Ọbasanjọ lọ s’Amẹrika, o ṣe ohun tolori ijọba ologun Naijiria kankan ko ṣe ri

Spread the love

Ariyanjiyan maa n wa laarin awọn onpitan ni Naijiria yii, ọrọ naa si maa n fẹẹ dija laarin wọn paapaa. Ọrọ naa ni pe ta ni olori ijọba Naijiria to kọkọ lọ si orilẹ-ede Amẹrika lati ki wọn lọhun-un, ko si ba aarẹ wọn lalejo. Bi awọn eeyan kan ti n sọ pe Tafawa Balewa ni, bẹẹ ni awọn kan n sọ pe ki i ṣe Balewa, Oluṣẹgun Ọbasanjọ, gẹgẹ bii olori ologun ijọba Naijiria lo kọkọ lọ si orilẹ-ede naa, to si ki aarẹ wọn, ti wọn jọ sọrọ, ti wọn si jọ ṣere, ninu oṣu kẹwaa, ọdun 1977. Loootọ ni Ọbasanjọ lọ si ọhun lọjọ naa, Aarẹ Amẹrika igba naa, Jimmy Carter, lo wa lọ sọhun-un, oun lo gba a lalejo, ti wọn si di ọrẹ lati igba naa lọ. Ṣugbọn bo ba jẹ ti pe ki olori ijọba lọ si Amẹrika ni, Tafawa Balewa lo kọkọ lọ si ọdọ awọn oyinbo yii, alejo ti wọn ṣe fun un si le debii pe kaakiri agbaye ni wọn ti royin pe olori ijọba Naijiria lọ s’Amẹrika.

Laye ijọba John Kennedy ni, oun ni olori ijọba wọn l’Amẹrika, funra ẹ naa lo si kọwe si Balewa pe oun fẹẹ ri i. Igba ti oun naa n lọ, ko lọ loun nikan, o mu awọn minisita rẹ dani, awọn bii Wachukwu, Shehu Shagari ati awọn mi-in bẹẹ bẹẹ lọ. N lawọn oyinbo ba duro de e ni papa-ọkọ ofurufu ibẹ, wọn n reti rẹ, ọrọ naa si ti di ohun ti gbogbo ilu paapaa mọ, wọn n gbe iroyin rẹ kaakiri pe olori orilẹ-ede ti awọn eeyan dudu ti pọ si julọ ni gbogbo agbaye n bọ ni Amẹrika, ki gbogbo ilu dide lati gba a lalejo. Fun odidi ọjọ meji gbako ni Kennedy paapaa fi pa gbogbo iṣẹ ilu ti lọdọ wọn, to jẹ Balewa yii nikan lo n mu kiri, alejo naa si miringidin debii pe titi doni ni akọsilẹ ati aworan irin-ajo naa wa nile ijọba Amẹrika, afi bii igba pe Naijiria ju bẹẹ lọ. Ati pe ni tootọ, loju wọn nigba naa, orilẹ-ede nla ni Naijiria i ṣe.

Ṣe a ṣẹṣẹ gba ominira nigba naa ni, awọn ilu aye gbogbo si ti nigbagbọ pe Naijiria yoo tete goke agba, ati pe orilẹ-ede naa yoo di nla kiakia. Laye igba yii, Britain, iyẹn ilu oyinbo to ko wa lẹru lawa gba ni baba, ohun gbogbo ti a n ṣe, ọwọ wọn la n wo lati ṣe e, ko si si orilẹ-ede mi-in to ṣe pataki loju Naijiria lasiko yii ju Great Britain lọ. Koda, eto ẹkọ wa, bakan naa lo jọ ri si ti ilu oyinbo yii, London lawọn eeyan wa ti n lọọ kawe, ko sẹni ti i de Amẹrika nigba naa, nitori sabukeeti wọn ki i wulo ni Naijiria, beeyan ba kawe ni Amẹrika to ba pada wa sile, bii ẹni ti ko kawe lawọn eeyan waa yoo ti maa ṣe e, wọn ni iwe Amẹrika ko lankuuri, wọn ni wọn ko mọwe bii London, ẹni to ba si mọ pe oun fẹẹ kawe gidi, London lo ti gbọdọ kawe rẹ, bi bẹẹ kọ, to ba pada wa sile, yoo ṣoro fun un lati ri iṣẹ ijọba ṣe.

