O ma ṣe o: Awọn agbebọn pa kansẹlọ l’Ado-Ekiti

Spread the love

Inu ọfọ nla lawọn ẹbi, ara ati ọrẹ kansẹlọ Wọọdu kẹsan-an ijọba ibilẹ Ado, Ọnarebu Adedeji Akeredolu, wa di akoko yii latari iku to pa oju ọdọmọde oloṣelu naa de lalẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja, lẹyin tawọn agbebọn kan kọlu u.

Gẹgẹ bi ALAROYE ṣe gbọ, Adedeji to jade laye lẹni ọdun mẹtadinlogoji loun ati iyawo rẹ ti wa nitosi ile ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ ọjọ naa, afi bi awọn agbebọn kan ti wọn gbe mọtọ Camry ṣe deede yọ si wọn, ti wọn si yinbọn lu u lẹẹmeji.

Bi wọn ṣe ri i pe ibọn ti ba oloogbe to tun jẹ alaga igbimọ to n ṣeto ayika nijọba ibilẹ Ado naa ni wọn sa lọ, iyawo rẹ lo si pariwo tawọn eeyan fi jade lati du ẹmi rẹ. A gbọ pe wọn kọkọ gbe e lọ si ileewosan aladaani kan lagbegbe naa, ṣugbọn awọn yẹn ni ki wọn maa gbe e lọ sileeweosan Ekiti State University Teaching Hospital (EKSUTH), lasiko naa lo si dagbere faye.

Ẹnikan to ba akọroyin wa sọrọ pẹlu ẹdun ọkan laduugbo tiṣẹlẹ ọhun ti waye sọ pe oun wa ni ṣọọbu lasiko naa loun gbọ ariwo iyawo rẹ, ẹni to jẹ onibaara oun, awọn eeyan si tete lọọ ran an lọwọ, ṣugbọn iṣẹlẹ naa pada ja si aburu.

O ni eeyan jẹẹjẹ ni Adedeji, oun atiyawo rẹ maa n ba oun ra nnkan daadaa, ko si sẹni to mọ idi ti ẹnikẹni fi le lepa ẹmi rẹ.

Bakan naa ni Ọnarebu Deji Ogunṣakin to jẹ igbakeji Ọjọgbọn Kọlapọ Ẹlẹka to dupo gomina lẹgbẹ People’s Democratic Party (PDP), lọdun to kọja sọ pe ibanujẹ gidi niṣẹlẹ naa jẹ foun nitori eeyan daadaa ni oloogbe yii.

Ogunṣakin ti Adedeji jẹ amugbalẹgbẹẹ rẹ juwe oloogbe naa bii olufọkansin to tun jafafa, bẹẹ lo ṣẹṣẹ ṣi ile aṣọ riran igbalode kan toun atiyawo rẹ fẹẹ maa ṣakoso ni. O waa ni iru iku bayii ti fẹẹ maa wọpọ l’Ekiti, kijọba tete dide lati daabo bo awọn araalu.

ALAROYE de ile ti Adedeji gbe nigba ayẹ rẹ, bẹẹ la de ọdọ baba rẹ, Alagba Jacob Akeredolu. Baba ẹni ọdun mejilelaaadọrin ọhun sọ pe awọn to ṣiṣẹ ibi naa ti da oun loro, ati pe igi lẹyin ọgba oun ni wọn ran sọrun laipe ọjọ.

Gẹgẹ bi baba to ti fẹyinti lati ọdun 2007 naa ṣe ṣalaye, ‘’ Nnkan ti mo kan gbọ ni pe awọn kan yinbọn lu u, nigba to si dagbere faye lawọn ọlọpaa kan lati teṣan Oke Ila gbe e wa sile. Mi o lowo ti mo le fi gbe e lọ si mọṣuari la ṣe fi silẹ nile, aarọ yii (Satide), la si sin in. Ṣe niyawo ẹ daku nigba ti wọn n sin in, a si ni lati sare gbe e lọ sileewosan.

‘’Adedeji ni ọmọ mi keji, oun si ni igi lẹyin ọgba mi. Tẹ ẹ ba beere lọwọ awọn to mọ ọn, wọn maa sọ fun yin pe ki i ṣe ẹni to n fa wahala tabi to fẹran jagidijagan. Idi ti wọn fi da mi loro yii ko ye mi, ṣugbọn mo ti fija f’Ọlọrun ja.

‘’Iranlọwọ ijọba ni mo nilo bayii nitori mi o lẹnikankan, afi Ọlọrun. Aburo ẹ ka iwe de ipele agba (Masters), ṣugbọn ko riṣẹ. Ti ijọba ba le ran mi lọwọ ki wọn fun un niṣẹ ki nnkan tun le rọrun fun wa, ma a dupẹ o.’’

Iwadii ALAROYE fi han pe Adedeji ṣi ni iya laye, bẹẹ loun atiyawo rẹ ko ti i bimọ lasiko ti ọlọjọ de.

Akọroyin wa pe DSP Caleb Ikechukwu to jẹ alukoro ọlọpaa Ekiti, ṣugbọn o ni oun ko ti i gba ẹkunrẹrẹ alaye lori iṣẹlẹ naa. O ṣeleri lati pe wa pada, ṣugbọn ko ṣe bẹẹ ta a fi pari akojọpọ iroyin yii.

wa, Henry Onyekuru, n ṣe bẹbẹ fun ti n wa gbogbo ọna lati ra ọmọkunrin naa patapata lọwọ Everton ilẹ England.

Lopin ọsẹ to kọja niroyin jade pe Galatasaray ti n ṣeto lati ta

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.