Ọgọrun-un ọjo Dapọ Abiọdun: Awọn araalu n binu si gomina, wọn lo ti ja ireti awọn kulẹ

Spread the love

Kayọde Ọmọtọṣọ, Abẹokuta

Lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja ni iṣakoso Gomina Dapọ Abiọdun ti ipinlẹ Ogun pe ọgọrun-un ọjọ, ọpọlọpọ awọn eeyan lo si ti n fi ero ọkan wọn han si bi iṣakoso ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ naa ṣe n lọ. Nnkan to daju ni pe ọpọlọpọ awọn eeyan lo ti n fi aidunnu wọn han si bi gomina naa ṣe n tukọ ipinlẹ Ogun. Ohun to fa eyi ni pe wọn n ṣe afiwe awọn ohun ti Gomina Abiọdun ṣe si ti Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ṣeyi Makinde. Afiwe yii lo si fa a ti ọpọ fi n sọ pe Dapọ Abiọdun ko ti i ṣiṣẹ kankan nipinlẹ Ogun.

Awijare awọn eeyan yii ni pe lorileede Naijiria, ọgọrun-un ọjọ ti iṣakoso tuntun ba bẹrẹ ni awọn araalu maa n fi i mọ bi nnkan yoo ṣe ri lasiko iṣakoso naa, nibẹ ni yoo si ti fi ọna to fẹẹ gba tukọ ilu han sita. Eyi nikan kọ, laarin ọgọrun-un ọjọ lọpọ gomina ti maa n yan awọn eeyan ti yoo ba a ṣiṣẹ, nibẹ si ni awọn eeyan yoo ti mọ bi afojusun irufẹ gomina bẹẹ ba ṣe ri.

Ṣugbọn ọgọrun-un ọjọ ti Gomina Abiọdun ti kọja, titi di asiko yii gomina naa ko ti i yan awọn kọmisanna tabi awọn eeyan ti yoo ba a ṣiṣẹ rara. Lasiko ti gomina naa n ṣe ipolongo fun awọn oludibo, o ni oun yoo ṣe atunṣe si awọn ileewe ijọba, oun yoo kọ awọn ileewosan alabọọde si awọn agbegbe, oun yoo ṣatunṣe si etọ ọrọ-aje ipinlẹ naa, idagbasoke yoo si tun de ba eto ọrọ aabo laarin ọgọrun-un ọjọ ti oun ba lo. Ileri yii lo da bii pe ko le wa si imuṣẹ mọ, nitori ọgọrun-un ọjọ naa ti kọja.

Ohun to tilẹ tun waa ba awọn eeyan ninu jẹ ju ni pe l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja, ni gomina naa ni oun ko mọ pataki ọgọrun-un ọjọ ti awọn eeyan n pariwo kiri. O ni oun ko nigbagbọ ninu aṣeyọri ọgọrun-un ọjọ, bi ko ṣe pe oun yoo sọ awọn igbesẹ toun ti gbe lọfiisi laarin asiko naa ni. Lasiko to n sọrọ nibi ifilọlẹ ayẹwo ilera ọfẹ nileewe Ilishan High School, Ikenne, gomina ni pe oun fi ọgọrun-un ọjọ akọkọ oun se ipilẹ awọn nnkan ti oun fẹẹ ṣe laarin ọdun mẹrin ni, idi niyẹn ti oun ko si ṣe ka ayẹyẹ ọgọrun-un ọjọ si nnkan pataki.

Nigba ti o n ba awọn oniroyin sọrọ lọjọ naa, gomina ni “mi o ro pe ijọba wa yoo ṣe ayẹyẹ ọgọrun-un ọjọ kankan, nnkan ti mo kan fẹ ki ẹ mọ pe a gbe ṣe laarin ọjọ naa ni pe ipilẹ awọn ohun ti a fẹẹ ṣe laarin ọdun mẹrin la kọkọ fi lelẹ naa. Lara awọn nnkan ti a ti fi ipilẹ rẹ lelẹ ni awọn titi ti a n ṣe lọwọ atawọn nnkan mi-in ti awọn araalu ko ni i pẹẹ ri.”

Nnkan ti awọn araalu n sọ ni pe bi gomina ṣe kọ lati yan awọn ti yoo ba a ṣiṣẹ lo n fa ifasẹyin ba eto iṣakoso rẹ. Bakan naa, ọpọ awọn araalu lo tun n kun pe ọna ti ijọba ipinlẹ Ogun loun fẹẹ gbe igbanisiṣẹ wọn gba buru jai. Tẹ o ba gbagbe, gomina ni ki awọn ọdọ to n waṣẹ lọọ fi orukọ silẹ lori ikanni kan ti ijọba ṣi silẹ lori intanẹẹti, nibi to ti ni awọn ileeṣẹ to ba nilo wọn yoo pe wọn. Ṣugbọn gbogbo eyi ni ko ba awọn araalu lara mu. Mama agbalagba kan ti akọroyin wa ri ba sọrọ lọja Kutọ, ṣugbọn to ni ka forukọ bo oun laṣiiri ni pe ko si ani-ani pe wọn ti tọwọ oṣelu bọ igbesẹ igbani-siṣẹ yii. Mama naa ni ti eeyan ba wo awọn aṣeyọri ti gomina ipinlẹ Ọyọ, Ṣeyi Makinde, ṣe, ti awọn gbọ lori redio, ti awọn si tun ri ninu awọn iweeroyin kaakiri, a jẹ pe ọna ṣi jin fun Gomina Dapọ Abiọdun, nitori awọn ko ti i mọ ibi to n lọ.

Ṣugbọn ṣa, gomina ti ni ipilẹ awọn ohun toun fẹẹ gbe ṣe lọọfiisi loun fi lọlẹ laarin ọgọrun-un ọjọ yii. Awọn eeyan si ti n woye ohun ti yoo tun ṣẹlẹ lẹyin ọgọrun-un ọjọ.

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.