Amẹrika naa ko sinmi, wọn n wa awọn orilẹ-ede gidi, paapaa awọn ti wọn ṣẹṣẹ gbominira kunra, ki awọn naa le lawọn orilẹ-ede ti wọn yoo jọ maa ṣe. Ohun to jẹ ki wọn fẹẹ mu Naijiria lọrẹẹ ree, nigba ti wọn si ri i pe orilẹ-ede naa ṣẹṣẹ gbominra, wọn sare si i, Kennedy pe Balewa pe ko maa bọ, nigba ti ko tilẹ ti i pe ọdun kan ti Naijiria gba ominira rẹ. Ọjọ kin-in-ni, oṣu kẹwaa, 1960, ni Naijiria gba ominira, nigba ti yoo si fi to oṣu kẹta, ọdun 1961, lẹta ti de lati Amẹrika pe Kennedy fẹ ki Balewa ti i ṣe olori ijọba Naijiria waa ṣe abẹwo sọdọ awọn, o ni ko maa bọ ki awọn jọ ṣilẹkun ajọṣe gidi. Ohun to mu Balewa lọ sibẹ lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu keje, ọdun 1961 yii ree, o si wa nibẹ titi di ọjọ kẹtadinlọgbọn, o n wọle, o n jade, bo ṣe wu u lọdọ Kennedy. Nidii eyi, awọn ti wọn n sọ pe Balewa lo kọkọ lọ si Amẹrika ko jẹbi.

Ṣugbọn ibi ti ọrọ yii ti ruju diẹ ni pe nigba ti Balewa n ṣejọba yii, aye oloṣelu ni, eto ijọba ti wọn si ṣe ni pe Balewa ki i ṣe olori Naijiria, olori ijọba lasan ni. Nigba naa, iyatọ wa laarin olori ijọba ati olori orilẹ-ede. Gẹgẹ bo ti ṣe wa titi doni yii ni United Kingdom ti wọn n pe ni Great Britain tẹlẹ, to jẹ pe Ọba oyinbo, iyẹn Queen, ni olori orilẹ-ede naa, to si jẹ ohun gbogbo ti wọn ba n ṣe, orukọ Queen yii ni wọn fi n ṣe e, bẹẹ lo jẹ nigba naa to jẹ ọtọ ni olori Naijiria gẹgẹ bii orilẹ-ede, ọtọ ni olori ijọba. Nnamdi Azikiwe ni olori Naijiria, oun ni Purẹsidẹnti, Balewa ni olori ijọba, oun ni Prime Minister. Eyi lo ṣe jẹ pe nigba ti wọn ba dibo ti wọn ba fẹẹ pe ẹni to wọle lati waa ṣejọba olori Naijiria, ẹni to ni orilẹ-ede naa ni yoo pe awọn to ba fẹ ko waa ṣejọba orilẹ-ede toun. Azikiwe lolori Naijiria, ki i ṣe Balewa, Balewa lolori ijọba.

Ṣugbọn aye ologun ko ri bẹẹ, awọn ti ṣe ofin ti wọn ti fi pa eyi to wa nilẹ rẹ pata, wọn si ti lo agbara ibọn lati sọ pe ẹnikẹni ko gbọdọ sọrọ, ẹni to ba sọrọ to le da oju ijọba de, tabi to le da ilu ru, bi wọn ba ti gbe e, inu ajaalẹ ni wọn yoo ti i mọ, iyẹn ti wọn ko ba ṣeto lati yinbọn pa a. Nitori bẹẹ, ẹni to ba n ṣe olori ijọba Naijiria naa ni olori ilu: oun ni olori Naijiria, oun naa ni olori ijọba Naijiria; oye meji loun nikan papọ lẹẹkan. Ohun to n fa ariyanjiyan laarin awọn eeyan ti wọn n pitan ilẹ yii niyẹn, nitori wọn ko le ya olori ijọba sọtọ, ati olori Naijiria. Ṣugbọn bi a ba ni ki a da a silẹ ka tun un ṣa, aṣaaju Naijiria akọkọ ti yoo de Amẹrika, Balewa ni. Ṣugbọn bo ba jẹ ti olori Naijiria to jẹ ologun ni o, ko si ṣọja olori Naijiria kan to lọ si Amẹrika ri, Ọbasanjọ ni akọkọ wọn, oun lo ṣe ohun tawọn ọga rẹ ninu iṣe naa ko ṣe ri.

