O ma ṣe o! Awọn adigunjale yinbọn pa ọga awọn oniroyin

Spread the love

Inu ọfọ lẹgbẹ awọn oniroyin lorileede yii (NUJ), wa bayii pẹlu ọkan ninu wọn, Samuel Nweke, ti iku oro pa lasiko ti awọn adigunjale da awọn oloye ẹgbẹ NUJ ipinlẹ Ebonyi lọna lọjọ Ẹti, (Furaidee), to kọja.
Ni nnkan bii aago mọkanla alẹ ọjọ yii lawọn adigunjale da ẹgbẹ oniroyin ipinlẹ Ebonyi lọna nigba ti wọn n pada si Abakaliki lẹyin idibo apapọ ẹgbẹ NUJ nilẹ yii to waye niluu Abẹokuta laarin Ọjọruu, Wẹsidee, si ọjọ Ẹti, Furaidee, ọdun yii.
Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, ọkọ bọọsi to jẹ ti ẹgbẹ NUJ ipinlẹ naa lawọn oniroyin yii gbe lọ si irinajo ọhun. Lẹyin ti awọn ẹrujẹjẹ igaara ọlọṣa yii ti fipa da ọkọ naa duro lagbegbe Nkalagu to wa nijọba ibilẹ Ishielu, lọna ilu Enugu si Abakaliki, ni wọn paṣẹ fun awọn oniroyin lati dọbalẹ gbalaja si oju titi, ki wọn si doju bolẹ.
Ori idojubolẹ ni wọn wa ti ọkọ mi-in to n bọ ti ba are buruku gba aarin wọn kọja, to mu Nweke gun mọlẹ, to si jẹ Ọlọrun nipe loju ẹsẹ.
Oṣiṣẹ ileeṣẹ Ebonyi State Broadcasting Corporation, iyẹn ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ ipinlẹ Ebonyi ni Nweke, o si jẹ igbakeji alaga ẹgbẹ awọn oniroyin ipinlẹ naa titi tọlọjọ fi de.
Ṣaaju lawọn adigunjale to da wọn lọna yii ti ṣe diẹ leṣe ninu awọn ẹgbẹ oniroyin to lọọ ṣoju ipinlẹ Ebonyi ninu idibo apapọ ẹgbẹ NUJ ti i ṣe ẹlẹẹkẹfa iru ẹ yii. Awakọ wọn, Peter Okutu to jẹ aṣojukọroyin iweeroyin Vanguard paapaa wa ninu awọn to fara kaasa gidigidi.
Ileewosan ijọba apapọ to wa niluu Abakaliki ni wọn gbe awọn to farapa lọ fun itọju. Ni yara ti wọn n ṣe oku lọjọ si nileewosan ọhun naa ni wọn gbe oku Nweke pamọ si.
ALAROYE gbọ pe baba Nweke ṣi wa laye, bẹẹ lo fi iyawo ati ọmọ mẹta saye lọ.
Apapọ ẹgbẹ oniroyin nilẹ yii ti ranṣẹ ibanikẹdun si ẹbi Nweke. Bẹẹ lẹgbẹ NUJ ni Ẹkun C, ni iha Ila-Oorun Ariwa orileede yii ti kede odidi ọsẹ kan lati fi ṣedaro ọkan lara wọn to jade laye ọhun.
Ninu atẹjade ẹgbẹ NUJ, eyi ti akọwe agba ẹgbẹ naa, Shuaibu Usman Leman, fọwọ si lẹgbẹ awọn oniroyin ti ba ẹbi oloogbe kẹdun, ti wọn si rawọ ẹbẹ si awọn agbofinro lati ṣawari awọn adigunjale to ṣokunfa iku ọmọ ẹgbẹ wọn naa.

(18)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.