Ọbasanjọ daro Shagari, aarẹ Naijiria igba kan

Spread the love

Bi gbogbo eeyan to mọ aarẹ Naijiria laarin ọdun 1979 si 1983, iyẹn Alaaji Shehu Usman Shagari, ṣe n daro iku ẹ, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ to gbejọba fun un lọdun marundinlogoji sẹyin naa ba wọn kẹdun, o si kọwe ibanikẹdun ranṣẹ sawọn ẹbi Shagari, nipinlẹ Sokoto.

Alẹ ọjọ Ẹti, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kejila, ni Shagari jade laye lẹni ọdun mẹtalelaaadọrun-un (93). Ọsibitu ijọba apapọ to wa niluu Abuja ni aarẹ tẹlẹ naa dakẹ si lalẹ ọjọ Jimọ ọhun, aisan ranpẹ to ni i ṣe pẹlu ogbo ni wọn lo mu Alaaji Sheu Shagari lọ.

Ninu lẹta Ọbasanjọ, o ni oun ri oloogbe yii bii ẹni to gba ipo lọwọ oun nilana ijọba tiwa-n-tiwa, bo tilẹ jẹ pe ologun loun nigba naa. O ṣapejuwe Shagari bii ẹni to kopa pupọ ninu oṣelu Naijiria ṣiwaju ominira ati lẹyin ti ilẹ yii gba ominira tan.

Ọbasanjọ sọ pe igbesi aye eeyan pataki, ẹni to ni bibi ire ni oloogbe yii gbe, asiko to si ku si jẹ igba ti Naijiria nilo awọn agba oloṣelu to yẹ ko maa tọ awọn eeyan sọna nipa oṣelu awa-ara-wa.

Ọbasanjọ lo gbejọba fun Shagari lọdun 1979, eyi ti oloogbe naa ṣe di 1983, nigba ti Aarẹ Muhamaadu Buhari ati Oloogbe Tunde Idiagbọn, lo ti ologun fun un, ti wọn gba a lọwọ rẹ.

Ọjọ Satide ti i ṣe ọjọ keji to ku ni wọn sin in si Abule Shagari, nipinlẹ Sokoto. Gomina ipinlẹ naa, Aminu Tambuwal, lo tẹwọ gba oku naa nigba to balẹ lati papakọ ofurufu Nnamdi Azikwe l’Abuja, ko si pẹ ti wọn fi gbe baba naa si koto nilana ẹsin Islam.

Ọdun 1925 ni wọn bi Aliu Usman Shehu Shagari si abule Shagari, nipinlẹ Sokoto. O ṣe tiṣa fungba diẹ ko too darapọ mọ oṣelu. O ṣiṣẹ kaakiri lẹka oṣelu Naijiria ko too ṣiwọ, awọn eeyan si ri i bii ẹni to ṣe iwọn to le ṣe kọlọjọ too mu un lọ.

 

 

 

(10)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.