Ọdun tuntun: Fayẹmi sanwo ajẹsilẹ awọn oṣiṣẹ Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Spread the love

Ijọba ipinlẹ Ekiti ti kede pe oun bẹrẹ ọdun tuntun yii pẹlu sisan owo ajẹsilẹ tijọba ana jẹ awọn oṣiṣẹ. Ikede naa waye nibẹrẹ ọsẹ yii latenu igbakeji gomina Ekiti, Ọtunba Bisi Ẹgbẹyẹmi.

Ninu atẹjade kan ti Ọdunayọ Ogunmọla to jẹ oluranlọwọ pataki lori eto iroyin fun Ẹgbẹyẹmi fọwọ si, ijọba tun ti bẹrẹ si i sanwo awọn to di ipo oṣelu mu tẹlẹ nipinlẹ naa.

Nibi eto kan to ti ko awọn olori ẹsin, oloṣelu ati oṣiṣẹ jọ ni Ẹgbẹyẹmi ti sọ pe awọn igbesẹ wọnyi ko ṣẹyin ileri ti Gomina Kayọde Fayẹmi ṣe pe oun yoo da igba ọtun pada fun igbaye-gbadun araalu pẹlu oriṣiiriṣii eto.

‘’Ijọba fẹẹ sanwo awọn oṣiṣẹ tan, idi niyi ta a fi dawọ duro lori awọn eto mi-in to yẹ ka ṣe. Mo gba yin niyannju lati gbaruku ti ijọba wa ka le fi ipinlẹ yii silẹ ju ba a ṣe ba a lọ.

‘’ Awọn kan sọ pe o maa le tiṣa ta a ba gbajoba, ṣugbọn a ko ṣe e nitori idunnu wọn la n wa. Gbogbo awọn owo to yẹ ka san la maa san, idunnu gbọdọ maa ṣubu layọ fawọn eeyan wa lọdun yii.’’

 

 

(16)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.