Ọga ọlọpaa lu insipẹkiitọ daku ni Ṣaki, o ni alaigbọran ni

Spread the love

Lọwọlọwọ bayii, ileewosan aladaani tawọn Musulumi, iyẹn Muslim Hospital, to wa niluu Ṣaki, ni Insipẹkitọ ọlọpaa kan, Lawal Akeem, ti n gba itọju. Nnkan to gbe ọkunrin naa debẹ ko ṣẹyin bi ọga rẹ, DSP Adejumọ Oluwọle Adedayọ, ṣe lu u ni aludaku, o ni o ṣe aigbọran si aṣẹ oun.

Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja niṣẹlẹ naa ṣẹlẹ ni olu-ileeṣẹ ọlọpaa, iyẹn Eeria Kọmand to wa laduugbo Idi-Araba, niluu Ṣaki, ni nnkan bii aago mẹjọ aabọ aarọ.

ALAROYE gbọ pe Ọgbẹni Adejumọ, ẹni to ti di ọga lẹnu iṣẹ ọlọpaa lo fẹsun kan Akeem pe gbogbo asiko to ba n tọrọ aaye lati lọọ wo awọn mọlẹbi rẹ lo maa n lo ju ọjọ ti oun ba fun un lọ. Aaye ọjọ mẹta ni Akeem tọrọ kẹyin, to si lo ọjọ marun-un dipo ọjọ mẹta lo fa a ti ọga rẹ fi pe e pe ko waa ṣalaye nnkan to tun ṣẹlẹ. Nigba ti Akeem n ṣalaye lo sọ pe iyawo meji loun ni, ati pe ko rọrun fun oun lati wo iyawo kan ki oun ma yọju wo ekeji laarin ọjọ mẹta pere, o si bẹ ọga rẹ pe ko ma binu.

Gbogbo ẹbẹ yii ni ko tẹ ọga naa lọrun, niṣe lo sọ igbati si Akeem, ti ẹjẹ si bẹrẹ si i jade leti ati imu rẹ. Eyi lo mu un sa jade kuro ninu ọgba teṣan naa, ṣugbọn ọga naa tun sa tẹle e, awọn eeyan lo si gba Akeem kalẹ lọwọ rẹ.
Ọga agba Eeria Kọmanda, ACP Bosso, sọ pe oriṣiiriṣii ọna ni wọn le fi ba ọlọpaa to ba ṣẹ sofin wi, ṣugbọn ko tọna ki ọga maa yọwọ ẹṣẹ si ọlọpaa ẹgbẹ rẹ, o ni nnkan itiju gbaa ni.

Bosso ni oun ko ni i foju kekere wo ọrọ naa rara, oun yoo gbe igbesẹ le e lori, ko le baa jẹ arikọgbọn fun awọn yooku.

Nigba ti akọroyin wa ṣabẹwo si yara kejila, nibi ti ọkunrin naa ti n gba itọju nileewosan Muslim, ko ti i le ba ẹnikan kan sọrọ.

 

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.