O tun ṣẹlẹ: ATIKU NI YOO KOJU BUHARI O

Spread the love

N lawn aaaju PDP ba n jo, ni wn n y

Wn ni awn ti ko wahala ba wn ninu APC

Gbangba ti dẹkun bayii o, kedere si ti bẹ ẹ wo; ara ile ti gbọ, wọn ti ranṣẹ si ara oko pe Olori ijọba Naijiria lọwọlọwọ bayii, Aarẹ Muhammadu Buhari, ati Alhaji Atiku Abubakar ni wọn yoo jọ koju ara wọn ninu ibo aarẹ to n bọ lọdun 2019 yii o. Ẹgbẹ APC ti fa Buhari kalẹ, ẹgbẹ PDP si ti fa Atiku naa kalẹ, bẹẹ ni awọn mejeeji ki i ṣe ajoji ara wọn tẹlẹ, wọn ki i ṣe ọmọde ninu iṣejọba Naijiria paapaa, eegun to eegun lawọn mejeeji, ọkunrin si to ọkunrin. Alaroye gbọ pe bi inu awọn aṣaaju ẹgbẹ PDP ti n dun ti wọn n sọ pe awọn ti ri eeyan nla ti yoo koju Buhari ninu ibo naa, bẹẹ ni inu awọn aṣaaju ẹgbẹ APC kan bajẹ pata, nitori wọn ti ro pe Atiku kọ ni i yoo wọle, wọn n ro pe Bukọla Saraki tabi Aminu Tambuwal, tabi Rabiu Kwakwanso ni, ibi ti wọn fi ọkan si gan-an niyẹn.

Wọn ni bo ba jẹ awọn mẹta yii ni, ẹrin lawọn iba maa rin, nitori ko ni i ṣoro fun Buhari lati fibo tẹ wọn pa. Awọn eeyan naa sọ pe awọn mọ agbara Tambuwal, awọn mọ ti Kwankwaso naa, awọn si mọ ibi ti agbara Saraki mọ. Ṣugbọn ni ti Atiku, awọn mọ pe agbara to wa lọwọ rẹ ga, eyi lo si fa idunnu nigba ti wọn n gbọ pe awọn gomina ipinlẹ Rivers, Ezenwo Nyesom Wike ati t’Ekiti, Ayọ Fayoṣe, ti panupọ pe Tambuwal lawọn yoo mu, ti awọn aṣofin si ti sọ pe Saraki lawọn n ba lọ. Gbogbo eyi ti jẹ ki wọn ro pe ko si bi Atiku yoo ti ṣe e, paapaa nigba ti wọn ko si gbọ orukọ rẹ mọ, ti ariwo rẹ ko si pọ laarin ẹgbẹ wọn ati nidii oṣelu mọ, ọkan wọn ti balẹ pe Atiku ko nibi kan ti yoo lọ, awọn ọmọ keekeekee ti ko lagbara to Buhari nidii oṣelu ni wọn yoo fa kalẹ, Buhari yoo si tẹ wọn pa lọwọ kan ni.

Koda, nibi ipade gbogbogboo ti awọn APC ṣe ni Abuja, nibi ti wọn ti fa Buhari kalẹ, alaga ẹgbẹ naa, Adams Oshiomhole, sọ oko ọrọ ranṣẹ si awọn PDP, o ni nibi ti wọn ti n ṣe laulau, ti wọn n daamu, wọn ko ti i mọ ẹni ti wọn yoo mu kalẹ ti yoo du ipo naa lorukọ ẹgbẹ wọn, bẹẹ awọn APC lawọn ṣe tawọn ni irọwọrọsẹ yii o. Ṣe lọjọ naa ni wọn yan Buhari, ti gbogbo eeyan APC si fọwọ si i pe oun nikan lawọn fẹ ko dupo, awọn ko fẹ ẹlomi-in ti yoo ba a du u, tabi ti yoo tiẹ duro pe oun fẹẹ woju ẹ, oun ni baba awọn, baba gbogbo Naijiria naa si ni. Ẹgbẹ APC kede lọjọ naa pe awọn miliọnu mẹẹẹdogun o din diẹ ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ APC ni wọn dibo, ibo ti wọn si di naa ni ti Buhari, wọn ni ko sẹlomi-in ti i ba yimiyimi dumi, Buhari naa nikan ni. Iyẹn ni ibo naa ko ṣe pẹ rara, loju ẹsẹ ni.

Ṣugbọn ti PDP yatọ diẹ, ibo naa gbomi gbẹyin, koda, o le koko bii oju ẹja ni. Fun odidi ọjọ mẹta ni wọn fi wa nidii ẹ, nitori ọjọ Ẹti, Furaidee, ni wọn ti bẹrẹ, wọn o si yanju rẹ titi di owurọ ọjọ Aiku ti i ṣe Sannde, lọjọ ti wọn yan Atiku bii ẹni ti yoo du ipo aarẹ lorukọ ẹgbe wọn. Nigba ti wọn kọkọ bẹrẹ ibo naa, bi wọn ti n dibo yii lọ, Saraki ni ẹnu kọkọ n kun, awọn eeyan ti wọn wa nibẹ n sọ pe ibo rẹ yoo ju ti awọn to ku lọ. Amọ nigba ti wọn dibo naa tan ti wọn n ka a, wọn ri i pe apoti awọn mẹta lo n kun julọ: ti Saraki, Tambuwal ati Atiku. Nibẹ ni awọn eeyan ti bẹrẹ si i ro kinni naa wo pe abi Atiku yoo ri ibo gidi mu loootọ. Ṣugbọn o, wọn mọ pe ko si iye ibo ti yoo ri mu ti yoo ju ti Saraki tabi Tambuwal lọ, nitori Wike ati awọn gomina kan wa lẹyin Tambuwal, Saraki si lawọn aṣofin.

