O ma waa ga o Awọn Fulani tun pa ọgọrun-un eeyan nipinlẹ Plateau

Spread the love

Nitori wahala to waye nipinlẹ Plateau ni Satide ọsẹ to kọja, nibi ti awọn Fulani ti ṣeku pa eeyan bii ọgọrun-un, ti ọkẹ aimọye si wa ni ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun, gomina ipinlẹ naa, Simon Lalong ti kede konile o gbele laarin aago mẹfa aarọ si mẹfa irọlẹ ni awọn ijọba ibilẹ mẹrin kan nipinlẹ naa. Ijọba Riyom, Burkin, Ladi ati Jos South ni ọrọ yii kan

Gẹgẹ bi ALAROYE ṣe gbọ, ṣe ni awọn Fulani darandaran ya wọ awọn abule bii ogun lawọn ijọba ibilẹ bii mẹrin, ti wọn si bẹrẹ si i pa awọn eeyan naa nipakupa lai ni idi kan. Awọn abule bii Xland, Gindin Akwati, Ruku, Nghar, Kura Falls, Kukuruku, Rakok, Kokand, Razat ati bẹẹ bẹẹ lo to jẹ ẹya onigbagbọ lo pọ nibẹ la gbọ pe wọn pọ ninu awọn to ba iṣẹlẹ naa lọ.

Alaga awọn to n ri si igbẹjọ nipa ọrọ to ba n dun araalu lọkan nile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa, Peter Gyendeng to wa lati ijọba ibilẹ Barkin Ladi ṣalaye pe niṣe ni wọn gba awọn eeyan naa lati pa awọn eeyan ijọba ọhun run, idojukọ naa ko si yatọ si ki eeyan gbe ogun si awọn.

O ni awọn to ku ju ọgorun-un ti awọn eeyan n pariwo lọ, o ni wọn yoo le ni ọgọrun-un meji daadaa nitori ni awọn ibi kan, awọn kan oku bii mọkanlelaaadọta, awọn ka mejilelọgbọn nibomi-in, oku tawọn si ti ri lojukoroju ti le ni ọgọrun-un meji daadaa. Bẹẹ lo ni awọn ko ti i dawọ kika rẹ duro. Ni nnkan bii aago mọkanla alẹ ọjọ Satide, ọsẹ to kọja ni ikọlu naa, eyi to sọ pe o tẹ siwaju di ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii waye.

Niṣe ni wọn ni awọn agbegbe ti iṣẹlẹ yii ti ṣẹlẹ kun fun oorun oku eeyan kaakiri, bẹẹ lọkẹ aimọye awọn mi-in si n pariwo pe awọn ko ti i ri awọn eeyan awọn.

Alukoro ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Plateau, John Akans, bu ẹnu atẹ lu ikọlu ti wọn ṣapejuwe gẹgẹ bii eyi to buru jai yii. Bẹẹ lo pe fun ajọ agbaye lati da si ọrọ yii ki wọn si gba awọn araalu naa silẹ lọwọ ijọba ti ko ri nnkan ṣe si ipaniyan to ti n waye nipinlẹ naa lati ọjọ yii wa.

Ninu ọrọ tiẹ, kọmiṣanna fun eto iroyin nipinlẹ Plateau, Ọgbẹni Yakubu Dati sọ pe iṣẹlẹ naa jẹ ohun to dun ijọba awọn gidigidi pẹlu bi awọn ṣe n gbiyanju lati jẹ ki alaafia jọba nipinlẹ naa.

Bakan naa ni apapọ ẹgbẹ Onigbagbo (CAN), kegbejare pe ki awọn ajọ agbaye da si ọrọ naa, ki wọn si gba awọn ara ipinlẹ naa ati gbogbo agbegbe ti wahala ipaniyan yii ti n ṣẹlẹ silẹ lọwọ awọn Fulani darandaran ti ẹmi eeyan ko jọ loju.

(36)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.