Ọdun meloo ni wọn aa fi ṣe ọna Eko s’Ibadan yii o

Spread the love

Awọn gomina mẹfẹẹfa ti wọn wa ni ilẹ Yoruba (South West), pa ẹnu wọn pọ lọsẹ to kọja yii, wọn ni awọn ko fẹ bi ijọba apapọ ṣe n ṣe ọna Eko si Ibadan, wọn ni ohun ti ko dara ni, iwa irẹjẹ ati aika awọn eeyan si ni pẹlu. Wọn ni ki ijọba pari ọna naa, ki alaafia le wa loju popo yii, nitori inira to n ba awọn eeyan nibẹ bayii le ju ohun ti ẹni kan le sọ pe oun ko ri i lọ. Tabi ta ni ko ri iṣoro to n koju awọn eeyan lọna Eko si Ibadan yii, nibi ti irin wakati kan ti n na awọn eeyan ni wakati mẹfa tabi mẹjọ tabi ju bẹẹ lọ. Naijiria yii nikan la ti ri i ti awọn oniṣẹ-ọna yoo dajọ pe wọn yoo pari ọna nigba bayii, ti wọn yoo si waa maa sun un siwaju titi di ọjọ to ba wu wọn. Nigba tawọn Jonathan bẹrẹ ọna yii, bii ọdun 2015 ni wọn ni yoo pari, nigba ti awọn Buhari yii de, wọn ni awọn fi ọdun meji kun un, iyẹn ni pe yoo pari ni bii 2017, eyi ti a si n gbọ bayii ni pe o di ọdun 2021, ọdun mẹta si asiko yii ki ọna naa too pari. Bo ba jẹ bi gbogbo aye ti n fọdun mẹwaa ṣe titi kan ree, ilu oyinbo ti awọn oloṣelu wa n lọ ko ni i maa wu wọn lati lọ, nitori awọn naa yoo sa fun inira. Awọn eeyan yoo wa ninu gosiloo ọna Ibadan yii, wọn yoo maa laagun, aṣọ wọn yoo di tutu, mọto yoo bajẹ, asidẹnti yoo ṣẹlẹ, ẹlomi-in yoo daku, ijamba oriṣiiriṣii, loju ọna kan yii naa ni. Ọlọrun lo mọ iye ẹmi to ti ṣofo nibẹ nitori pe wọn n tun ọna ṣe. Ki waa ni awa fẹẹ ṣe yanju ni tiwa gẹgẹ bii orilẹ-ede, ki la fẹẹ tọka si pe eleyii ni a mọ-ọn ṣe. Ko si iroyin kan ti ẹ gbọ lẹyin odi nipa Naijiria ti ko ni i jẹ lori ibajẹ ati aburu! Sibẹ naa, a ko jawọ, ohun gbogbo yoo si maa bajẹ mọ wa loju. Ghana lo wa nibẹ yẹn, oju ọna wọn dara ju ti Naijiria lọ, wọn ko si ni ida mẹwaa owo ti Naijiria ni. Togo lo wa nibẹ yẹn, oju ọna wọn dara ju tiwa lọ, bẹẹ ni awọn Bẹnnẹ ti wọn wa nitosi wa nibi to jẹ awa la tun n fun wọn lowo. Eyi to buru ni pe awọn ti wọn n ṣe titi fun wa yii naa, Julius Berger atawọn mi-in, ni wọn n ṣe ọpọlọpọ titi tiwọn naa, titi ti wọn ba si ṣe fun wọn ni Ghana tabi Togo ni ẹgbẹrun mẹwaa pere, ọgọrun-un ẹgbẹrun ni wọn yoo waa ṣe e fawa. Bawo laye wa kuku ṣe ri bayii Ọlọrun Ọba. Lọjọ wo lawọn oloṣelu fẹẹ tun ilu yii ṣe fun wa, ṣe awọn eeyan yii ko ni i tẹ Naijiria ri bayii! Ohun to ma n ṣẹlẹ yii ko da.

(4)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.