O ṣẹlẹ! Idi ti Tinubu ko fi fẹ ki Ambọde ṣe gomina Eko mọ ree o

Spread the love

Ko ṣee ṣe. Ọga meji ko le wa ninu ọkọ kan naa, bẹẹ ni owe Yoruba wi. Ṣugbọn ni ipinlẹ Eko, ọga ti fẹẹ maa lọ si bii mẹta mẹrin, bi ọga si ṣe n pọ to ni agbara ẹni to jẹ olori awọn ọga pata, iyẹn Jagaban funra rẹ, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, bẹrẹ si i dinku, agbara naa si ti dinku debii pe arifin ti fẹẹ maa wọ ọ. Iyẹn ni Tinubu sọ pe oun ko ni i gba mọ, asiko ti to bayii lati jẹwọ fun kaluku pe ọga ni wọn n pe ni masita, ọga lọga yoo si maa jẹ lọjọkọjọ. Yoo ṣoro gidi gan-an ki Gomina Akinwumi Ambọde too ri tikẹẹti ẹgbẹ APC gba lati fi dupo gomina naa lẹẹkeji, bo ba si jẹ bi nnkan ti n lọ yii ni, afaimọ ki kinni naa ma ti bọ lọwọ rẹ patapata. Aarẹ Muhammadu Buhari ti da si ọrọ naa, ṣugbọn ki i ṣe pe o da si i nitori ki wahala ma ba Ambọde kọ, nitori ki wahala ma ba ẹgbẹ APC ni ipinlẹ Eko ni.

Ṣugbọn Tinubu ti fi Buhari lọkan balẹ pe ko ni i si ewu kankan nidii ọrọ naa rara, nitori apa oun ka gbogbo ohun to n ṣẹlẹ, oun si mọ bi awọn yoo ti gbe eto naa gba ti ko ni i pa ẹnikẹni lara. Ọba ilu Eko naa, Riliwanu Akiolu, ti sọ si i, ṣugbọn Alaroye gbọ pe nigba ti Tinubu ṣalaye ohun to n lọ fun Kabiyesi, niṣe lọba naa ṣe mẹdọ, to si sọ pe bi Aṣiwaju ba ti fẹ ki ọrọ naa ri loun fara mọ. Itumọ eyi ni pe Ambọde n lọ niyẹn, afi ti Tinubu ba yi ero rẹ pada lori ọrọ naa, ko si too ronu pada, aa jẹ pe boya Ambọde ni iwe adehun kan to tọwọ bọ, tabi awọn ofin kan to fọwọ si pe oun yoo maa tẹle titi laye, ki i ṣe titi digba ti yoo fi ipo gomina silẹ nikan kọ o, titi di igba ti yoo dagbadagba, ti yoo jade laye ni, nitori ohun ti odo ba de mọlẹ ki i ri ita mọ. Bi ọrọ naa ti le to niyẹn.

Kinni kan lawọn eeyan ko mọ ninu ọrọ yii, iyẹn ni pe ki i ṣe ohun ti wọn n gbe kiri pe o da ija silẹ laarin Tinubu ati ọmọọṣẹ rẹ yii lo faja, ohun to fa ede-aiyede ti Tinubu fi taku pe oun ko ni i jẹ ki ọmọkunrin naa ṣejọba lẹẹkeji lagbara ju eyi tawọn eeyan n gbe jade yii lọ. Loootọ lo jẹ ọpọ awọn ti wọn wa lẹyin Tinubu, paapaa, awọn ti wọn jẹ alagbara ninu ẹgbẹ APC Eko ni wọn sọ pe Ambọde ko wo oju awọn, to si jẹ gbogbo awọn ọna ti wọn fi n jẹun lo ti di mọ wọn pata, ti gbogbo wọn si ti duro de e pe bo ba di asiko ibo, wọn yoo fi oju rẹ ri mabo, sibẹ, ki i ṣe ọrọ ti awọn yii sọ fun Tinubu lo ko wahala ba Ambọde, ohun to ṣẹlẹ jinnu ju bẹẹ lọ. Loootọ niroyin mi-in de ọdọ Tinubu pe Ambọde n yanju ara tirẹ pẹlu owo Eko, ti ko si jẹ kawọn ti wọn sun mọ ọn jẹ nibẹ, iyẹn paapaa ki i ṣe ohun ti Tinubu tori ẹ binu.

