O ma ṣe o Awọn agbebọn pa ‘Sharpman’, ogbologboo ọmọ ẹgbẹ okunkun

Spread the love

Kayeefi nla ni iku ọdọmọkunrin kan, ẹni ọdun mọkanlelogoji kan, Ayọdele Ọlajide, ẹni ti inagijẹ rẹ n jẹ Sharpman, ṣi n jẹ fun awọn eeyan ilu Ondo. Ọkan gboogi ninu awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun K.K ni Ayọdele, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ to kọja, ni wọn yinbọn pa a.

Ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ meji sẹyin, lo ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ yooku. Lojiji ni iroyin iku rẹ lu igboro pa. Iroyin ta a gbọ fi ye wa pe ile ọti kan ti wọn n pe ni Erelu Gbonjubọla, to wa laduugbo Okeṣẹgun, niluu Ondo, ni wọn yinbọn pa a si.

ALAROYE ṣabẹwo si adugbo naa, niṣe ni gbogbo rẹ si palọlọ, koda, awọn ọlọpaa duro wamuwamu si agbegbe yii.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣalaye fun ALAROYE pe ni nnkan bii aago mẹjọ kọja iṣẹju mẹẹẹdogun alẹ ọjọ naa ni iro ibọn ṣadeede dun nile ọti kan to wa laduugbo naa. Lẹsẹkẹsẹ ni awọn eeyan bẹrẹ si i sa asala fun ẹmi wọn, ṣugbọn nigba ti awọn agbebọn naa lọ tan ni wọn ri oku Sharpman nilẹ. Obinrin to nile ọti naa, Erelu Gbọnjubọla, ṣalaye fun wa pe onibaara oun ni Sharpman, ati pe ọdọ oun lo ti maa n waa mu ọti. O ni lasiko ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ, Sharpman n fi ọti rẹ ongbẹ lọwọ ni, to si n wo tẹlifisan. O ni lojiji ni awọn ọkunrin meji kan gun ọkada de ile ọti naa, ti wọn si fa ibọn yọ. Ibọn naa ni wọn yin lu Sharpman, lojiji lo si ṣubu lulẹ. Leyin to ṣubu ni awọn ọkunrin meji yii tun gbe e gun ori ọkada, ti wọn si gba ọna isalẹ adugbo yii lọ.

Ọkan ninu awọn ọdọ adugbo naa to ni ka forukọ bo oun laṣiiri ṣalaye fun akọroyin wa pe ko too di ọjọ ti wọn yinbọn pa a yii ni awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti n yinbọn soke kikankikan laduugbo naa to ba di alẹ. O ni idi niyẹn ti awọn araadugbo yii fi maa n tete wọnu ile lọ. Ọkunrin naa fidi rẹ mulẹ pe ọkan gboogi ninu ọmọ ẹgbẹ okunkun ni Sharpman i ṣe, gbogbo adugbo lo si maa n bẹru rẹ. O ni inu ọgba ileewe alakọọbẹrẹ kan to wa laduugbo naa ni oun pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ ti maa n ṣẹpade wọn.

Awọn ọlọpaa lo pada waa gbe oku Sharpman, ti wọn si mu obinrin to nile ọti naa lọ si teṣan wọn.

Ọga ọlọpaa kan to wa laduugbo Yaba, to ni ka forukọ bo oun laṣiiri sọ fun wa pe awọn ti fi ẹda iwe iṣẹlẹ naa ṣọwọ si olu-ileeṣẹ ọlọpaa to wa niluu Akurẹ, awọn si ti gbe oku ọmọkunrin naa pamọ si mọṣuari ijọba to wa niluu Ondo. O fi kun un pe ọdọ ọlọpaa ni obinrin to ni ile ọti naa wa, nibi to ti n ran awọn lọwọ lori iwadii awọn.

 

 

(12)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.