori pe awọn sẹnetọ wọn ki i ṣe ṣẹṣẹ de, saa keji ni wọn n ṣe lọ.

Ohun to n jẹ ki ilu Eko maa tẹ siwaju niyẹn, ẹni to ba wa nibẹ naa ni yoo maa ṣe ẹ lọ. Nnkan tipinlẹ Ogun ko dẹ ṣe tete nilọsiwaju niyẹn.

Ti emi ba kuro nibẹ lọdun to n bọ, tẹlomi-in ba gba a, o tun maa ṣẹṣẹ bẹrẹ si i kọṣẹ ni, ko ti i mọ bi ilẹ ṣe ri, o ṣẹṣẹ maa tun bẹrẹ eto tiẹ ni, ohun ti mo ṣe fẹẹ pada lọ lẹẹkeji niyẹn.

Awọn to mọyi  iṣẹ ti mo n ṣe gẹgẹ bii dokita nibẹ n dupẹ lọwọ mi ni, wọn o fẹ ki n lọ. Unicef kọ lẹta si mi, wọn dupẹ, bẹẹ naa ni Bill Gate. Ṣe nigba ti wọn ti waa mọ mi yii ni ki n waa fi i ṣilẹ, afi ki n lọ lẹẹkan si i.

ALAROYE: Ṣugbọn Gomina Ibikunle Amosun ti loun nifẹẹ si ẹkun Aarin-Gbungbun Ogun tẹyin naa fẹẹ lọ fun yii bayii, ṣe ẹ ṣẹtan lati yọnda ẹ fun gomina?

Sẹnetọ Tẹjuoṣo: Ọga mi ni Amosun. Mo ti sọ ọ tẹlẹ, mo dẹ tun n tun un sọ ọ. Mo ni ti wọn ba pe mi, ti wọn lawọn fẹẹ dije, pe ki n fi i silẹ fawọn, mo maa fi i silẹ, gẹgẹ bii ọga si ọmọọṣẹ.

ALAROYE: Ita gbangba ni gomina ti kede ero wọn lati dupo aṣofin lẹẹkan si i, ọjọ naa ni awọn ọmọ ẹgbẹ kan sọ pe ki ẹ kuro nibi ipade to waye n’Ibara naa. Ẹ ba wa ṣalaye diẹ nipa ohun to ṣẹlẹ lọjọ yẹn.

Sẹnetọ Tẹjuoṣo: Ita ni gomina ti kede loootọ, ṣugbọn ko ri bakan lara mi, ohun t’Ọlọrun ba fẹ ni mo maa ṣe.

T’Ọlọrun ba fun mi lanfaani lati wọle, deede ni, to ba dẹ jẹ nidakeji naa ni, ko si wahala.

Lọjọ ti wọn ni ki n jade nipade, awọn kan ninu ẹgbẹ lo kan fẹẹ huwa arekereke, nitori mi o kọwe si wọn pe mo kuro ninu  ẹgbẹ. Ewo waa ni ki wọn maa sọ pe ki n jade.

Mo ti sọ lori tẹlifiṣan pe mo ti pada sinu APC, Buhari to jẹ ọga gbogbo wa pata fa mi lọwọ soke, gbogbo aye lo ri i. Ewo waa ni lẹyin tọgaa ti sọrọ loke lọhun-un, ewo ni kọmọ iṣẹ nisalẹ maa tun paṣẹ.

Wọn ni mo kuro ninu ẹgbẹ, mo ni iwe ti mo kọ si yin pe mo kuro da, ẹ mu un wa, wọn ko riwee kankan mu wa. Ohun ti mo ṣe sọ pe wọn n huwa arekereke niyẹn.

ALAROYE: Ki lo de tẹyin naa fi kọkọ sọ pe ẹ o ṣe APC mọ?

Sẹnetọ Tẹjuoṣo: Inu lo bi mi. Mo pe awọn alaga ijọba ibilẹ mọkandinlogun ki wọn waa ba mi ṣepade, wọn dẹ wa, a dẹ ṣepade ọhun, a bara wa sootọ ọrọ.