Akọkọ ohun to fa ija gẹgẹ bi iwadii Alaroye ti fihan ni pe gbogbo awọn ọmọ ti Tinubu fẹyin pọn lo n pada da a, ti wọn si n ṣakọ si i pe ọga lawọn naa laaye ara awọn, iyẹn lẹyin ti agbara ba ti bọ si wọn lọwọ tan. Tinubu ti sọ ni aimọye igba pe ninu gbogbo awọn ọmọ ẹyin oun ti oun ran jade, ti oun si gba agbara fun ninu oṣelu, ko si eyi to da bii Raufu Arẹgbẹṣọla ti ipinlẹ Ọṣun ninu gbogbo wọn. O ni awọn miiran ti oun ti ro pe ọmọ daadaa ni wọn, wọn ko ni i dalẹ, wọn yoo ṣe ohun ti awọn ba ni ki wọn ṣe, ti wọn ba ti debẹ tan, ti ara wọn ni wọn yoo mojuto, ti wọn yoo si fẹẹ ba gbogbo eto to ti wa nilẹ tẹlẹ jẹ pata. O ni awọn wọnyi ki i bikita mọ bi ile oṣelu ti oun ti kọ lati ọjọ yii ba wo tabi ko wo, nitori loju oun bayii ni wọn yoo ṣe maa wa iṣubu oun. Awọn eeyan naa si ti pọ gan-an.

Ninu awọn eeyan yii ni Babatunde Raji Faṣọla wa, ẹni to ṣe gomina Eko laarin ọdun 2007 titi di 2015. Ọpọ awọn eeyan ti wọn dide si ọrọ Faṣọla yii lasiko ti Tinubu ni ko ni i ṣe ijọba Eko lẹẹkeji ni Tinubu n sọ fun bayii pe ṣe wọn ri ohun ti wọn ko oun si, nitori Faṣọla lo agbara tirẹ funra rẹ lati ri i pe oun da duro, ati pe ko si ohun ti Tinubu le ṣe lati fi bo irawọ toun naa mọlẹ. Eleyii han lasiko ti wọn fẹẹ mu minisita lati Eko, Aṣiwaju ti ni awọn ọmọ tirẹ to fẹẹ mu ni ipinlẹ kọọkan, ṣugbọn awọn Faṣọla gba ọna mi-in yọ si ọga, wọn si gba ipo naa lai jẹ pe oun funra rẹ fọwọ si i fun wọn. Ni bayii, ọrẹ awọn Buhari ati alatilẹyin awọn aṣofin ti wọn ba fẹẹ ba Tinubu ja ni wọn ni Faṣọla n ṣe, bo tilẹ jẹ pe ko gbe ọrọ naa ru, ko si ba ọga rẹ yii ja ni gbangba.

Ohun to waa dun Tinubu ju ni ti ọrọ Faṣọla ni pe gbogbo bi wọn ti gbiyanju to lati le mu un, tabi ki wọn ge iyẹ apa rẹ, ko ṣee ṣe fun wọn rara, ọrọ rẹ ko si yatọ si bii igba ti wọn ti ti oje bọ olooṣa lọwọ, ti ko ṣee bọ kuro lọwọ rẹ mọ. Nigba ti wọn ni ki awọn fiya kan jẹ Faṣọla, ti awọn aṣofin Eko si bẹrẹ si i ṣe giragira pe awọn yoo din owo ifẹyinti ati anfaani rẹpẹtẹ ti Faṣọla n gba gẹgẹ bii ẹni to ti ṣe gomina Eko ku, ohun ti wọn ba nidii awọn akọsilẹ naa ko dara rara. Ohun to wa nibẹ ni pe ẹnikẹni to ba ti ṣe gomina Eko lẹẹmeji, to si lo saa rẹ pe, gbogbo awọn anfaani yii lo tọ si i, ko si si aṣofin tabi ẹnikẹni to gbọdọ gba wọn kuro lọwọ rẹ. Bẹẹ awọn anfaani naa pọ ju, nitori Tinubu funra rẹ lo gbe e kalẹ, ko si si bi wọn yoo ti yọ ti Faṣọla ti wọn ko ni i yọ tirẹ naa danu.