Nigba ti wọn bẹrẹ si i ṣọ awọn ti wọn du ipo naa ati iye ibo ti wọn ri mu, onikaluku bẹrẹ si i sunraki lori ijokoo wọn. Ẹrin ni wọn kọkọ n rin nigba ti wọn darukọ awọn ti wọn n ka ibo wọn, ibo marun-un (5), pere ni Datti Ahmed ni; Jona Jang si ni ibo mọkandinlogun (19). Awọn eeyan ti ro pe David Mark to jẹ aarẹ ile-igbimọ aṣofn tẹlẹ tawọn eeyan ti ro pe yoo ja raburabu ko ri nnkan gidi mu, ipa lo fi ribo marundinlogoji, 35, niṣe lawọn eeyan si rẹrin-in nigba ti wọn darukọ rẹ pẹlu iye ibo to ri. Wọn ti tun waa ro pe Attahiru Bafarwa to n janu pe oun kan, Sokoto kan ni, oun kan, ilẹ Hausa kan ni, pe ibo toun nikan yoo mu nibi eto abẹle naa, ko sẹni ti yoo le sun mọ oun. Amọ nigba ti wọn ka ibo rẹ, marundinlaaadọta (45), ni gbogbo ẹ, iyẹn ni pe ko tiẹ mu ibo awọn eeyan lati ipinlẹ rẹ debi kan rara.

Alariwo ni Sule Lamido naa, ṣugbọn ibo mẹrindinlọgọrun-un lo ri, ẹni to si jẹ ọga awọn ọmọwe to wa laarin wọn ni Dankwabo, wọn si ro pe yoo ta biọbiọ ni, afi pe nigba ti wọn ka ibo rẹ, mọkanlelaaadọfa (111), pere ni. Nigba naa lawọn eeyan waa jokoo, wọn fẹẹ mọ ohun ti Kwankwaso fẹẹ mu, nitori ọkunrin algbara loun naa nilẹ Hausa, awọn eeyan to si ko wọ ilu Abuja lọjọ to n kede lati du ipo aarẹ yii ba awọn eeyan lẹru debii pe wọn ti ro pe yoo fa ilẹ ya ni Pọta yii ni, amọ ibo toun naa ti din meji ni ọgọjọ (158), nigba naa lawọn eeyan bẹrẹ si i ronu si Saraki, wọn ni ibo rẹ yoo ju ti gbogbo wọn lọ. Ootọ si ni, nigba ti wọn ja ibo tirẹ, kia lo ti kọja ti Kwankwaso, ni wọn ba tun n ka a lọ, ṣugbọn nigba ti wọn de ori okoolelọọdunrun o din mẹta (317), ibo naa duro.

Nibi yii lo ti waa ku Tambuwal pẹlu Atiku, awọn ti wọn mọ bo ti n lọ si ti sọ pe Tambuwal lo lọjọ naa, ko ni i pẹ ti yoo fi ta Atiku yọ. Wọn ka ibo tirẹ naa, ori ẹẹdẹgbẹrin o din meje (693), ni ibo tiẹ naa ku si, igba yii ni awọn eeyan too gba pe Atiku ni yoo gbe nnkan naa lọ, nitori ẹgbẹrun mẹta o le lawọn ọmọ ẹgbẹ ti wọn dibo lọjọ naa. Ko pẹ rara ti wọn ka ibo Atiku yii to fi ju ti Tambuwal lọ, nigba ti ibo rẹ si pe ẹgbẹrin (800), Saraki dide nibi to wa, o si ko awọn ti wọn jọ du ipo naa lẹyin, wọn lọọ ki Atiku pe o ku oriire. Igba ti wọn dibo naa tan, ibo Atiku le ni ẹgbẹrun kan ataabọ, o tun le mejilelọgbọn (1532), o si ta gbogbo awọn to ku yọ pata. Lẹsẹkẹsẹ ni ariwo si gbalu pe Atiku ni yoo koju Buhari.

Lẹsẹkẹsẹ lawọn aṣaaju APC bẹrẹ ipade, bo si tilẹ jẹ pe loootọ ni wọn ni kinni naa ko kan awọn, pe ọrọ naa ko dun awọn pẹẹ, sibẹ, bi wọn ti mura si ọrọ naa fi han gbangba pe ibi ti wiwọle Atiku ti mu wọn ko daa, o ba wọn lojiji pupọ. Kia lawọn naa ti bẹrẹ igbaradi tootọ tootọ, wọn ti gbe awọn irinṣẹ oriṣiiriṣii jade, awọn ti wọn si n ṣiṣẹ lori tẹlifiṣan, lori redio, ati awọn ti wọn wa lori ẹrọ ayelujara ti bẹrẹ lẹsẹkẹsẹ, ariwo ti wọn n wi naa ni pe Buhari daa ju Atiku lọ, ki ẹnikẹni ma dibo fun un. Amọ awọn Atiku ti mọ tẹlẹ, awọn si ti mura ija daadaa, awọn naa ti bẹrẹ igbaradi nla, wọn si ti ko irinṣẹ oriṣiiriṣii jade pẹlu, wọn ni bi Buhari ba gba inu ina, awọn yoo ba a gba a, bo si jẹ inu omi lo n lọ, awọn yoo ba a lọ, pe ko si kinni kan ti yoo ṣẹlẹ, wọn yoo jọ na an tan bii owo ni.

Ọrọ naa yoo ro ko too to, o digba naa na, ka too fọmọ Ọba f’Ọṣun.

(43)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.