Ọgbọn lati ra ibo fun ẹgbẹ APC ni 2019 ni eto ‘TraderMoni’ ti Osinbajo n gbe kiri -PDP

Spread the love

Ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Kwara ti ṣapejuwe eto ‘TraderMoni’ ti Igbakeji Aarẹ, Ọjọgbọn Yẹmi Ọsinbajo n gbe kaakiri gẹgẹ bii ọgbọn lati ra ibo awọn araalu fẹgbẹ APC lọdun 2019.

Alukoro ẹgbẹ PDP nipinlẹ Kwara, Tunde Ashaolu, lo sọ bẹẹ lọsẹ to kọja, nigba ti Ọsinbajo fi eto naa lọlẹ niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara.

Bẹẹ lawọn janduku kan tawọn eeyan fura si pe wọn ba Olori ile igbimọ aṣofin, Bukọla Saraki, ati ẹgbẹ PDP ṣiṣẹ lọọ da eto naa ru ninu ọja Mandate.

Awọn tọọgi ọhun ni wọn halẹ mọ awọn iyalọja ati babalaje lati ma gba owo naa. Wọn nijọba Buhari ati APC ko le maa lo ọja ti Saraki kọ lati maa fi gbe eto wọn larugẹ.

Ṣugbọn ọrọ yatọ ninu ọja Ipata. Gbogbo awọn ọlọja yẹn lo tako igbesẹ tawọn janduku naa fẹẹ gbe lati da eto naa ru.

Ashaolu ni ẹgbẹ PDP ki Ọsinbajo atawọn to kọwọọrin pẹlu rẹ kaabọ sipinlẹ Kwara. Ṣugbọn o ke si wọn lati ma ṣe ki oṣelu bọ eto naa.

Ẹgbẹ naa ninu atẹjade kan ni: “Bo tilẹ jẹ pe a mọ daju pe ọgbọn ati maa fi owo ra ibo lẹgbẹ APC n fi eto naa ṣe ṣaaju 2019, ṣugbọn ko gbọdọ si ọwọ oṣelu ninu ẹ.

“Lati 2015 ti wọn ti fi eto naa lọlẹ Ọsinbajo ko lọ sipinlẹ kankan lati maa gbe ‘TraderMoni’ kiri. Ṣugbọn nigba ti idibo ọdun 2019 ku oṣu diẹ lo bẹrẹ si i lọ sinu ọja kaakiri, to n pin owo fawọn ọlọja atawọn oniṣẹ ọwọ.

“Igbagbọ wa ni pe ṣe ki i ṣe ọna lati fi owo fa oju awọn araalu mọra lẹgbẹ APC n ṣe yii”.

Eto naa jẹ ọkan lara ohun tijọba aarẹ Muhammadu Buhari gbe kalẹ lati maa fun awọn to n ṣowo kekeeke ni ẹyawo ṣowo. Ọjọ Furaidee to kọja ni Igbakeji Aarẹ fi tipinlẹ Kwara lọlẹ.

 

 

 

(10)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.