O ku ọjọ mẹta ki Waidi joye Akinrogun Agodo ni wọn ṣa a pa

Spread the love

Waidi atawọn eeyan ẹ fẹẹ lọọ roko to wa nibẹ to fi di pe awọn kan ya bo wọn pẹlu ada, ibọn, igo ati oogun ibilẹ oriṣiiriṣii.

O darukọ ẹni to ṣaaju ikọlu naa lọjọ yii, Gbeminiyi Ṣotade. Awọn gende yooku ta a gbọ pe wọn ṣigun wọ Agodo, ti wọn ṣa Waidi pa ni Ayọ Fajọbi, Emmanuel Fajobi, Ṣẹgun Daisi, Jomoye Adeyẹmọ, Daisi Ajayi, Lateef Aileru, Adewuyi Adeọṣun, Ayolo Yobo ati James.

Awọn mi-in ti wọn ni wọn lọwọ ninu ẹsun naa ni Ramọni Saidi, Sẹmiu Sanni, Ṣẹgun Akinjiyan, Ṣeun Olugbenga ati Nurudeen Balogun.

Njẹ wọn fiṣẹlẹ yii to ọlọpaa leti nigba to n lọ lọwọ, olori ẹbi Obidairo sọ pe teṣan ọlọpaa Ibogun to sun mọ awọn ju lawọn kọkọ pe, ṣugbọn wọn ko wa. Awọn tun pe wọn ni Sanngo, awọn iyẹn wa, ṣugbọn Waidi ti ku nigba ti wọn yoo fii de, nitori awọn ti wọn ṣa a ladaa naa ri i daju pe o ku pata ki wọn too sa lọ ni.

O ni diẹ ninu awọn afurasi tawọn ọlọpaa ti mọle ko pẹ nibẹ ti wọn fi n yan fanda nigboro pada, bẹẹ, oku Waidi ṣi wa ni mọṣuari, awọn ko ti i le sin in.

Iyawo kan atọmọ mẹfa lo ni oloogbe naa da silẹ lojiji, ẹni ọdun marundinlaaadọta ( 45)lo pe e.

Ni gbogbo asiko ta a n kọ iroyin yii, Abule Agodo ko fararọ, ibẹ kan gbinringbinrin ni. Koda, baalẹ to fẹẹ jọba paapaa ko le gbele mọ, ko si duro labule naa, wọn ni awọn kan n dọdẹ ẹmi tiẹ naa kiri lo ṣe dọgbọn yẹra.

A gbiyanju lati ri ninu awọn eeyan ti wọn fẹsun kan yii, ka tiẹ bi wọn bo ṣe jẹ. Ṣugbọn ko sẹni kan to duro nitosi ninu awọn naa bi a ṣe gbọ, wọn ni bawọn ọlọpaa ṣe yọnda wọn nipinlẹ Ogun ni wọn ti wabi kan gba lọ.

Olori ẹbi sọ fun wa pe ki Waidi to n ṣiṣẹ wẹda ma ṣe bẹẹ ku gbe, kiya ma jẹ iyawo atawọn ọmọ ẹ mẹfa lo fa a tawọn fi bẹ awọn lọọya lọwẹ, ti wọn ṣeto iwe kikọ si ọga ọlọpaa pata nilẹ yii, IGP Mohammed Adamu, to fi di pe keesi naa ti wa l’Ekoo lọdọ awọn SARS bayii.

Lori bi ẹjọ ipinlẹ Ogun ṣe tun d’Ekoo, Ọgbẹni Obidairo to jẹ ọmọ baba kan naa pẹlu oloogbe ṣalaye pe nigba to jẹ awọn ti ko yẹ kawọn ọlọpaa mu lori iṣẹlẹ naa ni wọn mu nipinlẹ Ogun, to jẹ awọn ti wọn fara ṣeṣe latari ṣiṣa ti wọn ṣa wọn ni wọn tun ti mọle, ti wọn si pẹ ni teṣan ki wọn too fi wọn silẹ, iyẹn lawọn ṣe kọwe sọgaa agba, lati ibẹ lo si ti de ilu Eko.

ALAROYE  pe Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, lati fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, ohun to sọ fun wa ni pe oun ko gbọ nipa iṣẹlẹ bẹẹ, oun ko mọ bi ẹjọ yoo ṣe ṣẹlẹ nipinlẹ Ogun, ti wọn yoo tun maa gbọ ọ l’Ekoo.

Ṣugbọn awọn ẹbi Obidairo ko yee sọ pe wọn pa eeyan awọn nitori ọrọ ọba jijẹ, wọn si lawọn ko fẹ nnkan meji ju idajọ ododo lọ.

 

(11)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.