O ṣoju mi koro Buhari laye fẹẹ ri, ki i ṣe Tinubu o

Spread the love

Pe Aarẹ Muhammadu Buhari lọ si ipinlẹ Bauchi lati ṣe ipolongo ibo rẹ lọsẹ to kọja, iroyin to tẹ awọn eeyan lọrun ni. Awọn ero jade ni rẹpẹtẹ lati waa pade Aarẹ, wọn si foju ara wọn ri ẹni ti wọn yoo dibo fun, ọrọ to n sọ lẹnu si ye wọn. Lẹyin ti wọn ti gbọ ọrọ ẹnu rẹ, ẹni to ba fẹẹ dibo fun un yoo dibo fun un, ẹni ti ko ba si ni i dibo fun un ko ni i dibo fun un naa ni. Bi wọn ti n ṣeto ijọba tiwa-n-tiwa niyi, ohun ti ofin sọ niyẹn pe ẹni ti yoo ba du ipo kan, afi ko jade sọdọ awọn eeyan, ko bẹ wọn pe ki wọn dibo foun, ko si sọ ohun ti oun yoo ṣe ti wọn ba dibo fun un. Eyi yatọ si ohun ti awọn eeyan ti gbọ tẹlẹ, ṣe ohun ti wọn gbọ ni pe Aarẹ Buhari ko ni i jade, kaka bẹẹ, o ti fa eto ipolongo rẹ le Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu lọwọ, o ni oun ni yoo ba oun mojuto eto ipolongo naa, oun ni yoo maa kaakiri foun nitori oun fẹẹ ṣe iṣẹ ijọba. O ṣee ṣe ko jẹ ariwo tawọn eeyan pa ni Buhari ṣe gbe ọrọ rẹ yii ti si ẹgbẹ kan, ọrọ pe Tinubu ni yoo maa ṣe kampeeni kiri lorukọ oun. Awọn eeyan pariwo, nitori ko si ibi ti wọn ti n ṣe iru eto bẹẹ yẹn ninu ijọba dẹmokiresi. Ẹni ti awọn araalu fẹẹ dibo fun ni wọn fẹẹ ri. Buhari lo n ṣejọba, oun naa lo si sọ pe oun fẹẹ du ipo yii lẹẹkeji, oun naa ni wọn si fẹẹ ri lati ba sọrọ, oun ni wọn fẹẹ gbọ ti ẹnu rẹ, ọrọ to ba sọ fun wọn ni yoo jẹ ki wọn mọ boya wọn yoo dibo fun un tabi wọn ko ni i dibo fun un. Oju awo ni awo fi n gbọbẹ, ileri ti Buhari ba ṣe fawọn eeyan ni wọn yoo gbọ, ti wọn yoo si le beere lọwọ rẹ lọjọ iwaju pe oun lo sọ bayii nibi to ti waa ṣe ipolongo fawọn. Amọ to ba jẹ Aṣiwaju Tinubu lo ran jade, ti iyẹn si sọ oriṣiiriṣii ọrọ, nigba ti ki i ṣe oun lo n ṣejọba tabi oun lo fẹẹ ṣejọba, ko si ẹni ti yoo le pada lọọ bi i leere pe awọn ileri to ṣe ree, awọn ẹjẹ to jẹ ree, lọjọ wo lo fẹẹ mu wọn ṣẹ. Idahun ti yoo fun wọn naa ni pe ṣe oun loun n ṣejọba ni. Loootọ awọn kan sọ pe ara Buhari ko ya daadaa to lati maa ṣe ipolongo kaakiri ni, bo ba jẹ bẹẹ ni, ki i ṣe baifọọsi lati ṣe aarẹ Naijiria, Ọlọrun si ba a ṣe e, o ti ṣejọba ilẹ yii lẹẹmeji, bi ara rẹ ko ba ya, tabi ti agbara rẹ ko ba gbe iṣẹ ijọba lasiko yii, to ba fi i silẹ ko ṣe nnkan kan. Amọ ki Buhari ma purọ o, kijọba yii naa ma si purọ, bẹẹ ni ki wọn ma gbe Tinubu jade lati purọ fun wa. Ọrọ pe Buhari fẹẹ dojukọ iṣẹ ijọba ni ko ṣe ni i le jade ki i ṣe ọrọ to mọgbọn dani, ọrọ ẹtan ati abosi ni. Oṣu kan ataabọ pere ni ibo ku, Buhari si ti lọ nilẹ yii nigba ti ara rẹ ko ya fun bii oṣu mẹrin o le. Bi Buhari ba fi oṣu mẹrin jade ti ijọba rẹ ko daru, ṣe oṣu kan aabọ to fẹẹ fi ṣe ipolongo ni yoo da ijọba naa ru ni. Irọ niyẹn, awa ko fẹ ẹ. Gbogbo eeyan lo fẹẹ ri oju Buhari, nitori oun ni wọn fẹẹ dibo fun. Ki i ṣe Tinubu ni wọn fẹẹ ri, nitori ko si ohun to pa oun ati awọn araalu pọ, ko ṣa gbe apoti pe oun fẹẹ du ipo kankan. Ẹ jẹ yaa tete wa iṣẹ mi-in gbe le Tinubu lọwọ, Buhari lawọn eeyan fẹẹ ri o.

 

 

(6)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.