Ọga agba ọlọpaa ṣabẹwo s’Ọṣun, l’Oluwoo ba ni ẹgbẹrun marun-un eeyan lo n ku lojumọ

Spread the love

Florence Babaṣọla

Ṣe ni gbogbo awọn eeyan ti wọn pejọ si olu-ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun lọsẹ to kọja lasiko abẹwo ọga agba patapata fawọn ọlọpaa, Mohammad Adamu sibẹ pariwo, ‘haaa’ nigba ti Oluwoo tilu Iwo, Ọba Adewale Akanbi, sọ pe eeyan ẹgbẹrun marun-un lo n ku laarin ipinlẹ Ọṣun lojumọ.

Lasiko ti wọn ni ki Ọba Adewale sọrọ ṣoki nibi eto naa lo ti ni ojoojumọ ni ẹjẹ awọn eeyan n ṣan nipinlẹ Ọṣun latari ipaniṣowo ati ipakupa to n waye kaakiri, idi si niyi ti eto aabo fi gbọdọ rinlẹ si i.

Gẹgẹ bo ṣe wi, “Ẹjẹ to wa loju popo l’Ọṣun, ipani-ṣetutu (ritual murders), ipaniṣowo (ritual killings), awọn ọlọpaa o ni i sọ fun yin, koda, kọmiṣanna ọlọpaa ko ni i sọ fun yin pe lojoojumọ, lojoojumọ, eeyan ẹgbẹrun marun-un lo n ku, ọga-agba ọlọpaa, wọn le ma le sọ ootọ fun yin, ṣugbọn emi aa sọ ootọ fun yin, lojoojumọ ni igbaaya, ọyan, oju-ara awọn eeyan wa kaakiri, eleyii ki i ṣe iṣe wa, ko si ninu aṣa wa.

“A gbọdọ wa ọna lati ṣe ofin kan pe ẹnikẹni to ba ti paayan ṣetutu gbọdọ gba idajọ iku, gbogbo awọn sọọbu ti wọn ba ti n ta ẹya ara eeyan la gbọdọ wo lulẹ. O n ṣẹlẹ kaakiri iha Iwọ-Oorun Guusu ati Ila-Oorun Guusu, Guusu-Guusu orileede yii, ojoojumọ ni wọn n pa awọn ọmọ wa, tori naa, mo fẹ ki ọga-agba ọlọpaa kiyesi eleyii daadaa, ẹjẹ wa lọwọ awọn eeyan, ẹ ṣeun”

Oluwoo ko ti i sọrọ de idaji ti awọn ọlọpaa atawọn araalu ti wọn wa nibẹ fi n pariwo pe iru ki ni Kabiyesi n sọ yii, ninu ariwo ni baba naa si sọrọ wọn tan ki wọn too lọọ jokoo. Nigba to n fesi si ọrọ Oluwoo, Alukooro ileeṣẹ ọlọpaa lorileede yii, Frank Mba, sọ pe ti wọn ba gbe iṣiro le oun ti Kabiesi sọ, o yẹ ki awọn eeyan ti tan nipinlẹ Ọṣun.

Mba ṣalaye pe ninu akọsilẹ, eeyan miliọnu mẹta ati ẹgbẹrun mẹrin lo wa nipinlẹ Ọṣun, ti eeyan ẹgbẹrun marun-un ba n ku lojumọ, a jẹ pe eeyan ẹgbẹrun lọna aadọjọ lo n ku loṣu niyẹn, eleyii to tumọ si pe laarin ọdun meji pere, gbogbo eeyan ti tan nipinlẹ Ọṣun.

Bakan naa ni Aragbiji ti ilẹ Iragbiji, Ọba Abdulrasheed Ọlabomi, sọ pe ko si nnkan to jọ ipaniyan lagbegbe toun, nitori iṣẹ takuntakun lawọn ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun n ṣe tọsan-toru lati ri i pe aabo to nipọn wa fun awọn araalu.

Ninu ọrọ Ọga-agba patapata fawọn ọlọpaa, Adamu, o ni oun wa sipinlẹ Ọṣun lati ṣe koriya fawọn ọlọpaa lori iṣẹ takuntakun ti wọn n ṣe, ati lati jẹ ki wọn mọ pe asiko isinmi ko ti i to nitori ojuṣe wọn ni lati jẹ ki gbogbo agbegbe wa lalaafia, lai si ibẹru kankan.

O ni gbogbo eto lo ti to bayii lati ri i pe gbogbo awọn janduku ti wọn n gbe awọn nnkan ija oloro nla nla kiri ko ni alaafia mọ kaakiri orileede yii, ati pe awọn yoo pese irinṣẹ igbalode tawọn yoo lo lati fi koju iwa ọdaran laipẹ.

Adamu fi kun ọrọ rẹ pe gbigba awọn to kunju oṣuwọn sẹnu iṣẹ ọlọpaa ṣi n tẹsiwaju, bakan naa nijọba ko ni i kuna ninu ojuṣe rẹ lori igbaye-gbadun awọn ọlọpaa lati le jẹ koriya fun wọn lẹnu iṣẹ ipese aabo fun ẹmi ati dukia awọn araalu.

Nigba ti Adamu ṣabẹwo si Gomina Gboyega Oyetọla lọọfiisi rẹ, o lu u lọgọ-ẹnu fun ifọwọsowọpọ rẹ pẹlu awọn ileeṣẹ eto aabo, eleyii to mu ipinlẹ Ọṣun wa lara awọn ipinlẹ ti iwa janduku ko ti rọwọ mu.

O ni ileeṣẹ ọlọpaa ti pinnu, laipẹ yii si ni igbesẹ yoo bẹrẹ lati gbe ogun ka awọn ajinigbe ti wọn fi inu aginju ṣebugbe mọle, ti awọn yoo si rẹyin wọn. O waa fi da awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun loju pe ko si ewu kankan lẹgbẹrun ẹkọ wọn.

Gomina Oyetọla dupẹ lọwọ Adamu fun atilẹyin rẹ lori eto aabo nipinlẹ Ọṣun, o si ṣeleri pe gbogbo ọna loun yoo maa gba ṣeranlọwọ fawọn ọlopaa lati ri i pe ipinlẹ Ọṣun gbona fun awọn janduku.

(74)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.