Ọjọ keji ni wọn pe wọn lati ipinlẹ Ogun nibi ti wọn ba wọn ja, pe wọn ṣe maa waa ba mi ṣepade lai gbaṣẹ. Ohun lo bi mi ninu pe emi sẹnetọ to ṣi wa lori aleefa ko tun le ṣepade pẹlu awọn alaga kansu mọ ni, to jẹ pe bii gomina lemi gan-an ri laarin gbungbun ti mo n ṣoju fun, ohun to bi mi ninu nigba yẹn niyẹn ti mo fi ni mi o ṣẹgbẹ APC mọ.

Nnkan ti wọn ṣe fun mi pọ gan-an o, mo kan sọ diẹ nibẹ ni.

Igba mi-in wa ti tẹlifiṣan ipinlẹ yii maa ṣe ifọrọwanilẹnuwo fun mi laarin awọn eeyan mi-in, to ba dalẹ ti wọn fẹẹ sọ iroyin yẹn, wọn aa ti ge ibi ti mo wa kuro.

Mo maa wo tẹlifiṣan lalẹ bayii, ma a ri awọn ta a jọ sọrọ, wọn o dẹ ni i gbe temi jade. Awọn nnkan mi-in bẹẹ naa tun pẹlu ṣa.

ALAROYE: A gbọ pe aarin ẹyin ati Gomina Amosun ko gun mọ, ṣe bẹẹ ni?

Sẹnetọ Tẹjuoṣo: Awọn eeyan to yi gomina ka lo n da nnkan ru, awọn ni wọn n sọ katikati, nitori ẹ ni mo ṣe n lọ jẹẹjẹ temi.

Sẹnetọ Tẹjuoṣo:A da a silẹ kawọn ọmọleewe naa le ni ọna kan ti wọn aa maa gba fi ohun ti awọn eeyan ko ti mọ han wọn. Oriṣiriṣii akọle ni wọn maa n fede Ẹgba sọrọ le lori, itaniji ni.

ALAROYE:Dokita oniṣẹgun oyinbo ni yin, ṣugbọn oṣelu ko jẹ ki ẹ ṣiṣẹ naa bayii. Bi ẹ ba foṣelu silẹ, ṣe o pada si i.

Sẹnetọ Tẹjuoṣo: Bẹẹ ni, mo maa pada siṣẹ dokita ti mo kọ nileewe.

ALAROYE: Amọran yin fawọn ti wọn yoo gbe yin wọle lẹẹkan si i.

Sẹnetọ Tẹjuoṣo: Ko ju pe ti wọn ba ri i pe a ṣe daadaa bawọn ṣe n fẹ, ki wọn gbe wa wọle pada, kiṣe yii le maa tẹsiwaju. Bi wọn ba si ri i pe a o ṣe daadaa to, ki wọn le wa lọ.

Mo ti sọ fun gomina pe ta a ba pari oṣelu tan, aa maa ṣe ba a ṣe n ṣe tẹlẹ bii baba  sọmọ, nigba tawọn to n da nnkan ru yii ko ni i si nibẹ mọ. Awọn to jẹ igba ti wọn di kọmiṣanna ati oṣiṣẹ abẹnu tan ni wọn bẹrẹ si i sọ katikati.

ALAROYE: Fifa ọmọ oye kalẹ loni-in, (Consensus), ka tun ni odikeji ẹ la maa ṣe lọla to n ṣẹlẹ nipinlẹ yii, ki lẹ ri si i?

Sẹnẹtọ Tẹjuoṣo: Gbogbo wa la mọ eyi to ba dẹmokiresi mu ninu awọn eto yii, ka faayan kalẹ, ka jẹ kawọn eeyan yan ẹni ti wọn ba fẹ, a mọ eyi to daa ju ninu mejeeji, eyi to daa lo yẹ ka ṣe.

ALAROYE: Idije lede Ẹgba ti ẹ gbẹ kalẹ fawọn ọmọleewe girama lọdọọdun, ki lohun ti ẹ tori ẹ da a silẹ?

 

(13)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.