Ọbasanjọ sọrọ: Ẹ WA, Ẹ JẸ KA JỌ LE BUHARI LỌ

Spread the love

Ẹni kan ṣoṣo lawọn Kristẹni aye yii bẹru ju ti wọn si maa n gbe ọla fun nigba ti a ba ti yọwọ Jesu Krisiti kuro, iyẹn naa ni Pope, ẹni ti wọn n pe ni “Papa Mimọ.” Ẹnikẹni to ba wa lori ipo naa ki i da si ọrọ oṣelu, yoo si ti ṣe ẹsin de gongo ko too debẹ, iyẹn naa lawọn ẹlẹsin rẹ si ṣe maa n fun un ni gbogbo ọwọ to ba tọ si olori awọn ojiṣẹ Ọlọrun ninu ẹsin tiwọn. Ṣugbọn bi ọkunrin naa ki i ti i sọrọ to, ọrọ ohun to n lọ ni Naijiria bayii, ati bi ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari ti kọyin si oku to n fojoojumọ sun ti de iwaju Pope Francis, baba naa si sọrọ lọsẹ to kọja yii pe oun ko faramọ iru ijọba yii, ijọba ti wọn n fojoojumọ paayan labẹ rẹ ti ko mu awọn to n pa wọn, ti ko si ṣe bii ẹni pe awọn eeyan lo n ku. Loootọ ko sọ pe ki Buhari maa lọ o, ṣugbọn awọn ọrọ to sọ jade lati Rome lọhun-un ko ni i jẹ ki awọn ọmọlẹyin Krisiti kan fẹẹ ba Buhari ṣe.
Ko si ohun to fa ariwo tuntun yii bii ti awọn Fulani onimaaluu ti wọn tun ya wọ ile-ijọsin kan ni ipinlẹ Benue, ti wọn si pa awọn eeyan mejidinlogun lẹẹkan, ti wọn tun waa pa awọn ojiṣẹ Ọlọrun meji ti wọn n ṣiṣẹ Oluwa jẹẹjẹ tiwọn. Wọn ṣe bẹẹ yẹn, gbogbo aye pariwo, nigba to si tun di ọjọ keji, wọn tun lọọ ka awọn mi-in ti wọn sa lọ si ṣọọṣi mi-in nitori ogun Fulani to le wọn nile yii mọbẹ, wọn si tun pa meje ninu wọn lẹẹkan. Ni tododo, ọkan ninu awọn alukoro fun Buhari kede sita pe Buhari ba wọn daro, o ni iku naa ka oun lara, ṣugbọn ọrọ naa ko tẹ awọn eeyan lọrun, nigba to jẹ lojoojumọ ti wọn ba ti paayan bayii, ọrọ kan naa ti Buhari tabi awọn to n ran niṣẹ yoo sọ niyi, bo ba si ti sọ bẹẹ tan, nibi ti ọrọ naa yoo pari si niyẹn. Iyẹn lọrọ naa ko ṣe dun mọ awọn yẹn ninu rara.
Paripari rẹ si ni pe lọjọ keji ti wọn paayan bayii, Aarẹ lọ si ipinlẹ Bauchi lati lọọ ṣe kampeeni, to si n ba awọn eeyan sọrọ nibẹ pe asiko ibo to n bọ yii, ki wọn ma da awọn ti wọn n sọrọ oun laidaa lohun, oun ni ki wọn tun dibo fun lọjọ ti idibo ba de. O ya awọn araata, atawọn araale paapaa, lẹnu pe Buhari yoo maa ṣe kampeeni lọjọ keji tawọn eeyan ku rẹpẹtẹ bẹẹ, ti ko si ni ọrọ aanu kan to sọ nibi to ti lọọ kampeeni yii ju pe ki wọn dibo foun lọ. Ohun ti awọn eeyan n sọ ni pe ṣe Buhari ko loju aanu rara ni, abi ko tilẹ mọ ohun to n ṣẹlẹ ni ayika rẹ ni. Ọrọ naa ka awọn Kristẹni lara debii pe niṣe ni wọn tu jade pẹlu iwe nla nla lọwọ wọn, ti wọn n fi ẹhọnu wọn han, ti awọn mi-in ninu wọn si n pariwo pe afi ki Buhari maa lọ. Lati Ṣokoto, Kano, Benue, Kogi titi to fi de Ọyọ, Ekiti, Ibadan, Ọṣun, Abuja, Taraba, Ondo ati ilẹ Ibo, ko sibi ti awọn Kristẹni ko ti jade ni Sannde to lọ yii, bi wọn ti n gbarayilẹ lawọn mi-in n sunkun, nitori aburu to n ṣẹlẹ ni ṣọọṣi nilẹ Hausa.