Ohun to mu ọrọ naa lokiki bẹẹ ni pe ki i ṣe Ọbasanjọ ni ṣọja akọkọ ti yoo ṣe olori Naijiria. Akọkọ wọn ni Aguiyi Ironsi, oṣu mẹfa pere lo lo, wahala to si wa ni Naijiria nigba naa ko jẹ ki oun tilẹ le lọ sibi kan. Lẹyin tirẹ ni Yakubu Gowon, oun si pẹ lori oye yii, bẹẹ lo de ọpọlọpọ awọn orilẹ-ede aye yii, aimọye igba lo si lọ si London ati awọn ilu oyinbo mi-in, ṣugbọn ko de Amẹrika, nitori ko jọ pe o fẹ kinni kan lati ba wọn ṣe. Lẹyin tirẹ ni Muritala de, Muritala lo si kọkọ fihan pe oun ko fi taratara gba iwa ati iṣe awọn ara Britain yii, o fẹẹ wa awọn ọrẹ tirẹ siwaju. Ṣugbọn oun naa ko pẹ lori oye yii, ko si ti i ronu lati lọ si Amẹrika rara ti ọlọjọ fi de ba a. Nigba naa ni Ọbasanjọ de, ọdun kan ati oṣu kẹjọ lẹyin to gbajọba lo si lọ sibẹ, o yọ si wọn l’Amẹrika ganboro, agbada nla lo wọ lọ.

Ko too di ọjọ to lọ sọhun-un ni ariwo ti n lọ lọtun-un losi, iroyin ti kaakiri ilu pe Ọbasanjọ n lọ si Amerika, ohun to si n da a duro ni awọn ọmọ igbimọ aṣoju-ṣofin ti yoo jiroro lori ọrọ ofin Naijiria ati iru oṣelu alagbada ti wọn yoo ṣe. Nigba to ti ṣe ifilọlẹ naa tan lọjọ kẹfa, oṣu kẹwaa, 1977 yii, lo ti bẹrẹ ipalẹmọ, o loun n lọ si Amẹrika lati lọọ ki wọn. Ṣe ọrọ naa ni bo ti jẹ tẹlẹ, nitori nigba ti Jimmy Carter ti wọle gẹgẹ bii olori orilẹ-ede Amẹrika ni 1976 lo ti sọ pe awọn Afrika loun fẹẹ ba ṣe, o si fi Naijiria ṣe aṣaaju awọn orilẹ-ede gbogbo nibẹ. Eyi lo fa a to jẹ ni gbara to gbajọba, laarin ọsẹ kan naa lo ran Andrew Young ti i ṣe minisita fun ọrọ ilẹ okeere fun un pe ko tete waa lọ si awọn orilẹ-ede pataki ni Afrika, ko bẹrẹ lati Naijiria, ko si sọ fun wọn pe ọrẹ pataki ni ijọba oun Jimmy Carter fẹẹ ba Afrika ṣe.

Eleyii dun mọ Ọbasanjọ ninu pupọ, agaga nigba ti Andrew Young de, ti toun pẹlu rẹ jọ sọrọ, ti wọn si ri i pe iwa awọn ba ara awọn mu. Andrew Young yii lo tete pada sile, to si sọ fun Carter ko kọwe ipe si Ọbasanjọ, ko jẹ ki awọn gba a lalejo, nitori bi awọn ba ti gba a lalejo, bii igba ti awọn ti yanju iṣoro yoowu ti awọn ba ni ni Afrika ni. Ọbasanjọ gbawe, inu oun naa dun, o si ni oun yoo lọ sibẹ dandan. Lati igba naa lo ti bẹrẹ ipalẹmọ rẹ wẹrẹwẹrẹ, to n reti igba ti aaye yoo wa daadaa ti oun yoo le lọ. Kinni naa ko ṣee ṣe ṣaa titi di ọjọ kẹwaa, oṣu kẹwaa, ọdun 1977. Ọjọ naa lawọn eeyan Amẹrika sare jade lati waa wo olori ijọba ati olori Naijiria, wọn fẹẹ mọ ẹni ti wọn n pe ni Ọbasanjọ funra rẹ, nitori wọn ti gbọ pupọ ninu awọn ohun to ṣe, ati pupọ ninu ohun to ṣẹlẹ si Naijiria to ti wa.

