O ma ṣe o: Awọn eeyan ṣedaro Ọsatoyinbo, ọmọọṣẹ Fayẹmi tẹlẹ to ku

Spread the love

Inu ibanujẹ lawọn mọlẹbi ati ọrẹ Oludamọran Pataki fun Gomina Kayọde Fayẹmi tẹlẹ, Tọpẹ Ọṣatoyinbo, wa di asiko yii pẹlu bi iku ṣe pa oju ọkunrin naa de lọjọ Abamẹta, Satide, to kọja niluu Ado-Ekiti.

Ohun to mu ọrọ yii ka awọn eeyan lara ni bi ẹni ọdun mẹrindinlọgọta naa ṣe ku lẹyin oṣu mẹfa geerege tiyawo rẹ faye silẹ.

Ọṣatoyinbo lo jẹ Oludamọran Pataki lori eto ilanilọyẹ fun Fayẹmi lasiko iṣejọba akọkọ lọdun 2010 si 2014, lẹyin naa lo si pada si ileeṣẹ ijọba apapọ to n ṣeto itaniji, National Orientation Agency (NOA), nibi to ti di ọkan lara awọn ọga ibẹ kọlọjọ too de.

Gẹgẹ bi ALAROYE ṣe gbọ, ko si nnkan to ṣe oloogbe lati aarọ ọjọ iṣẹlẹ ọhun, ṣugbọn ni nnkan bii aago mẹsan-an alẹ ni wọn sare gbe e lọ si ọsibitu Ekiti State University Teaching Hospital (EKSUTH), nibi to pada ku si.

 

Ọgbẹni Dayọ Famosaya to jẹ adari NOA l’Ekiti ṣalaye pe oloogbe wa sibi iṣẹ lọjọ naa, o si pari iṣẹ ni bii aago mẹrin irọle. O ni awọn tun sọrọ lalẹ, iyẹn lẹyin to lọ sibi igbeyawo ọmọ Ọba Adeyẹmọ Adejugbe Aladesanmi Kẹta, Ewi tilu Ado.

 

O ni awọn sọ oriṣiiriṣii ọrọ lalẹ ọjọ naa lori foonu, afi boun ṣe gbọ pe o ku lẹyin aisan ranpẹ. O fi ẹdun ọkan han lori iṣẹlẹ naa, bẹẹ lo juwe oloogbe bii ẹni to ṣiṣẹ tọkan-tọkan de ọjọ iku.

Ninu ọrọ ikẹdun rẹ, Gomina Kayọde ni iṣẹlẹ ibanujẹ gbaa niku oloogbe, nitori ko si aarẹ kankan to ṣe e tẹlẹ.

O fi kun un pe ibanujẹ nla ni iku rẹ jẹ fun oun, gbogbo ẹgbẹ All Progressives Congress (APC), atawọn eeyan oloogbe lapapọ.

O ṣapejuwe Ọṣatoyinbo bii ẹni to huwa olufọkansin ati ẹniire laarin ọgbọn ọdun o le ti wọn fi mọra.

O waa gbadura itunu fun ọmọ ati mọlẹbi rẹ.

Lasiko ta a pari akojọpọ iroyin yii, mọṣuari EKSUTH ni oku oloogbe naa ṣi wa.

 

 

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.