Ọrọ naa ka Ọjọgbọn Wọle Ṣoyinka paapaa lara, ohun ti oun si sọ ni pe o da bii pe awọn Fulani ti mura lati pa awọn ẹya to ku rẹ ni Naijiria, ko jẹ ẹya tiwọn nikan ni yoo ku, nitori aburu tawọn eeyan naa n ṣe, oun ko ri i ri nibi kan. Ṣoyinka ni eyi to si n dun-un-yan ni pe ko jọ pe ọwọ ijọba yii mọ rara, nitori niṣe lo da bii pe awọn kan wa ninu ijọba naa ti wọn n ṣe aabo fun awọn apaayan ti wọn paayan kaakiri.

Ọkunrin ọmọwe naa ni ọrọ Naijiria da bii ọrọ ẹronpileeni kan to jabọ lọdun 1994, to si pa gbogbo eeyan lẹẹkan naa. Bẹẹ ohun to fa a ni pe awakọ-baalu naa fi aaye dẹrẹba silẹ, o waa lọ si ọdọ awọn eeyan ẹ to wa ninu baalu yii, o bẹrẹ si i ba wọn ṣere, wọn n dọwẹkẹẹ, baalu n da fo lọ. Iyẹn ni pe awọn eeyan tirẹ to ko ṣe pataki ju gbogbo awọn to ku ninu baalu lọ. Lọrọ kan, baalu naa pada jabọ, o si pa gbogbo ẹni to wa nibẹ. O ni bi ọrọ Naijiria ti ri ree, bii pe ko si awakọ to n wakọ naa lofurufu mọ ni o, baalu kan n da fo lọ ni.