Lara ofin yii ni pe ẹnikẹni to ba ṣe gomina Eko fọdun mẹjọ, ijọba yoo kọ ile fun un si Eko ati si Abuja, bi wọn o ba si le kọ ile, wọn yoo ra fun un nibẹ, ibi to ba si dara ju ni wọn gbọdọ kọ awọn ile mejeeji yii si. Iyẹn ni pe o ti di dandan fẹni to ba ṣe gomina Eko lẹẹmeji lati ni ile ni Eko ati Abuja. Bẹẹ ni yoo ni awọn iranṣẹ, gbogbo awọn ọlọpaa ati SSS ti wọn ba ba a ṣiṣẹ, mẹrin mẹrin ni wọn yoo da duro foun nikan ti yoo si maa lo wọn, bẹẹ ni ijọba Eko ni yoo si maa sanwo wọn. Iyẹn tumọ si pe Faṣọla naa yoo ni awọn SSS ti yoo maa ṣọ ọ, bẹẹ ni awọn ọlọpaa yoo maa tẹlẹ e kiri bii igba pe o ṣi wa nipo gomina, gẹgẹ bi wọn ti n ṣe fun Tinubu titi doni yii. Bakan naa ni wọn yoo ko mọto tuntun iru eyi to ba fẹ marun-un fun un, ọdun mẹta mẹta ni wọn yoo si maa paarọ awọn mọto naa fun un.

Bo ba ti lo mọto kan fọdun mẹta, dandan ni ki wọn paarọ rẹ, mọto marun-un lẹẹkan naa si ni, gẹgẹ bii gomina atijọ! Tinubu funra rẹ lo ṣe e bẹẹ! Bo ba ti waa wa nipo naa, iye owo gan-an ti gomina ipinlẹ Eko ba n gba lọwọ, iye owo naa ni wọn yoo maa san foun naa gẹgẹ bii gomina atijọ. Iyẹn ni pe bi gomina Eko ba n gba miliọnu marun-un loṣu bayii, miliọnu marun-un loṣu naa ni wọn yoo maa san fun gomina atijọ. Lẹyin eyi ni wọn yoo maa gbọ bukaata oun atawọn idile rẹ, ohun ti wọn yoo jẹ, ati ileewosan to ba wu wọn ti wọn yoo lo lagbaaye, ti wọn yoo si sanwo gbogbo awọn oṣiṣẹ to ba n ba a ṣiṣẹ. Agbara nla ni eleyii yoo fun ẹnikẹni to ba ti ṣe gomina yii ri, ko si ni i si ẹni ti yoo tun ni agbara to o ni ipinlẹ naa ju boya Aṣiwaju funra rẹ lọ.

Gbogbo eleyii ni wọn mura lati gba kuro lọwọ Faṣọla, ṣugbọn wọn ri i pe ko ṣee ṣe, afi ti wọn ba gba ti Tinubu naa. Eleyii ko waa dun wọn ju bii agbara ati owo buruku ti Faṣọla tun ni, agbara naa si pọ debii pe awọn eeyan ti wọn ti ba a ṣiṣẹ ri, awọn ti wọn ṣe kọmiṣanna labẹ rẹ wa lara awọn ti wọn n dide tako Tinubu bayii, ti wọn si n sọ pe ko le maa paṣẹ Eko bo ti ṣe n pa a yii, afi ki awọn gba kinni naa kuro lọwọ rẹ, koun naa tiẹ jokoo na, ko lọọ fẹyin ti, o ṣa ti dagba, o si ti ṣe iṣẹ naa debi kan. Eleyii ko daa rara, ko ba Tinubu lara mu, nitori bii igba ti eeyan ba fẹẹ pa agbalagba oloṣelu ni yoo ni ko ma ṣe oṣelu mọ, nitori wọn yoo sọ pe awọn ko mọ iṣẹ mi-in, tabi owo mi-in to ju oṣelu yii lọ. Tinubu ko fẹ ki iru eleyii tun ṣẹlẹ mọ, ko fẹ ki alagbara Eko tun di mẹta.

Ọna kan naa ti agbara Eko ko fi ni i di mẹta ni ki Ambọde ma lọ lẹẹkeji, nitori bi oun naa ba ti le lọ lẹẹkeji, gbogbo ohun to tọ si awọn Tinubu yii naa ni yoo tọ si i, ati pe saa keji yii ni yoo lo lati fi fi ẹsẹ ara rẹ rinlẹ daadaa, ti oun naa yoo ni awọn ọmọ tirẹ lẹyin, ti apa ko si ni i ka a mọ. Tinubu n sọ fawọn eeyan tirẹ pe bo ba jẹ nigba ti Faṣọla ti ṣe ijọba akọkọ, ti wọn ko si fẹ ko ṣe ẹẹkeji ni awọn eeyan ti fi oun silẹ ki oun ṣe bẹẹ ni, ko si bi yoo ti lagbara loni-in, ti agbara naa yoo si pọ debii pe apa oun ko fẹẹ ka a mọ. O ni Ambọde yii funra rẹ ko tilẹ duro ki oun gbajọba lẹẹkeji to ti bẹrẹ si i yọ ọwọkọwọ, oju ti yoo si ba ni kalẹ ni, ko ni i ti owurọ maa ṣepin. O ni bi awọn ba fi le jẹ ki ọmọkunrin yii ṣe ẹẹkeji, ohun ti yoo ti idi rẹ yọ, Ọlọrun jẹ ko dara foun ati awọn ti wọn tẹle oun ni.

