O ma ṣe o, ina oṣelu n jo Fayoṣe lọwọlọwọ

Spread the love

Ko si ẹni to mọ eewọ ija bii ọlẹ, abi nigba ti wọn ri ọlẹ, ti wọn bu u pe yoo ba iya rẹ, yoo ba baba rẹ, to si da wọn lohun pe, ‘Rara, ko ni i ba iya ẹni kankan, ko si ni i ba baba ẹni kankan ninu wa!’ Ṣebi oogun ija ni ọlẹ ṣe yii, abi ta ni yoo tun ba a ja nigba to ti ni ko ni i ba iya ẹni kankan. Ohun ti Ayọdele Fayoṣe ro papọ ree to fi sinmi agbaja. Oloṣelu, eeyan lasan ti pọ ju ninu wọn, ẹni to ba kan n tẹle wọn yoo kan ṣe ara rẹ leṣe lasan ni. Nigba ti ọti oṣelu n pa Fayoṣe, ohun to n sọ kaakiri ni pe Ọlọrun ti pe oun, Ọlọrun ti paṣẹ foun, Ọlọrun ti fi han oun pe oun loun yoo gba ijọba lọwọ Buhari, pe ti Buhari ati Ọṣinbajo ba kuro nipo naa ni ọdun 2019, oun Ayọdele Fayoṣe ni yoo bọ sibẹ, oju gbogbo aye ni yoo si ṣe. Awọn were, awọn ẹlẹtan, awọn omugọ eeyan ti jade, wọn ti bẹrẹ si i pe e ni Purẹsidẹnti, wọn n pariwo le e lori bi wọn ba ti ri i pe Abuja sireeti, nibi ti laakaye awọn eeyan naa mọ niyẹn. Ṣugbọn awọn eeyan naa ko lẹbi bii ẹni ti wọn n tan, to tun n tan ara rẹ, ṣe bi eeyan ba gbe jẹẹ, iba lawọn eeyan yoo ti i gbọn-ọn gbọn-ọn mọ. Fayoṣe waa jade bayii pe oun ko du ipo mọ, oun ko si fẹẹ ṣe aarẹ, nitori oun fẹẹ dojukọ ija ibo gomina Ekiti ti oun n ja lọwọ. Kin ni tiẹ? Oun lo dibo ni abi oun ni gomina ti wọn fa kalẹ. Ohun to ṣẹlẹ ko ju pe ilẹ ti mọ oloro si gbangba, bi eeyan ba si kan Fayoṣe nibi to ba jokoo si bayii, to ba fọwọ kan aya rẹ, yoo ri i ti yoo maa lu kii kii kii, nitori ko mọ ohun to ku ti yoo ba oun lẹyin ọjọ to ba gbejọba silẹ. Ko si yẹ ko ri bẹẹ o. Oloṣelu to ba fi ododo ati ifẹ ṣiṣẹ fawọn eeyan rẹ, ti ko ko owo wọn jẹ, ti ko si ṣe garagara kọja aniyan, bo ba n lọ bayii, tidunnu tidunnu ni yoo fi maa lọ. Ṣugbọn ti awọn oloṣelu Naijiria ki i ri bẹẹ, nigba to ṣe pe wọn ko jẹ kinni kan ki wọn too lọọ ṣe oṣelu, bi wọn ba si depo naa tan, wọn yoo sọ ara wọn di Ọlọrun ni, nigba ti wọn ba fẹẹ kuro nipo ni wọn yoo maa ṣe bii adiẹ ti ojo ti pa, nitori awọn naa yoo ranti aburu wọn ti wọn ti ṣe, ibẹru yoo si mu wọn de gongo. Ala ti Fayoṣe la ko ṣiṣẹ mọ, ina oṣelu buruku ti jo o

(11)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.