O to gẹẹ, ọrọ Alaafin Ọyọ ni o

Spread the love

Nibi ti ọrọ oṣelu ilẹ yii wa bayii, ki awọn Ọba Yoruba ro o daadaa ki wọn too da si i, ẹni to ba si mọ pe oun ko mọ itan tabi ridii ọrọ ti yoo ba sọ, o dara ki tọhun sinmi, ka fi le ri nnkan to wa nilẹ yii yanju. Alaafin sọrọ kan lọsẹ to kọja, ọrọ naa si ni pe ki awọn eeyan ti wọn n ṣejọba bayii da ijọba pada si ẹlẹkun-jẹkun, nibi ti kaluku yoo ti na owo to ba pa, ti yoo si ṣeto idagbasoke adugbo rẹ gẹgẹ bi owo ati ohun ini to ba ni. Ọrọ naa n ka Alaafin lara, o ni bi wọn ba ṣedanwo, ti ọmọ Yoruba gba maaki 240, ti ọmọ Hausa si gba 120, wọn yoo mu ọmọ Hausa ṣaaju ọmọ Yoruba, wọn yoo si tun jọ ko wọn sinu kilaasi kan ni, bi aaye ko ba si si to, wọn yoo fi ọmọ Yoruba silẹ, wọn yoo mu ọmọ Hausa ni. Alaafin ṣalaye bo ṣe jẹ owo ti wọn ba n pa nilẹ Yoruba nibi ki i to ọmọ Yoruba lọwọ, awọn ti wọn ko pawo lọdọ tiwọn ni wọn yoo pin in. Iyẹn ni Alaafin ṣe ni ka pada si ‘Regional Government’, ijọba ti kaluku yoo maa ṣeto idagbasoke adugbo rẹ funra rẹ. Ohun ti gbogbo awọn eeyan ti ọrọ kan nilẹ Yoruba n ja fun ree, ohun ti a n beere lọwọ Buhari gan-an niyẹn. Awọn ti wọn ba n mu Buhari bọ nilẹ Yoruba, ki wọn beere lọwọ rẹ pe ki lo fẹẹ ṣe si wahala yii, ṣe o ti ṣetan lati tun ofin ilẹ yii ṣe. Atunto ti a n wi ree o. Amọ ki awọn ọba wa kan ma tori ipo ati ohun ti wọn ba n wa lọwọ ijọba kan sọ ọrọ ti yoo bi araalu ninu, ki wọn ma da si ohun ti wọn ko ba mọ, ki wọn fi ikunlukun pẹlu Alaafin, ki wọn le jọ mọ ohun ti wọn yoo ṣe ati awọn ọrọ ti wọn yoo sọ. Asiko ree ki Yoruba ja ara rẹ gba, ki ṣiṣẹ-ṣiṣẹ yee da bii ọlẹ, ki wọn yee fi owo wa jẹun, ki wọn si maa pe wa ni ọlẹ nigba tawa o ba ri ounjẹ jẹ. O ti to gẹẹ o! Ọrọ Alaafin Ọyọ ni.

(132)

1 Comment

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.