Ọbasanjọ ni: DANDAN NI O, BUHARI GBỌDỌ LỌ NI 2019

Spread the love

Bi Ọlọrun ba gba adura aarẹ Naijiria tẹlẹ, Oluṣẹgun Ọbasanjọ, to si ṣe ohun to n fẹ fun un, Aarẹ Muhammadu Buhari ko ni i pada si ipo to wa yii lẹyin ti a ba dibo tan lọdun 2019. Ọbasanjọ ti sọ pe dandan ni, Buhari gbọdọ lọ. Ẹni to ba fẹẹ gba ounjẹ lẹnu ẹni, eeyan ki i ba iru ẹni bẹẹ ṣọrẹ o, Buhari paapaa – oun nikan tiẹ kọ, oun ati awọn eeyan rẹ ni – ko ri Ọbasanjọ bii ọrẹ rẹ mọ, ipo ọta lo to o si, ọna bi yoo ti ki baba naa sinu ago irin lo n wa, ija naa si ti di ija agba meji, abi keeyan pe e ni ija awọn ọga ologun meji, ibi ti yoo yọri si, ko si puruntu to le sọ. Buhari ati awọn eeyan rẹ ti dẹ okun rẹpẹtẹ yi Ọbasanjọ po, wọn n beere bo ṣe na owo rẹpẹtẹ kan ti wọn lo ni oun fi ṣe eto ina mọnamọna nigba to fi wa nile ijọba. Biliọnu mẹrindinlogun ni wọn pe owo naa, owo Dọla, Buhari si sọ pe oun ko ri ina ti Ọbasanjọ loun ṣe.

Ọrọ naa jo Ọbasanjọ lara, o ni Buhari ki i kawe lo ṣe n sọ bẹẹ, bo ba jẹ o kawe ni, yoo ti mọ pe oun ko na owo to to bẹẹ fi ṣe ina, iye ti oun na ati bi oun ṣe na an wa ninu iwe ijọba. Lẹyin naa ni awọn Buhari ni bi ọrọ ina ko ba tete yanju, awọn yoo hu ọrọ awọn oku ti wọn yinbọn pa laye Ọbasanjọ dide, yoo ṣoro ko too sọ pe oun ko mọ bi awọn eeyan naa ti ṣe ku, ati bi wọn ṣe ku ti wọn ko ri awọn ti wọn pa wọn mu. Ọbasanjọ foyinbo nitori eyi, o ni kampe loun wa, ‘I dey Kampe,’ o ni oun ko paayan, oun ko si le sọ pe ki wọn ma wadii ohunkohun to ba ṣẹlẹ nigba ti oun fi ṣejọba. Gbogbo eleyii ti fi han Buhari pe Ọbasanjọ ko ni i gba lẹrọ, afi ki awọn fi ọwọ to le mu un. Ọkunrin naa ti kọkọ sọ pe Ọbasanjọ n halẹ lasan ni, ṣugbọn nigba to ri ibi ti ọrọ n lọ yii, o ni gbogbo ọna ni ki awọn ọmọ oun wa lati fi da Ọbasanjọ lẹkun.

Iyẹn gan-an lo fa Ọbasanjọ paapaa si irin nla. Oun naa ti ri i pe bi agbara ijọba ba fi tun bọ si ọwọ Buhari, afaimọ ko ma ba ẹyin yọ soun, eyi lo si fa a ti oun naa fi ko si irin ojoojumọ, to n sọ fawọn eeyan pe, Buhari fẹ o, o kọ o, awọn gbọdọ le e lọ ni ọdun 2019. Ọrọ naa le debii pe Ọbasanjọ ti mura lati ba gbogbo awọn ọta rẹ tẹlẹ ṣe ọrẹ, o mura lati dariji awọn ti wọn ti ṣẹ ẹ tẹlẹ, o si ṣetan lati bẹ awọn ti oun naa ṣẹ, o ni ọrọ to wa nilẹ yii, iṣẹ gbogbo awọn ni, awọn gbọdọ ṣe e, ki Buhari ṣa maa lọ. Awọn ọrẹ Abubakar Atiku to jẹ igbakeji rẹ nigba kan ti bẹrẹ si i bẹ ẹ, wọn ni ko ti ọkunrin naa lẹyin, nitori Atiku nikan lo da bii pe o lowo ati agbara, o si mọ-ọn-yan rẹpẹtẹ nilẹ Hausa lati le koju Buhari ni asiko ibo 2019, wọn ni nigba ti ẹgbẹ Ọbasanjọ to da silẹ ko ti i faayan kalẹ, ki wọn fa Atiku kalẹ ko du ipo aarẹ.

