Ọga ọlọpaa fẹẹ pa mi o, Saraki figbe ta fun gbogbo agbaye

Spread the love

L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja, ni Olori ile aṣofin agba, Sẹnẹtọ Bukọla Saraki, figbe ta to si ni ẹgbẹ APC, pẹlu Ọga ọlọpaa patapata nilẹ wa, Ibrahim Idris, n lepa ohun atawọn ẹbi oun nitori idibo to n bọ. O fẹsun kan ileeṣẹ ọlọpaa pe wọn ṣatilẹyin fawọn janduku kan lati maa kọlu awọn alatilẹyin oun ati lati ba awọn dukia kan jẹ.

Eyi waye bi awọn janduku ṣe tun ya bo agboole Saraki ni Agbaji, niluu Ilọrin, lọjọ Abamẹta, Satide, ti wọn si ba mọto to n lọ bii aadọta jẹ. Bi wọn ṣe n yinbọn ni wọn lagi mọ ọkọ ti wọn ba ri lagbegbe naa.

Iṣẹlẹ yii mu ki Saraki sare pada wa sile lati Ẹrin-Ile, nibi to ti lọọ polongo ibo lati foju ri gbogbo ohun tawọn janduku naa bajẹ.

O ke si awọn alatilẹyin lati gba alaafia laaye, ki wọn si ma gbẹsan ohun to ṣẹlẹ naa. O ni iṣẹlẹ ti fidi ariwo toun n pa mulẹ pe ọga ọlọpaa n lepa ẹmi oun nitori ọrọ ibo to n bọ.

Saraki to pe ipade awọn oniroyin niluu Abuja, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja, ni ẹmi oun atawọn ẹbi oun ko de mọ bayii, nitori bi awọn janduku kan to furasi pe wọn n ṣiṣẹ fun ẹgbẹ APC, ṣe n fi gbogbo igba kọlu awọn ọmọ ẹgbẹ PDP.

“Iṣẹlẹ mẹta ọtọọtọ yii yoo ṣalaye lẹkun-un-rẹrẹ ohun ti mo n sọ. Ni ana (Tọsidee), lẹyin ti ẹgbẹ APC pari ipolongo wọn niluu Ilọrin, awọn alatilẹyin wọn kan pẹlu awọn janduku bẹrẹ si i lọ kaakiri igboro. Wọn lọ sawọn agbegbe Adewọle/Adeta, Ile Otan ati Ubandawaki/Pakata, nibi ti wọn ti ba awọn eeyan wa ti wọn n ṣepade wọọdu  ẹgbẹ to maa n waye lọsọọsẹ.

“Bi wọn ṣe debẹ ni wọn da ipade naa ru pẹlu ariwo, ti wọn si bẹrẹ si i yinbọn saarin wọn, bẹẹ ni wọn n darukọ ẹgbẹ wọn. Wọn ṣa awọn eeyan ladaa, eeyan meji lo fara gbọta ni Adewọle.

“Lọjọ kan naa, awọn janduku APC yii pẹlu aabo awọn ọlọpaa gba ile mọlẹbi mi to wa ni Agbaji lọ, wọn ba gbogbo awọn ile jẹ, wọn ba ṣọọbu jẹ, wọn tun ṣa awọn eeyan ladaa yannayanna lagbegbe naa.

“Bakan naa, Ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa l’orilẹ-ede Naijiria, Ibrahim Kpotum Idris, ti bẹrẹ si i gbe gbogbo awọn ọga ọlọpaa agbegbe (DPO), kuro nipinlẹ Kwara. Eleyii jẹ ohun to ṣe ajeji si wa, paapaa julọ niru asiko yii. O jẹ ka maa fura pe o lohun ti ileeṣẹ ọlọpaa ni lọkan lati ṣe nipa igbesẹ naa”.

Ṣugbọn ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara ti ni ẹsun ti olori ile-igbimọ aṣofin agba fi kan awọn pe awọn n ṣatilẹyin fawọn janduku ati ẹgbẹ APC ko lẹsẹ nilẹ rara.

Kọmiṣanna ọlọpaa, Bashiru Makama, to fesi ninu atẹjade kan lọjọ Abamẹta, Satide, to kọja ni olori aṣofin naa ko fiwe ṣọwọ si ileeṣẹ ọlọpaa lori iṣẹlẹ idunkooko mọ ẹmi rẹ ati akọlu to ni wọn ṣe sawọn ẹbi atawọn alatilẹyin rẹ.

Ọga ọlọpaa ni pẹlu ipo ti Saraki di mu lorilẹ-ede Naijiria, o lẹtọọ si aabo to peye, nitori naa, ileeṣẹ ọlọpaa ri i daju pe awọn pese aabo fun un, o ṣi n janfaani rẹ titi ti akoko yii.

O ni gbogbo awọn tọwọ tẹ pe wọn da wahala silẹ lasiko ipolongo ibo to n lọ lọwọ yii lawọn ti fi jofin, lai ka ẹgbẹ oṣelu ti wọn n ṣe si.

 

 

(12)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.