O kare jare, Yinka Ayefẹlẹ

Spread the love

Loootọ kin ni naa yoo dun-un-yan, yoo si baayan lọkan jẹ. Paapaa nibi ti nnkan le de yii, ki eeyan ti kọle rẹ sibi kan, ki awọn alagbara aye kan si de lojiji ki wọn wole ẹni. Ṣugbọn Ayefẹlẹ ṣe bii ọkunrin ti i ṣe, o ṣe bii ẹni to le ja fun ilu ẹ ti i ṣe, ko si bikita ohun ti awọn abatẹnijẹ aye le ṣe. Ko sẹni ti ko mọ pe ọrọ oṣelu lo jẹ ki wọn wo ile Ayefẹlẹ yii. Ki i kuku i ṣe pe Ayefẹlẹ kọrin bu Ajimọbi, ṣugbọn nitori pe ileeṣẹ redio to da silẹ sọrọ oṣelu, ọrọ naa ko si tẹ Ajimọbi lọrun, wọn lo sọ pe wọn bu oun, nitori rẹ ni wọn ṣe wo ile rẹ. Ki lo de ti wọn ko le bu Ajimọbi, o ni kin ni tiẹ! Ki lo n ta to n jẹ saarata! Iṣẹ ki lo n ṣe tẹnikan ko ṣe ri, awọn wo lo n tan an pe ko ṣẹlẹ ri! Kin ni ko ṣẹlẹ ri yatọ sawọn aburu to n ṣe! Ẹni to ba ti wa nidii oṣelu, to fi oṣelu de ipo kan, ko si ohun to le ṣe, bi awọn kan ti n bu u, bẹẹ lawọn kan yoo maa yin in, bi aye ti ri niyẹn. Awọn to n bu u loni-in ko sọ pe wọn ko le pada yin in lọla, awọn to si n yin in loni-in ko sọ pe wọn ko le pada bu u lọla. Bi aye oloṣelu ti ri niyẹn. Iyẹn lo ṣe jẹ pe oloṣelu ti ko ba ni arojinlẹ tabi to ba jẹ ika buruku, ni yoo ba nnkan oni-nnkan jẹ nitori pe wọn sọrọ si i. Njẹ Ajimọbi mọ iye epe ti awọn ti wọn ji wa si ibi ti wọn ti n wo ile Ayefẹlẹ yii gbe oun ṣẹ lọjọ naa, ti wọn n fi oun ati idile rẹ ṣepe. Ohun ti Ayefẹlẹ fi fi ajulọ han an niyẹn. Bo ba jẹ ẹlomiiran ni, yoo ti gbọn waa ba a, wọn yoo ti ko ero lẹyin pe ki wọn ba oun bẹ ẹ ko ma binu, yoo si ti sọ redio rẹ di eyi ti yoo maa kọrin oriki rẹ pe oun ni baba gbogbo aye. Ṣugbọn ẹni to ba gba iṣẹ iroyin, to si fẹẹ ṣe e nitori araalu ti mọ pe oun ko ni i ṣe ọrẹ oloṣelu, nigba to jẹ ole ati ọdalẹ ni wọn, bẹẹ lẹnikan ko gbọdọ sọ pe iwa wọn ko dara. Ṣebi Ajimọbi ti lọ sileeṣẹ redio yii ni 2016 to sọ nibẹ pe oun dupẹ pe oun ko wo ile Ayefẹlẹ nigba tawọn kan ni ki oun wo o, eyi si fihan pe wiwo to wo o yii, ọrọ oṣelu ni. Oun Ajimọbi yoo lọ, o si daju pe yoo maa gbọ esi ọrọ rẹ lẹnu Ayefẹlẹ ati redio rẹ lẹyin to ba lọ, yoo maa gbọ orukọ ara rẹ si aburu ni ogun ọdun, ọgbọn ọdun, ati titi ti yoo fi ku laye rẹ ni. Ẹni to ṣe oore fun oṣere ko ṣe e gbe, ẹni to si ṣe aburu fun oṣere naa ko ṣe e gbe, tọhun yoo gbọ orukọ ara rẹ lẹyin ọla. Pẹlẹ o, Ayefẹlẹ, ile ọba to jo, ẹwa ni yoo bu si i!

 

(283)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.