Awọn oyinbo ti gbọ oriṣiiriṣii iroyin nipa ọkunrin ṣọja naa, wọn si fẹẹ foju ara wọn ri awọn ohun ti awọn ti gbọ. Wọn ni Ọbasanjọ ki i sọrọ pupọ pẹlu awọn oniroyin, ati pe ki i pariwo, wọn si ni ki i ko ero rẹpẹtẹ tabi mọto pupọ lẹyin to ba n lọ si irin-ajo, ati pe aṣọ olowo pọọku lo n wọ kiri. Gbogbo awọn nnkan yii lo jọ awọn ara Amẹrika loju, wọn si fẹẹ ri ọkunrin ti wọn ti gbọ iroyin rẹ yii, paapaa nigba to tun jẹ ọga awọn ṣọja ni. Oun naa si ti mura wọn, o ni wọn yoo ri oun wo bii iran. Ko da lọ si irin-ajo ọhun o, o kan jẹ ko ko ero rẹpẹtẹ lẹyin ni. Nigba to n lọ, o mu Gomina Ayọdele Balogun ti ipinlẹ Ogun dani, ati Dan Suleman to n ṣe gomina wọn ni Plateau nigba naa, pẹlu awọn eeyan diẹ mi-in, o ni oun ko fẹ ero rẹpẹtẹ. Bẹẹ ni wọn de Amẹrika lọjọ kọkanla, oṣu kẹwaa, ọdun 1977, nibi ti Jimmy Carter ti pade ẹ.

Awọn ti lilọ ti Ọbasanjọ lọ si Amẹrika yii dun mọ ninu ju ni awọn aṣofin alawọ-dudu orilẹ-ede naa, gẹgẹ ni wọn n gbe e, ti wọn si ni afi ko waa ba awọn sọrọ lọtọ, awọn ni apejẹ pataki ti awọn yoo ṣe fun un. Wọn ṣe e fun un loootọ, wọn si jẹ ko ba wọn sọrọ, Ọbasanjọ si sọ oju abẹ nikoo pe ko siyatọ kan laarin eeyan dudu ati eeyan funfun, ẹkọ ti kaluku ba ni ni yoo sọ ọ di ohun yoowu to ba da lawujọ, nitori ko sẹdaa ti ko lọgbọn lori, bi kaluku ba ti lo ọgbọn ori rẹ, ati anfaani ti kaluku ba ni lo maa n ta wọn yọ. Eleyii dun mọ awọn aṣofin alawọ-dudu naa ninu, paapaa nigba ti wọn ri i bi awọn oyinbo ti n gbe Ọbasanjọ gẹgẹ, wọn ni ṣe awọn naa ri i pe eeyan gidi wa ninu awọn alawọ-dudu, ati pe Afrika ki i ṣe ilu awọn ẹranko. Awọn oniroyin wọn paapaa bẹrẹ si i sọrọ jade, wọn ni Naijiria ni orilẹ-ede ti Amẹrika gbọdọ ba ṣe.

Ohun to tun waa ṣẹlẹ ni pe irin-ajo Ọbasanjọ yii bọ si asiko ti awọn ajọ orilẹ-ede agbaye n ṣepade wọn, iyẹn awọn UN, wọn si pe Ọbasanjọ ko waa ba awọn sọrọ nibẹ, awọn naa fẹẹ gbọ ohun lati Afrika. Ṣugbọn ohun ti wọn ro kọ ni wọn tọ wo, Ọbasanjọ ko ilaali fun gbogbo wọn ni. O ni awọn alawọ-funfun yii n wo awa ọmọ orilẹ-ede alawọ-dudu bii ilu ti ko le nilaari, wọn si maa n da kun wahala ati iṣoro to ba n ṣẹlẹ laarin awọn orilẹ-ede ti eeyan dudu ba ti n ṣejọba wọn. O waa sọ fun wọn pe iwa ti wọn n hu yii o, ki wọn maa mura si i, pe niwọn igba ti ko ba ti si alaafia ni awọn orilẹ-ede alawọ-dudu, ti awọn eeyan ibẹ ko sinmi, ti iṣẹ si n yọ wọn lẹnu, bo pẹ bo ya, ọrọ naa yoo di iṣoro ti yoo ko idaamu gidi ba awọn ilẹ alawọ-funfun naa, aibalẹ ọkan naa yoo si kari gbogbo aye. Awọn oyinbo paapaa gbọ, wọn runra lori ijọba wọn.

