O ṣoju mi koro; Atiku ṣe misiteeki, aṣiṣe nla

Spread the love

Bi eeyan ba ṣe aṣiṣe to tobi diẹ lawọn oloyinbo maa n sọrọ bẹẹ jade, wọn aa ni tọhun ṣe misiteeki. Ni ọjọ Satide to kọja yii, Atiku ṣe misiteeki tirẹ naa, nigba to sọ pe oun ko ni i ba wọn jiroro nibi ipade tawọn kan ṣeto fun gbogbo awọn ti wọn ba fẹẹ du ipo aarẹ lati waa ṣalaye ohun ti wọn fẹẹ ṣe fawọn ọmọ Naijiria bi wọn ba di aarẹ. Atiku lọ si Amẹrika, o si sare pada wale lati le waa kopa ninu ijiroro naa ti gbogbo ọmọ Naijiria ti n reti. O mura daadaa fun eto naa, o si tete de ibi ti wọn ti fẹẹ ṣe e, igba to waa debẹ ti wọn sọ pe Aarẹ Muhammadu Buhari ko wa, iyẹn lo bi i ninu to fi ni oun ko kopa ninu eto naa mọ, o ni oun ko ni ijiroro kan ti oun fẹẹ ṣe ti Buhari ko ba ti wa. O ni awọn ibeere ti wọn fẹẹ beere, ati awọn ọrọ ti oun fẹẹ sọ, ori ijọba to wa lode bayii loun fẹẹ sọ ọ le lori, nitori ohun to jẹ ki wọn fẹẹ du ipo aarẹ niyẹn, ṣugbọn nigba ti olori ijọba naa ko ti wa, oun ko ni ijiroro ti oun fẹẹ ṣe, oun ko si ni i kopa ninu rẹ. Alaye ti ko muna doko gbaa ni, awọn ti wọn si n ṣeto ipolongo eto oṣelu rẹ ko gba a nimọran daadaa. Akọkọ ni pe ki i ṣe Buhari ni Atiku fẹẹ ba sọrọ, ki i ṣe ija ni wọn si ni ki wọn waa ba ara wọn ja, ki kaluku waa sọ ohun to ba fẹẹ ṣe fawọn araalu ni. Bi wọn ba ṣe alaye bẹẹ, awọn eeyan yoo fi mọ ẹni to yẹ ki wọn dibo wọn fun gan-an ni. Anfaani ni iru ipade ijiroro bayii maa n fun awọn oloṣelu ti wọn ba fẹẹ du ipo lati ri ọpọlọpọ araalu ti yoo tẹle wọn lẹyin, ti wọn yoo si dibo fun wọn, nitori awọn ọrọ ti wọn ba gbọ lẹnu wọn. Bi Atiku ba ni ohun gidi to fẹẹ ṣe fun awọn ọmọ Naijiria, asiko yẹn ni anfaani gidi wa fun un ti iba sọ ọ, awọn ti wọn si n pe e ni ole ati akowojẹ, asiko naa ni iba ṣalaye gbogbo ohun ti wọn ko mọ nipa ẹ, idi ti wọn fi n pe e lole, ati idi ti wọn fi n pe e ni akowojẹ. O daju pe bo ba ri alaye gidi ṣe lori awọn ẹsun wọnyi, ọpọ awọn ọmọ Naijiria ni yoo tẹle e lẹyin, ti wọn yoo si tori rẹ dibo fun un. Ati pe bi Buhari ba wa nibẹ, awọn atako ati ọrọ ti oun paapaa yoo sọ le din iyi ati apọnle ti Atiku iba gba ku, o si le ma niyi to bi iba ṣe gbayi to ba jẹ ko si Buhari nibẹ. Gbogbo ohun to yẹ ki Atiku ro pọ niyẹn, ko ko awọn iwe eto rẹ jọ, ko si bẹrẹ alaye, koda bo ba n ṣe alaye rẹ to n bu Buhari nitori pe ko wa, awọn eeyan yoo maa patẹwọ fun un ni. Amọ oun naa waa ṣe bii ọbun to ri iku ọkọ tiran mọ, to ni ni ọjọ ti ọkọ oun ti ku, oun ko fomi kanra, ki ọkọ rẹ too ku nkọ! O jọ pe Atiku paapaa ko ni ọrọ gidi to fẹẹ sọ ni, iyẹn loun paapaa ṣe fi ti Buhari kẹwọ, bii igba pe oun naa si sa lọ ni. Awọn ohun tawọn ọmọ Naijiria fẹ kọ niyi, aṣaaju ti yoo ba wọn sọrọ, ti wọn yoo si le mu ohun rẹ dani, ti wọn yoo le gbe ọrọ rẹ ka iwaju rẹ lọjọ iwaju pe awọn ohun to sọ niyi, awọn ileri to ṣe niyi, iru awọn aṣaaju bẹẹ lawọn ọmọ Naijiria fẹ, ki i ṣe awọn oloṣelu ti wọn n sa funra wọn. Misiteeki gidi l’Atiku ṣe yii, bi iru anfaani bẹẹ ba tun yọ lọjọ iwaju, ko ma dan an wo, o si gbọdọ wa aaye mi-in, ko mọ ibi ti yoo ti ba araalu sọrọ ni gbangba, tawọn eeyan yoo beere ọrọ lọwọ rẹ, ti yoo si fun wọn lesi, iyẹn la fi le mọ pe ọkunrin yii fẹẹ ṣejọba daadaa fun Naijiria loootọ. Eyi to n ṣe yii ko yatọ si tawọn to ku, abi kin ni iyatọ ninu igun pẹlu ọbọ, apari ati apadii lawọn mejeeji jare.

 

(95)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.