Odiwọn FIFA: Naijiria gun akasọ mejila

Spread the love

Lẹyin ipo kẹta ti ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles ilẹ wa ṣe nibi idije Afrika to ṣẹṣẹ pari, ipo kẹtalelọgbọn la wa bayii lẹyin ta a gun akasọ mejila lori odiwọn ajọ ere bọọlu agbaye (FIFA) tuntun.

Ninu odiwọn ti wọn gbe jade lopin ọsẹ to kọja naa ni Naijiria ti sun kuro nipo karundinlaaadọta ta a wa loṣu to kọja, eyi si tun mu wa duro ṣinṣin sipo kẹta l’Afrika.

Senegal to ṣe ipo kin-in-ni l’Afrika lo wa nipo ogun lagbaaye, nigba ti Tunisia to ṣe ipo keji wa nipo kọkandinlọgbọn lagbaaye.

Algeria to ṣẹṣẹ gba ife-ẹyẹ idije Afrika lo wa nipo ogoji lagbaaye bayii lẹyin ti wọn gun akasọ mejila, ipo kẹrin ni wọn si bọ si l’Afrika.

Lagbaaye, Belgium, Brazil, France, England ati Uruguay lo di ipo kin-in-ni sipo karun-un mu.

Oṣu kẹrin, ọdun 1994, ni Naijiria ṣe daadaa ju lagbaaye pẹlu ipo karun-un, nigba ti ipo kejilelọgọrin toṣu kọkanla, ọdun 1999, jẹ eyi to buru ju.

(3)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.