Bo tilẹ jẹ pe Ọbasanjọ ti n leri tẹlẹ pe o di ẹyin igbin, ka too fi ikarawun rẹ ha ikoko, pe bi oun ba ṣi wa nitosi, Atiku ko ni i jẹ aarẹ loju oun, sibẹ, bi nnkan ti n lọ yii, oun Ọbasanjọ ko le si ọkunrin naa mọ, nigba ti Ọbasanjọ si pariwo nijọsi pe Buhari fẹẹ mu oun pamọ, Atiku lo kọkọ sọrọ pe Buhari ko to bẹẹ, pe ko tilẹ sẹni to to bẹẹ, afi tẹni to ba fẹ ki Naijiria parẹ. Eleyii dun mọ Ọbasanjọ ninu, o si jọ pe inu rẹ ti n yọ si ọkunrin Adamawa naa. Ohun ti ko sẹni to ti i ri idi rẹ fi mulẹ ni boya ninu ẹgbẹ ADC ti Ọbasanjọ da silẹ ni wọn yoo ni ki Atiku maa bọ ni o, abi Ọbasanjọ yoo paṣẹ ki gbogbo awọn ọmọ ADC rọ wọ inu PDP pada, nigba to jẹ ibẹ naa kuku ni gbogbo wọn ti jade lọ. Ṣugbọn ohun to n dun mọ awọn eeyan ninu ju bayii ni pe inu Ọbasanjọ n yọ si Atiku, ati pe baba naa ti ṣetan lati ba awọn ti ki i ba ṣe tẹlẹ ṣe.

Eyi to tilẹ ṣẹlẹ lọjọ Abamẹta, Satide, to kọja yii ya awọn eeyan lẹnu gan-an. Obasanjọ ṣepade pẹlu awọn agbaagba Yoruba, nnkan iyanu gbaa lo jẹ. Idi ni pe lati ọjọ to ti pẹ ni Ọbasanjọ ti koriira awọn ti wọn n pe ara wọn ni Afẹnifẹre, ko fẹran ẹgbẹ naa rara, yoo ni awọn ọmọlẹyin Awolọwọ, to jẹ loju wọn, awọn nikan ni wọn maa n ro pe awọn lọgbọn, awọn to ku ko gbọn mọ. Ki i ba wọn ṣe. Awọn naa ko fẹran rẹ, wọn ki i ba a ṣe, wọn ni ki i ṣe ara wọn, awọn mi-in yoo si sọ pe ki i ṣe ojulowo Yoruba, nitori lati ọjọ to ti n ṣejọba rẹ, ko fi ti Yoruba ṣe. Ija naa le si i lẹyin ọdun 1999 ti awọn Afẹnifẹre fa Olu Falae kalẹ lati du ipo aarẹ, to si koju Ọbasanjọ, ṣugbọn to jẹ Ọbasanjọ lo pada wọle. Ọbasanjọ ko dariji wọn, iyẹn lo fi fa Bọla Ige mọra. Awọn naa ko dariji i, iyẹn ni wọn fi ba Bọla Ige ja.