Bi ọrọ si ti ri niyẹn loootọ, nitori ko jọ pe Aarẹ Buhari wa nidii baalu yii mọ rara, ohun ti awọn aṣofin fi n leri pe awọn yoo yọ ọ niyẹn. O pẹ ti awọn aṣofin ti n binu si i, paapaa bi ko ṣe bẹru wọn, ti ko si pọn wọn le, ti ki i gbọrọ si wọn lẹnu, ti ọrọ wọn ko si ta leti rẹ, ti awọn ti wọn n ba a ṣiṣẹ naa si n ṣe bẹẹ gẹlẹ si awọn aṣofin yii. Lọsẹ to kọja yii, nigba tawọn ọlọpaa mu Dino Melaye, ọkan ninu awọn aṣofin to maa n sọrọ fatafata nile igbimọ yii, wọn ranṣẹ pe ọga ọlọpaa pe ko waa ṣalaye ọrọ naa fawọn, ṣugbọn ọkunrin naa ko da wọn lohun. Olori ile igbimọ aṣofin yii, Alaaji Bukọla Saraki, mura lati ba ọga ọlọpaa yii sọrọ, ṣugbọn fun odidi ọjọ meji, ko ri i ba sọrọ lori foonu.
Saraki funra ẹ lo sọ bẹẹ, o ni ki i ṣe pe foonu oun ko wọle o, ọkunrin ọga awọn ọlọpaa naa ko gbe e ni, nigba ti wọn yoo si wadii rẹ lọ wa a bọ, Buhari lo ba lọ si Bauchi lati ṣe kampeeni fun wọn.
Bẹẹ ni ọpọ awọn ọmọlẹyin Buhari ti wọn n ba a ṣiṣẹ n ṣe fawọn aṣofin. Iyẹn ni wọn ṣe dide lọsẹ to kọja pe Buhari ti ṣẹ awọn ẹṣẹ kan, o si yẹ lẹni ti wọn yoo yẹ ọrọ rẹ wo lati mọ boya ki wọn yọ ọ, nitori awọn aṣofin lagbara lati yọ ọ kuro nipo naa bo ba ṣe ohun to buru loju wọn. Buhari si ṣe kinni kan ti wọn lo buru. O nawo kan ni, owo naa si jẹ miliọnu mẹrindinlẹẹẹdẹgbẹta dọla ($496m). Aarẹ sọ pe awọn ṣọja ni wọn nilo owo naa, wọn fi ra ẹronpileeni to n jagun fun wọn ni nitori idaamu awọn Boko Haram. Ṣugbọn ibi ti ọrọ naa ti bu Buhari lọwọ ni pe, labẹ ofin, ko gbọdọ na iru owo bẹẹ lai gba aṣẹ nile igbimọ.
Ko si ibi ti aarẹ orilẹ-ede kan ti gbọdọ da na iru owo bẹẹ lai gba aṣẹ, o ti kọkọ gbe iwe naa wa siwaju awọn igbimọ aṣofin ki wọn si fọwọ si i. Ṣugbọn boya nitori aika awọn aṣofin yii si nnkan kan ni o, tabi pe Buhari funra rẹ ko naani ofin, wọn ko gbe iwe kankan de ọdọ awọn aṣofin, wọn ti sanwo naa ki wọn too maa gbọ. Awọn aṣofin tun waa wadii, wọn ri i pe iye ti wọn n ta ẹronpileenmi yii kere pupọ si iye ti awọn eeyan Buhari sọ pe awọn ra a, bẹẹ bo ba ṣe pe wọn gbe iwe owo naa wa ni, wọn yoo ti mọ iye ti wọn n ta a daadaa ki wọn too lọọ ra a, ko si ni i da bii pe wọn lu wọn ni jibiti, tabi pe awọn kan ko owo ẹ jẹ. Iyẹn lawọn aṣofin ṣe sọ pe ki awọn le e. Bo tilẹ jẹ pe aṣofin to gbe ọrọ naa kalẹ, Mathew Uroghide, ti ri oju pipọn gomina ipinlẹ Edo ati awọn eeyan rẹ, ti wọn fabuku kan an ni gbangba nigba ti wọn pade ni papa ọkọ ofurufu ni Binni, sibẹ, Alaroye gbọ pe awọn aṣofin naa ti pinnu pe Buhari yoo lọ dandan.
Iyẹn ni wọn n sọ lọwọ nigba ti Oluṣẹgun Ọbasanjọ jade, aarẹ ana, ẹni to si wa ninu awọn ti wọn gbe Buhari wọle ni ọdun 2015. Niluu Ibadan ni baba naa wa, nibi ti wọn ti n ko ẹgbẹ rẹ to loun ko jọ fawọn ọdọ lati fi gbajọba lọwọ Buhari jade. Ọrọ pataki to sọ, to si n tẹnumọ nibẹ naa ni pe ki ọpọlọpọ eeyan wa, ki gbogbo ọmọ Naijiria maa bọ, ki wọn jẹ ki awọn jọ le Buhari jade. O ni Buhari gbọdọ lọ, nitori ti ko ba lọ, ewu to wa lọrun Naijiria fun ọdun mẹrin mi-in, apa orilẹ-ede yii ko ni i ka a, iyẹn si loun ṣe n sọrọ, ki awọn ọmọ Naijiria ma pada waa sọ pe awọn ko wi kinni kan. Ọbasanjọ ni, “Bi ẹ ba ri ẹnikan to ba n sọ pe ki Buhari tun ṣe ijọba lọdun mẹrin mi-in ni Naijiria, ẹ jẹ ki wọn yẹ iru ọpọlọ ẹni bẹẹ wo, nnkan n ṣe e o! Ohun to kan mi ni pe ki gbogbo yin maa bọ, kẹ ẹ jẹ ka jọ le Buhari lọ!”
Njẹ ọrọ naa yoo ṣee ṣe bẹẹ? O digba naa na, ka too fọmọ ọba fọṣun!

(96)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.