Ṣe asiko naa ni ija buruku n lọ ni orilẹ-ede South Afrika, nibi ti awọn oyinbo alawọ-funfun ti lọọ gba ilẹ awọn eeyan dudu ibẹ, ti wọn si taku pe awọn ko ni i lọ kuro nibẹ, nitori nibẹ ni wọn ti gbe bi awọn, loootọ alejo ni baba awọn, ṣugbọn awọn ti di ọmọ oniluu, ko si sẹni to le le awọn jade. Bo ba jẹ lori iyẹn nikan ni wọn ti duro, ko sẹni ti yoo ba wọn ja, ko si sẹni ti yoo le wọn jade. Ṣugbọn wọn n ṣe aburu kun aburu, wọn n huwa ibajẹ ti ko lẹgbẹ ni. Iwa ti ko daa ti wọn n hu ju ni pe wọn ni awọn lawọn gbọdọ maa ṣejọba le awọn eeyan naa lori, nitori awọn ko ni i gba ki ẹni dudu ṣejọba lori awọn eeyan funfun. Wọn ni loootọ lawọn waa ba wọn niluu wọn ni, ṣugbọn awọn lawọn yoo maa paṣẹ ibẹ, awọn lawọn yoo maa ṣejọba. Koda, wọn ba a debi ti wọn ni awọn eeyan dudu ko le dibo, awọn alawọ-funfun nikan lo le dibo nibẹ.

Paripari rẹ ni pe wọn ni awọn ko le jọ gbe adugbo kan naa pẹlu awọn eeyan dudu yii, awọn yoo maa gbe adugbo ọtọ ni, adugbo ti awọn si n gbe yii, dudu kankan ko gbọdọ ba ibẹ kọja, dudu to ba ba ibẹ kọja, ẹwọn ni yoo ṣe. Wọn ni awọn ko le gba ki awọn ọmọ awọn ati awọn ọmọ eeyan dudu maa lọ sileewe kan naa papọ, wọn ni ọtọọtọ ni ileewe ti wọn yoo lọ, ọmọ alawọ-dudu kan ko gbọdọ de ileewe awọn alawọ-funfun. Eewọ ni ki wọn jọ lo ọsibitu kan naa paapaa, wọn ko si gbọdọ lo ohunkohun to ba jẹ tijọba ti awọn alawọ-funfun ba n lo, ọtọọtọ ni wọn n ṣe ohun tiwọn fun wọn, ohun ti wọn yoo si ṣe fun wọn ko ni i daa bii eyi ti wọn ba ṣe funra wọn. Awọn eeyan dudu ti wọn lọ sita lati kawe bii Nelson Mandela, ti wọn si bẹrẹ lati gba orilẹ-ede wọn lọwọ awọn amunisin yii, ẹwọn ni wọn rọ wọn da si, wọn ko jẹ ki wọn jade.

Ọrọ yii ni Ọbasanjọ n sọ fawọn oyinbo yii pẹlu ibinu, o ni ohun ti wọn n ṣe ko daa to, nitori kaka ki awọn orilẹ-ede alawọ-funfun aye dide, ki wọn ba wọn ja ni South Afrika, ki wọn jẹ ki awọn ọmọ oniluu ṣe ilu wọn, ki wọn si le awọn alawọ-funfun to fipa gba ilu oniluu yii sigbo, niṣe ni wọn n fọwọ pa wọn lori, ti wọn si n sọ pe ko si ohun to buru ninu ohun ti wọn n ṣe, ati pe awọn iwa kan wa ti wọn n hu to ba ofin mu. Ọbasanjọ ni bo ba jẹ bẹẹ ni wọn n ṣe, wọn ko ni i ri ojuure awọn eeyan dudu aye, ati pe nigba ti ọrọ naa ba de oju rẹ tan, yoo ṣoro fun wọn lati ri iranlọwọ kankan lati ọdọ awọn. Ọrọ naa mu awọn eeyan yii lọkan nigba ti Ọbasanjọ n yẹ ẹ lu wọn, bi awọn kan ti n runra ni awọn mi-in fa oju ro, bo si tilẹ jẹ kinni naa ka awọn mi-in lara inu awọn mi-in dun si i pe ododo ni olori Naijiria naa sọ.

Eleyii mu okiki Ọbasanjọ gbilẹ kaakiri ilu awọn oyinbo yii, lati Amẹrika to ti sọrọ naa ni wọn si ti gburoo rẹ de orilẹ-ede aye gbogbo. Nigba ti yoo fi pada wa sile paapaa lẹyin odidi ọjọ marun-un to lo nibẹ, okiki rẹ ti kan si i ju bo ti ṣe wa tẹlẹ lọ, awọn eeyan si n gbedii fun Ọbasanjọ, wọn ni oun ni olori Naijiria akọkọ to lọ si Amẹrika, o ṣe ohun ti awọn ọga rẹ ko le ṣe.

 

 

 

 

 

(56)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.