O ṣoju mi koro Kin ni Buhari n ṣe bayii fun?

Spread the love

Bi nnkan ṣe ri bayii fun wa ni Naijiria yii, Ọlọrun nikan lo le to o. Lati igba ti wọn ti yan obinrin kan ti wọn n pe ni Amina Zakari gẹgẹ bii olori awọn ti yoo kabo 2019 yii fun ileeṣẹ INEC to n ṣeto ibo ni ariwo ti gba gbogbo ilu kan. Ko si si ohun to fa ariwo naa ju pe ọmọ ẹgbọn Aarẹ Muhammadu Buhari ni wọn yan sipo naa lọ. Nigba ti eeyan jẹ olori ijọba orilẹ-ede kan, to jẹ ijọba rẹ lo n ṣeto idibo yii, to si wa ninu awọn ti yoo du ipo aarẹ ninu idibo naa, to si jẹ ki wọn yan aburo oun si ipo ẹni ti yoo ka ibo ti wọn ba di. Gbogbo ibo ti wọn ba di, nigba ti wọn ba ko ibo naa jọ tan, ẹni to jẹ olori awọn to n ko o jọ yii ni Amina Zakari, bẹẹ Amina yii, ọmọ aburo Buhari obinrin ni. Ṣe bi wọn ba ṣe iru eleyii fun Buhari, awọn ti wọn n tẹle e le gba ṣaa. Ko jẹ pe nigba ti Goodluck Jonathan fẹẹ ṣeto idibo lọjọsi, ko jẹ aburo rẹ lo mu to fi ṣe olori awọn ti yoo ka ibo naa, njẹ awọn eeyan bii Lai Muhammed ati awọn ti wọn wa ninu APC ko ni i fara ya kọja aniyan, njẹ ọrọ naa ko ni i de ile-ẹjọ bọ. Bẹẹ ni gbogbo ilu yoo duro ti wọn bo ba ṣẹlẹ bẹẹ, nitori kaluku lo mọ pe ohun ti ko daa ko daa. Ṣugbọn Buhari ti gbogbo eeyan ro pe oniwa-mimọ, olododo ti ko le ṣojooro tabi fi igba kan bọ ọkan ninu, oun lo n ṣe bo ti n ṣe yii o, oun lo n fawọn ẹbi rẹ ṣe olori ileeṣẹ ijọba gbogbo, agaga ileeṣẹ ti yoo ṣeto idibo. Ṣe bi wọn ba fun were ni ọkọ, ọdọ ara rẹ kọ ni yoo roko si ni, tabi ọmọ aburo rẹ yoo laju silẹ, yoo si jẹ ki wọn ka ibo ti yoo yọ ẹgbọn iya rẹ loye, ibo ti yoo sọ Buhari di korofo. Ṣe bi Buhari ba di korofo, oun naa ko ni i di korofo ni. Dajudaju, iru ẹni yii ko ni i ṣiṣẹ fun ẹlomiiran ju Buhari lọ. Awọn ti wọn fẹran Buhari, ti wọn si fẹ ti APC yoo maa sọ bayii pe bo ṣe daa niyẹn, inu wọn yoo si dun pe Buhari fẹẹ gba ọna alumọkọrọyi yii wọle, wọn yoo ni ko si ohun to kan awọn, koda, ko jẹ ojooro naa ni wọn ṣe, ko ṣa ti jẹ Buhari lo wọle. Ohun ti ko ye awọn ti wọn ba ronu bayii ni pe ohun ti Buhari ati ijọba to wa bayii n ṣe yii yoo ba orilẹ-ede yii jẹ ni, yoo fọ Naijiria ni, yoo tu wa ka laipe ọjọ, nitori nigba ti ijọba ko ba ti ṣododo pẹlu araalu, ijọba bẹẹ yoo ṣubu ni. Ohun ti Buhari ṣe yii ko dara, ko si si ohun meji to yẹ ki ileeṣẹ INEC ṣe ju ki wọn yọ obinrin yii kuro ni ipo to wa, bo ba si ṣee ṣe, ki wọn yọ ọ kuro nileeṣẹ INEC, ki wọn wa iṣẹ ijọba mi-in fun un ko maa ṣe. Ko si bi ibo ti wọn fẹẹ di yii yoo ṣe dara to, bi obinrin yii ba wa nibẹ, ko sẹni ti yoo ka a si ibo to mọ, tabi ibo ododo, awọn ara ilẹ okeere yoo si maa fi wa rẹrin-in ni, wọn yoo ni ibo buruku ni Buhari ṣeto, eru lo wa ninu gbogbo ohun to ṣe. Idi niyi ti wọn ṣe gbọdọ yọ obinrin yii lẹsẹkẹsẹ, ki gbogbo aye le nigbagbọ ninu eto idibo ti wọn ba ṣe. Ṣugbọn ohun ti ko yeeyan ninu gbogbo ọrọ to wa nilẹ yii ni pe kin ni Buhari paapaa n ṣe bayii fun! Ṣe Buhari lo n ṣe e ni abi awọn mi-in, Ọlọrun nikan lo le gba wa o!

 

(3)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.