Ọga Ọlọpaa Eko, o ṣeun ṣeun

Spread the love

Iroyin to jade lọsẹ to kọja pe awọn ọlọpaa Pen Cinema, ni Agege, n mu awọn araalu niwaju ile wọn, wọn n ko wọn lọ si teṣan, wọn si n pada gba owo lọwọ wọn fun beeli ki i ṣe iroyin to mu inu ẹni dun rara. O baayan ninu jẹ peọlọpaa le ṣe ohun to buru bẹẹ, bo tilẹ jẹ pe ko ṣe ajoji, nitori o pẹ ti iru iroyin bẹẹ ti n jade. Ọpọ awọnọlọpaati a gbojule nilẹ yii pewọn yoo ja fun awọn eeyan, pe wọn yoo gba wọn lọwọ awọn adigunjale ati awọn arẹnijẹ, awọn naa ni wọn joye adigunjale ati arẹnijẹ funra wọn, nigba to ba ṣe pe awọn gan-an ni wọn n da awọn eeyan lọna pẹluibọn ati aṣọijọba. Iroyin jade peni adugbo Alimi Ogunyẹmi, ni Ifakọ-Ijaye, l’Agege, awọn ọlọpaayii jade lọ, DPO ibẹ funra ẹ, Ọgbẹni Nwabuisi, lo si ṣaaju wọn. Wọn ba awọn eeyan kan to wa niwaju ita wọn, wọn ko wọn, wọn baawọn eeyan ti wọn ṣẹṣẹ kirun tan, wọn ko wọn, wọn ri ẹni ti wọn ran loogun fẹni ti ara rẹ ko ya, wọn mu un, wọn si ṣa awọn eeyan yika bẹẹ. Lati aago mẹjọ kọjadiẹ lalẹ ni wọn ti n mu wọn o, bẹẹ ni wọn si n ko wọnlọ si teṣan. Nigbẹyin, wọn ni ki wọn waa maafi owo beeli ara wọn, wọn si gba owo to to ọgbọn ẹgbẹrun lọwọẹlomi-in nibẹ. Eleyii buru, abi kin ni iyatọ awọn to ṣe eleyii pẹlu awọn adigunjale, iwato lewọpe ki i ṣe gbogbo ọlọpaa lole, ati peọlọpaa kan daa ju ọkan lọ.

Kia lo ti ni ki wọn gbe ọkunrin DPO naakurol’Agege, to si gbe igbimọ nla dide lati wadii ọrọ naa daadaa, ki wọn le mọ iru ijiya ti wọn yoo fun ọlọpaa ijẹwuru yii. Bo ba jẹ bi gbogbo ọlọpaa ti n ṣe ree, nnkan ko ni i bajẹ to bayii rara. Iyẹn lawa naa ṣe n ki Kọmiṣanna Edgal, ọgaọlọpaa to poju-owo!

 

 

 

(32)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.