Ọdaju abiyamọ ju ọmọ ọjọ meje sinu ṣalanga n’Ileṣa

Spread the love

Bi ki i baa ṣe ti Ọlọrun to ni ẹmi ọmọdebinrin jojolo kan ti iya rẹ ju sinu ṣalanga niluu Ileṣa laipẹ yii i lo, ọmọ naa i ba ti dagbere faye kawọn araadugbo too fura pe eeyan wa nibẹ.
Igbe ọmọ tuntun ni ẹnikan to n kọja lọ lagbegbe Anaye, niluu yii lọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹwaa, gbọ, o wọtun, o wosi, o si ri i pe inu ṣalanga kan to wa lẹyinkule ile to wa ni K65, lopopona ọhun ni igbe naa ti n jade wa.
Bayii lo pe akiyesi awọn ti wọn wa lagbegbe naa si i, bi wọn si ṣe ṣilẹkun ṣalanga naa, iyalẹnu lo jẹ fun wọn lati ba ọmọdebinrin jojolo naa nilẹẹlẹ ṣalanga, nibi to ti n sunkun.
Oju ẹsẹ lawọn eeyan ti pe sibẹ, bẹẹ lonikaluku bẹrẹ si i sọ oniruuru nnkan nipa ọdaju abiyamọ to le hu iru iwa bẹẹ.
Wọn wadii kaakiri adugbo naa lati mọ ẹni to loyun, to si le ṣẹṣẹ bimọ tuntun ti wọn le fura si, ṣugbọn wọn ko ri eegun to n jẹ ajikẹ, idi niyi ti wọn fi gbe ọmọ naa lọ si agọ ọlọpaa to wa lagbegbe naa.
Awọn ọlọpaa fi ọrọ ọhun to ileeṣẹ to n ri si igbaye-gbadun awọn obinrin ati ọmọde nipinlẹ Ọṣun leti, latigba yẹn ni wọn si ti gbe ọmọ naa sọdọ, ti wọn n tọju ẹ.
Gẹgẹ bi akọwe agba nileeṣẹ naa, Lara Ajayi, ṣe wi, lẹyin ayẹwo lo di mimọ pe ọmọ ọjọ meje pere lọmọbinrin jojolo naa lọjọ ti alaaanu gbohun rẹ ninu ṣalanga, ti wọn si gbe e lọ sọdọ awọn ọlọpaa naa.
Ajayi waa rọ ẹnikẹni to ba mọ iya, baba tabi awọn mọlẹbi ọmọ naa lati waa fi to ileeṣẹ naa leti ki wọn le gbe ọmọ yii fun wọn fun itọju to peye.

(33)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.