Ṣugbọn ni ọjọ Satide to kọja yii, ija naa pari pata. Ọbasanjọ lọ si ile Oloye Ayọ Adebanjọ, ẹni to ku ti a le pe ni Arole Awolọwọ, nitori ninu awọn ti wọn ba Awolọwọ ṣiṣẹ ni, oun lo dagba ju gbogbo awọn to ku lọ. Ki i ṣe baba yii nikan lo wa nibẹ lati gba Ọbasanjọ lalejo, awọn aṣaaju Yoruba, paapaa awọn ti wọn n pe ni Afẹnifẹre, ati awọn mi-in naa ti ko si lara wọn, ṣugbọn ti wọn jẹ olori ẹgbẹ Yoruba kaakiri. Ṣupọ Ṣonibare, Fẹmi Okurounmu, Amos Akingba. Pastor Tunde Bakare. Ọjọgbọn Banji Akintoye, Tokunbọ Awolọwọ-Dosumu, Oluṣẹgun Mimiko, Abraham Akanle ati Yinka Odumakin, alukoro fun ẹgbẹ Afẹnifere. Awọn wọnyi ki i ṣe ẹni ti Ọbasanjọ maa n fẹẹ ri tẹlẹ, ṣugbọn ina ti jo de ori koko bayii. Wọn ṣe ipade naa, wọn ti ilẹkun mọri, nigba ti wọn si jade, Baba Adebanjọ sọ pe ko si ohun meji ti ipade awọn da le lori ju ki Yoruba fohun ṣọkan lasiko yii lọ.

Ti gbogbo awọn yii le ma jọ ẹlomi-in loju ju ti awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP kan ti wọn wa nipade naa lọ. Otunba Gbenga Daniel ni ọga pata fun igbimọ to n ṣeto idibo Atiku ninu PDP, o wa nipade yii o. Bẹẹ ni Ọtunba Oyewọle Fasawe, ọkan ninu awọn ti wọn ti n ba Ọbasanjọ bọ lati ọjọ yii wa pẹlu Akin Ọṣuntokun to jẹ akọwe ipolongo fun ẹgbẹ ADC, ẹgbẹ awọn Ọbasanjọ tuntun, ṣugbọn ti ko ti i fi ẹgbẹ PDP silẹ tan patapata. Ohun ti eyi fihan ni pe bi ipade naa ṣe ri, awọn ti wọn jẹ aṣoju Atiku nilẹ Yoruba wa nibẹ, bi wọn ko si tilẹ ti i sọrọ pe Atiku ni wọn yoo ti lẹyin, o jọ pe awọn ọmọ rẹ yoo mọ ohun ti wọn ba ṣe, ati idi ti wọn ṣe ṣe e. Baba Adebanjọ ni awọn ko ni i fi aaye silẹ lati jẹ ki ẹni kan ṣoṣo ba orilẹ-ede yii jẹ, nitori ti gbogbo wa ni, bi ko si ṣe ni i si ẹni kan ti yoo fi ọwọ pa Yoruba rẹ lawọn tori ẹ ṣepade awọn.

Ki Ọbasanjọ too wa si ipade yii lo ti kọkọ ya ọdọ Oloye Ọlabode George, ọkan ninu awọn ọmọlẹyin rẹ ti wọn ti jọ ṣiṣẹ nijọsi, ṣugbọn ti wọn pada ja, olori ẹgbẹ PDP ni gbogbo ilẹ Yoruba nigba kan. Loootọ Ọbasanjọ lọọ ki i nitori ọmọ rẹ to ku ni, ṣugbọn wọn sọrọ mi-in lẹyin iyẹn, nitori nibẹ naa ni wọn ti pari ija to ti wa laarin wọn lati ọdun yii wa. Kia ni Bọde George si ti gbe ẹwu wọ, to ni oun yo tẹle ọga oun lọ sibi to ba n lọ. Ọbasanjọ si ti sọ pe ko si ibi meji ti oun n lọ ju ọna ti awọn yoo fi le Buhari lọ ni 2019, o sọ fun Bọde ati awọn to ku pe iṣẹ kan ṣoṣo to wa lọwọ oun ree, iṣẹ ti gbogbo awọn si gbọdọ ṣe ni ki awọn too tilẹ sọrọ ohun mi-in rara. Baba naa sọ fawọn tirẹ pe ki wọn mura silẹ de ohunkohun to ba fẹẹ ṣẹlẹ, nitori bi Buhari fẹ bi ko fẹ, yoo lọ dandan ni.

(57)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.