Lara ohun ti ọkan rẹ ko si ṣe na si Ambọde ni ti iroyin to n jade, ti ko si yẹ ko jade. Iroyin nipa ileeṣẹ Alpha Beta to jẹ ileeṣẹ Tinubu. Ṣe Alaroye gbe kinni naa jade bi ọga agba pata fun ileeṣẹ naa tẹlẹ, ẹni to mọ gbogbo aṣiri wọn ṣe jade laipẹ yii, to kọwe si EFCC, to ni awọn Tinubu ki i san owo-ori, bẹẹ owo Eko ti wọn n fi ileeṣẹ Alpha Beta yii ji ko pọ debii pe bi awọn ara Eko funra wọn ba gbọ, wọn ko ni i ṣadura fun Tinubu, ọga awọn. Awọn Tinubu n binu si ọkunrin ọga agba tẹlẹ yii gidigidi. Amọ inu ti wọn bi si i ko to eyi ti wọn n bi si Ambọde, wọn ni awọn aṣiri yii ko le jade bi ko ba jẹ olori ijọba Eko naa mọ nipa rẹ, ati pe ko sohun to le maa ki i laya lati maa sọ gbogbo ohun to n sọ yii bi ko ba jẹ o ni atilẹyin awọn alagbara, ko si si alagbara kan to le wa lẹyin rẹ ju gomina lọ.

Bo tilẹ jẹ pe wọn ko gbe ọrọ naa ko Ambọde loju, lara ohun ti wọn fi mọ pe bo ba pẹ, bo ba ya, yoo dalẹ awọn niyi, nitori wọn mọ pe oun naa ti fi orukọ ileeṣẹ kan silẹ nigba kan to fẹẹ maa fi ṣe iṣẹ ti Alpha Beta yii n ṣe gan-an, iyẹn ni pe o fẹẹ gba iṣẹ lọwọ ọga rẹ, o fẹẹ gbaṣẹ lọwọ Tinubu. Awọn eeyan ti wọn jẹ ti Tinubu sọ fun Alaroye pe aṣiri ti Ambọde ati awọn tirẹ n jẹ ko tu sita yii, bo ba jẹ o mọ aburu ti yoo fi da si ọga lọrun bi ọrọ naa ba fẹju tan ni, ko ni i ṣe bẹẹ rara. Eyi lo ṣe jẹ pe bi nnkan si ṣe wa yii, o dara ki wọn tete da a duro, ko too di pe yoo di iyọnu fun wọn, nitori kekere la ti n pẹka iroko, to ba dagba tan, ẹbọ ni yoo maa gba lọna oko. Amọ iru awọn ọrọ bayii ko ṣee sọ sita, awọn miiran ti wọn si n ja ija naa paapaa ko mọ ohun to n lọ, awọn kan n ja ni tiwọn ni.

Tinubu ko si gbagbe gomina to ṣẹṣẹ jẹ ni Ekiti, iyẹn Kayọde Fayẹmi. Ọkan ninu awọn ọmọ rẹ to le ku sẹyin rẹ ni lọdun 2007, koda, bi wọn ba ni ko tọwọ bọna nigba naa, ko ni i boju wẹyin ti yoo fi tọwọ bọ ọ. Eyi ni Tinubu sọ fawọn eeyan pe oun ro pọ ti oun fi nawo nara lori ibo rẹ, ti oun si ri i pe o di gomina Ekiti dandan. Ṣugbọn nigbẹyin, niṣe ni Fayẹmi kọyin soun, to n pẹlu awọn ọta oun ba oun ja, to n sọ lẹyin oun ti oun n pada gbọ pe ko sohun ti oun le ṣe, awọn lawọn wa lẹyin oun tawọn aye ṣe n ro pe oun lagbara, ati pe bi awọn ba ti kuro tan, aye yoo ri i pe oun ko lagbara kankan. Tinubu ko fẹ ki Fayẹmi ba Buhari ṣiṣẹ, wọn gba ẹyin yọ si i lori ọrọ naa ni, ko si le ṣalaye rara pe bayii lawọn Fayẹmi ṣe di minisita labẹ Buhari, nitori o da bii pe ọdọ El-Rufai ni wọn ba wọle.

