Ọdun mẹta ni Jimoh yoo lo lẹwọn, iya arugbo lo fipa ba lo pọ ni Modakeke

Spread the love

Ọmọkunrin ẹni ogoji ọdun kan, Jimoh Oyemọni, ladajọ Majistreeti ilu Mọdakẹkẹ ti ni ko lọọ fi ẹwọn ọdun mẹta jura lori ẹsun pe o fipa ba iya arugbo ẹni ọgọrin ọdun lo pọ.

 

Ọjọ kẹtalelogun, oṣu kejila, ọdun to kọja, la gbọ pe Jimoh huwa naa ni abule Onibambu, nitosi Mọdakẹkẹ, laago meji aabọ ọsan.

 

Gẹgẹ bi agbefọba to n gbọ ẹsun naa, Inspẹkitọ Ona Glory, ṣe sọ funle-ẹjọ, oju-ọna oko ni Jimoh ti da iya oniyaa, Victoria Ṣogunlana, dubulẹ, to si ba iya laṣepọ lodi si ifẹ inu rẹ.

 

Ona sọ siwaju pe ṣe ni Jimoh ga iya agba yii lọrun mọlẹ titi ti iya naa ko fi lagbara lati janpata mọ, to si fi ṣiṣẹ laabi naa.

 

Iwa ti Jimoh hu gẹgẹ bi Inspẹkitọ Ona ṣe wi lodi, bẹẹ lo si nijiya nla labẹ abala aadọta ati ẹyọ kan le lọọọdunrun (351), ofin iwa ọdaran ti ọdun 2003 tipinlẹ Ọṣun n lo.

 

Nigba ti akọwe kootu ka ẹsun mejeeji to ni i ṣe pẹlu fifi ipa ba iya agba lo pọ ati fifun iya lọrun lati huwa ibi s i leti, Jimoh ni oun ko jẹbi ẹsun ẹlẹẹkeji, nitori oun ko fun iya naa lọrun rara.

 

Onidajọ A.O. Famuyide fagile ẹsun keji, o si sọ pe Jimoh, ẹni ti ko ni agbẹjọro to n ṣoju rẹ ni kootu jẹbi ẹsun akọkọ.

 

Lati le jẹ ẹkọ fawọn ọkunrin alagbere bii Jimoh, adajọ sọ pe ko lọọ faṣọ pempe roko ọba lọgba ẹwọn Ileefẹ fun odidi ọdun mẹta gbako lai faaye faini silẹ fun un rara.

 

(7)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.