Ọgọrun-un kan awọn ọmo egbe PDP lo n dupo ile igbimọ aṣofin Kwara

Spread the love

Ọgọrun-un kan o le diẹ (106), awọn oludije ninu ẹgbẹ oṣelu PDP lo ti fifẹ han lati dupo si aaye mẹrinlelogun to wa ni ile igbimọ-aṣofin lọwọ ninu eto idibo ọdun 2019.
ALAROYE gbọ pe awọn adari ẹgbẹ PDP nipinlẹ Kwara ti pe awọn oludije naa papọ fun asọye, ti wọn si ti n wa ọna ti wọn yoo gba din wọn ku ko too di ọjọ idibo abẹle to maa waye lopin ọsẹ yii. Alaga ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Kwara, Kọla Shittu, sọ pe amọran ni igbesẹ ti ẹgbẹ naa gbe yii, ki i ṣe pe awọn kan-n-pa fun ẹnikẹni pe ko ma dije. O ni bi awọn oludije naa ba dinku ni yoo fi rọrun lasiko eto idibo abẹle lati yan awọn ti awọn ba fẹ.

Ọkan lara awọn oludije naa, Ben Duntoye, to gbẹnusọ fun awọn oludije yooku sọ pe awọn ti gba lati tẹle ilana ti ẹgbẹ la kalẹ naa, awọn yoo si ṣe nnkan to tọ ko too di ọjọ idibo abẹle.

(16)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.