Loni-in yii, ko si ẹni to le sọ ẹni to koriira Tinubu ju ninu Fayẹmi ati Rotimi Akeredolu to wa l’Ondo, bẹẹ Tinubu ni oun loun fa gbogbo awọn yii lọwọ soke, ko si le dara fun wọn naa loun ṣe. Kukute kan ko waa gbọdọ da ni lepo nu lẹẹmeji o, iyẹn ni Jagaban ṣe n lo ọgbọn oloṣelu nla fun Ambọde, ohun to si n ṣẹlẹ ju eyi ti awọn eeyan ro lọ. Ki i ṣe pe Ambọde funra rẹ ko ti rin sun mọ awọn eeyan ti wọn wa l’Abuja pe ki wọn gba oun, awọn naa si ti mura pe awọn yoo gba a, ṣugbọn ibi ti ọga wọn gba yọ si wọn lo le ju eyi ti wọn mọ lọ, o si ti pari eto naa ko too di pe Ambọde ati awọn tirẹ mọ ohun to n lọ rara. Igbagbọ Tinubu ati awọn ti wọn n ṣiṣẹ fun un ni pe bi gomina kan ba ti jẹ l’Ekoo, to ba jẹ ẹẹkan naa lo lọ nipo rẹ, agbara ti yoo ni ko ni i to o lati fi ṣe ohunkohun, ko si ni i le tako ọga lae.

Ohun to si fa a to fi n ṣe eyi ko ju pe ọrọ Eko ti di ibẹru gidi si oun naa laya lọ, nitori awọn ọta rẹ ṣẹ n pọ ju, wọn n gbara jọ lati gba Eko lọwọ rẹ. Ọkan ninu awọn ti wọn sun mọ ọn gidi yọ sọ fun Alaroye bayii pe, “Abi ki lẹ n wi yii, ọgbọn ni baba n lo, awa naa ti mọ pe o maa ṣoro lati lo agbara kan lori ẹni to ba wọle gẹgẹ bii gomina ni ipinlẹ Ogun ati Ọyọ, nitori awọn gomina ibẹ funra wọn ni wọn n da ṣejọba ara wọn lai pe ẹnikẹni si i. Bi Ondo ba bọ lọwọ wa, ti Ekiti si tun bọ, ṣe ka tun laju silẹ ki awọn alatako gba Eko mọ wa lọwọ ni! Ko jọ ọ! Tabi ẹyin o mọ pe bii igba ti wọn kan posi iṣẹ oṣelu Jagaban funra ẹ ni. Iyẹn la ṣe n fi gbogbo ara ja. Bọbọ yẹn o ni i pada wa mọ o, to ba dẹ fi di pe o pada, o maa tọwọ bọwe, gbogbo nnkan ta a ba fẹ lo maa ṣe!”

Bo tilẹ jẹ pe awọn ọmọ Tinubu kan ṣi n sọ pe Jagaban ti jeburẹ, ko ni i binu mọ, o ti dariji Ambọde, sibẹ, awọn ọmọ ẹyin rẹ ti wọn ti jade lawọn ko le wọle mọ, ọrọ ti Aṣiwaju funra rẹ si n sọ ko fọkan ẹni kan balẹ. Ọkan Ambọde lo wa loke ju ṣaa o, nitori ko mọ ibi ti ọrọ naa yoo ja si rara. Bi oun ṣe n sa sọtun-un o, bẹẹ lawọn to fẹẹ gbajọba lọwọ rẹ ti wọn fa Jide Sanwoolu kalẹ naa n sa gba osi, kaluku lo si n sọ pe Tinubu yii naa lo wa lẹyin oun, ohun ti Tinubu funra rẹ si n tẹnumọ ni pe ko si ija ni ṣọọṣi, ṣadura ki n ṣe amin ni, ki gbogbo wọn bọ si gbangba, gbangba laṣa n ta, aṣa ki i ta ni kọrọ, ki gbogbo wọn jade sọdọ awọn ọmọ ẹgbẹ to ku, awọn ni wọn yoo fa ẹni to ba wu wọn ninu wọn kalẹ lati waa ṣe gomina Eko o.

Ṣugbọn awọn ti wọn mọdi ọrọ sọ pe bo ba jẹ bẹẹ ni Tinubu ṣe, bii igba pe o kan Ambọde mọ agbelebu ni o, nitori ohun gbogbo ti pari niyẹn, ki ọmọkunrin naa mura lati pada siluu Ẹpẹ ni: ko si ibi ti yoo gbe e gba, ipo gomina Eko bọ lọwọ rẹ titi aye niyẹn. Bi kinni naa ti n lọ si ko ye awọn ope, awọn oloṣelu lo n ta ayo laarin ara wọn, asiko yii la o si mọ ọga awọn ọta, o ku diẹ ginngin!

(30)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.