Ọbasanjọ yọju sibi ipolongo ibo ẹgbẹ PDP

Spread the love

Iyalẹnu nla gbaa lo jẹ fun oludije ipo gomina ipinlẹ Ogun labẹ PDP, Ọladipupọ Adebutu, ati awọn ọmọ ẹgbẹ PDP ti wọn n ṣe iponlogo fun un ni Olusegun Obasanjo Presidential Library, nigba ti wọn ri aarẹ ana Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ to yọ si wọn wurẹ.

Oloye Adebutu yii lo n ṣoju awọn agbegbe Rẹmọ nile-igbimọ awọn aṣojuṣofin lọwọlọwọ bayii, bẹẹ lo tun jẹ ẹgbọn iyawo ọmọ oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, Olujuwọn Ọbasanjọ.

Bi baba agbalagba oloṣelu yii ṣe bọ silẹ ninu jiipu rẹ to yọ saarin awọn ti wọn n polongo ibo nitosi ile rẹ yii, ariwo sọ laarin awọn ọmọ ẹgbẹ PDP, ajọyọ naa si kọja ohun ti ẹnikan le royin tori baba naa ti sọ tẹlẹ pe oun ko ni nnkan kan ṣe pẹlu ẹgbẹ oṣelu kankan to fi lọọ da ẹgbẹ akojọpọ ọmọ Naijiria silẹ, eyi to pada darapọ mọ African Democratic Congress ADP.

Nigba ti baba naa bọọlẹ saarin wọn nibi ti wọn ti n ṣajọyọ wiwa rẹ yii, o ni, “Mo kan n kọja lọ ni mo ni ki n ṣe hẹlo si yin, ki n sọ fun ẹ pe aa yọri sire o.”

Bẹẹ naa lo ni ilẹkun ile oun ṣi silẹ fun gbogbo ọmọ Naijiria to nigbagbọ ninu ifọwọsopọ orileede yii bii toun, lati waa gba imọran lori ohun ti wọn ba fẹẹ ṣe.

Lẹsẹkẹsẹ to ṣeyi tan naa lo tun wọnu ọkọ rẹ pada to si gba ile rẹ ti ko jina sibẹ lọ.

Oloye Ọladipupọ, ti kọkọ lọ sọdọ Alake ilu Ẹgba, Ọba Adedọtun Gbadebọ, lati lọọ gba adura lẹnu rẹ lori ipo gomina to n le, bẹẹ naa lo tun fun adugbo mẹrin ni ẹrọ amunawa (Transformer) niluu Abẹokuta yii kan naa.

(52)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.