O ma ṣe o! Ọmọ ọdun meje ko si kanga l’Akowọnjọ, o ti mumi ku ki wọn too ri i yọ

Spread the love

Alaga ileeṣẹ to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri niluu Eko, Ọgbẹni Adeṣina Tiamiyu ti rọ awọn obi lati maa mojuto awọn ọmọ wọn, ki wọn si maa kiyesi awọn ibi ti wọn ba ti n ṣere lati le tete yọ wọn kuro ninu ewu to ba fẹẹ tibẹ yọ. Ikilọ yii waye pẹlu bi ọdọmọkunirn kan ti ko ti i ju ọdun meje lọ, ti ko si tun da pe daadaa, Godwin Samuel, ṣe ko sinu kanga nibi to ti n ṣere ni Satide ọsẹ to kọja laduugbo Ọrẹpeju Close, Akowonjọ niluu Eko.

ALAROYE gbọ pe lọsan-an ọjọ naa ni ọmọkunrin yii jade nile, to si lọ si itosi ile wọn, iyẹn Ojule kẹfa, Ọrẹpeju Close, nitosi Ọlashẹinde, ti ko fi bẹẹ jinna sile wọn ni Akowọnjọ yii kan naa lati lọọ ba awọn ẹlẹgbẹ rẹ ṣere gẹgẹ bo ṣe maa n ṣe. Nibi to ti n ṣere naa lo ti gbẹsẹ le kanga kan ti wọn ti lo pati ti wọn fi apo simẹnti de lori, lojiji lo ja sinu kanga naa. Ṣugbọn awọn ti wọn jọ n ṣere ko tete mọ, ki awọn araadugbo si too mọ ohun to n ṣẹlẹ, Godwin ti mumi yo ninu kanga naa, o si ti ku ki wọn too gbe e de ileewosan lẹyin ti wọn yọ ọ jade.

Ohun to mu ki ọrọ naa buru ni pe ọmọkunrin yii ko da pe, o ni ipenija ara, abirun ni. Bẹẹ lawọn obi ati ẹgbọn rẹ ko si nile lọjọ yii to fi jade lọ lati ṣere. Gẹgẹ bi ọkọ iya ọmọ naa, Ọgbẹni Isaac Okon, ṣe sọ, o ni oun ko si nile ni Satide ọsẹ to kọja ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ, o ni ṣọọṣi loun wa, bẹẹ ni mama rẹ naa ko si nile, oun lọ sọja lati lọọ ra nnkan ọbẹ ti wọn fẹẹ fi jẹun.

Baba yii ni ṣọọṣi loun wa ti awọn kan fi waa sọ foun pe ọmọ oun ti ko sinu kanga. Nigba toun si fi maa debẹ, awọn eeyan ti pe sibẹ pitimu, bẹẹ ni ileeṣẹ to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri naa ti wa nibẹ. Awọn ni wọn pada yọ ọmọ yii jade, bi wọn si ti yọ ọ jade naa lawọn ti sare gbe e lọ si ọsibitu lati du ẹmi rẹ, ṣugbọn o ṣe ni laaanu pe Godwin ti ku.

Gbogbo awọn to wa nibi iṣẹlẹ naa, to fi mọ awọn mọlẹbi ọmọ to ku yii, ni wọn bu ẹnu atẹ lu lanlọọdu to ni ile ti iṣẹlẹ ọhun ti ṣẹlẹ, wọn ni iwa aibikita ẹni to nile ọhun lo ṣeku airotẹlẹ pa ọmọ ọdun meje ọhun. Idi ni pe wọn lo pẹ ti kanga naa ti wa bẹẹ to jẹ pe wọn ko mọ nnkan kan le e lori, bo tilẹ jẹ pe wọn ko lo o mọ, sibẹ, omi wa ninu rẹ. Dipo ki lanlọọdu ile ọhun si di kanga ọhun pa tabi ki wọn mọ nnkan le e lori ti wọn yoo fi le maa ti i, niṣe ni wọn lo da apo simẹnti bo o, eyi to le fi ṣoro fun ẹnikẹni lati mọ pe ohun to lewu bẹẹ ni wọn da nnkan bo.

Eyi naa lo ṣẹlẹ si Godwin ti oun ko fi mọ pe nnkan to le ṣakoba fun oun ni. Oun kan ri i ti wọn fi apo simẹnti bo ibẹ, ko si bikita to fi tẹ ori rẹ mọlẹ pe ki oun kan gbabẹ kọja, eyi naa lo si fa a to fi ko si kanga naa, to si mu omi yo, leyii to pada ṣeku pa a.

Awọn eeyan ni niṣe lo yẹ ki wọn fọwọ ofin mu ẹni to nile naa, ki wọn si ba a ṣẹjọ nitori iwa aibikita rẹ lo ṣeku pa ọmọ ọlọmọ. Ṣugbọn nitori wahala, oju ẹsẹ ni gbogbo awọn to wa ninu ile naa ti sa jade.

Ileeṣẹ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri, LASEMA ko fakoko ṣofo rara ti wọn fi ti ile naa pa. Ọga ileeṣẹ ọhun, Ọgbẹni  Adeṣina Tiamiyu, ṣalaye pe idi ti awọn fi ti ile yii pa ko ju pe kanga to wa nibẹ ti wa ni ita gbangba ju, pẹlu bi wọn ko si ṣe fi nnkan to daa bo o, o tun le ṣakoba fun ẹlomin-in to ba tun gba ori ibẹ kọja lai ni ifura.

O rọ awọn eeyan lati ri i pe wọn fi n to ijọba leti ti wọn ba ri awọn ile akọku tabi ile alapa, eyi to le ṣakoba fun awọn olugbe adugbo ibẹ. Bakan naa lo rọ awọn obi lati ri i pe wọn mojuto awọn ọmọ wọn, ki wọn maa kiyesi ibi ti wọn n lọ ati ibi ti wọn ti n ṣere lati dena wahala to ṣee ṣe ko ṣẹlẹ si wọn ti wọn ba rin si ibi ti ko yẹ.

 

 

(31)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.