O ma ṣe o, inu odo ti Pẹlumi ti n luwẹẹ lo ku si l’Akurẹ

Spread the love

Ṣe nibanujẹ dori awọn eeyan agbegbe Adebọwale, niluu Akurẹ, kodo lori isẹlẹ iku ọmọbinrin kan, Friday Pẹlumi, ti wọn lo ku sinu odo nibi to ti n luwẹẹ.

 

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, ileeṣẹ kan ti wọn n pe ni Africola, ni wọn lo gbẹ adagun odo ọhun sinu ọgba wọn ko too di pe wọn kẹru wọn kuro lagbegbe naa lọ si ibomi-in.

 

Lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja lọmọbinrin ti wọn lo ṣẹṣẹ pe ẹni ọdun mejidinlogun ọhun mu aburo rẹ kan ti wọn n pe ni Ọdun atawọn ọrẹ rẹ mẹta mi-in lẹyin lati lọọ luwẹẹ ninu adagun odo ọhun.

Bi wọn ti de eti odo naa ni wọn lo ti bọ ẹwu to wọ, to si ku awọtẹlẹ lọrun rẹ. Ọmọbinrin ọhun ni wọn ni ko duro de awọn ọrẹ rẹ to fi bẹ sinu odo lati wẹ. Bo ti fẹẹ bẹ sinu omi ni wọn lo tun fa aburo rẹ lọwọ pe ki wọn le jọ luwẹẹ papọ.

 

Loju ẹsẹ ti Ọdun to jẹ aburo Pẹlumi ti bẹ somi pẹlu ẹgbọn rẹ lọrọ ti yiwọ mọ awọn mejeeji lọwọ. Alaroye gbọ pe awọn mẹta ti wọn jọ lọ seti odo naa ni wọn sare fa Ọdun jade ko too di pe o mu omi yo, ṣugbọn gbogbo igbiyanju wọn lati ri ẹgbọn rẹ fa jade lo ja si pabo. Pẹlumi ti ku sinu odo naa kawọn eeyan too ri i fa jade.

 

Ọkan ninu awọn araadugbo ọhun fidi ẹ mulẹ fun wa pe adagun odo ọhun ti dẹru jẹjẹ sawọn eeyan agbegbe naa lọrun, o ni ki i ṣe igba akọkọ niyi tawọn eeyan yoo ku sinu rẹ, ọdọọdun lo maa n ṣẹlẹ bẹẹ.

 

Ẹbẹ kan ṣoṣo tawọn araadugbo naa n bẹ ijọba ni pe ki wọn gbẹsẹ le ilẹ ileeṣẹ naa pẹlu adagun odo yii niwọn igba ti ko si aridaju pe awọn Africola to ni ileeṣẹ naa ṣetan lati pada sibẹ.

 

 

 

(1)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.