O ma tojọ mẹta kan ta a gbohun Osokomole

Spread the love

Ọrọ oṣelu, nnkan ma ni o. Abi ilu yii naa kọ la wa, ti Gomina Ayọdele Fayoṣe n bu bii ẹkun, to n fọn bii erin, to n tu bii ejo sebe. Ko si ohun ti agbara oṣelu ko le ṣe fun ẹni to ba wa lọwọ rẹ, yoo sọ ọ di nnkan mi-in ti aye ko mọ ni. Amọ nigba ti oju ba mọ, ti oju ba la waa, to di pe agbara naa fẹẹ poora, ẹni to ti n ro pe ko si iru oun laye mọ, tabi pe oun gan-an ni igbakeji Ọlọrun loke-eepẹ, yoo waa gbe jẹẹ, yoo rọ bọjọ bii ẹfọ, nitori yoo ti mọ pe iru Ọlọrun nikan ni ko si, iru eeyan pọ lọ jara. Gbogbo aṣiri Fayoṣe ti wọn tu nigba to n ṣejọba, gbogbo ariwo ti wọn pa le e lori, gbogbo ọrọ owo ti wọn lo ko jẹ, oun ati Musiliu Ọbanikoro, awọn nnkan wọnyi naa to keeyan bẹru ori ara rẹ, nitori oun naa mọ pe ko si bi yoo ti jẹ ti oun ko ni i ba wọn de ile awọn EFCC, ohun ti wọn ba si ṣe fun un lọhun-un, oun paapaa ko ni i le fẹnu ara rẹ sọ, nitori o pẹ ti wọn ti n wa a. Bo ba tiẹ waa jẹ pe igbakeji rẹ ja ajaye bo ti fẹ, se iba tilẹ daa diẹ, nitori gbogbo ohun to ba bo mọlẹ, ko si ẹni ti iba tu u. Ṣugbọn o daju pe ẹni to n bọ nile ijọba yii, iṣẹ akọkọ ti yoo ṣe ni lati tu gbogbo ohun ti Fayoṣe bo mọlẹ, bẹẹ ni ki i ṣe pe iyẹn naa fẹran awọn ara Ekiti, ko kan le fi Fayoṣe ṣẹsin ni. Ohun to dara ju ni pe bi eeyan ba wa laye, ko ṣe daadaa, ko si ri i pe daadaa oun pọ ju aburu yoowu ti oun ba ṣe lọ. Bẹẹ ni bi eeyan ba wa ni ipo kan, ko mọ lọkan ara rẹ pe fun igba diẹ ni, ipo naa yoo bọ lọwọ oun. Ọpọ awọn ti Fayoṣe ti bu, to ti tẹ mọlẹ, to ti ṣe garagara niwaju ẹ, awọn naa ni yoo dide gba a nigba to ba ko si panpẹ awọn EFCC, nitori oun funra ẹ naa ti dana kinni naa silẹ lọjọ to ti pẹ, bi wọn ko ṣe ni i fi ina naa sun un ni ko tete maa wa kiri. Aye oloṣelu ki i ṣe aye kan to yẹ ko wuuyan lori, paapaa awọn oloṣelu Naijiria, iyẹn naa lawọn naa si ṣe maa n fẹẹ ku sile ijọba. Abi nigba ti ibẹrẹ ba dara, to dun bii oyin, ti igbẹyin waa koro bii nnkan mi-in yii nkọ. Ẹ sọ fun Fayoṣe ko sọrọ jare, ko si ohun to n bọ loke ti ilẹ ko gba, Osokomọlẹ o gbọdọ bọkunrin jẹ.

(67)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.