O ṣẹlẹ, Ambọde tu aṣiri nla O ni Sanwoolu ti wọn fẹẹ fa kalẹ ti lu jibiti ri l’Amẹrika O tun ni alawoku ni Tinubu kede atileyin fun Sanwoolu

Spread the love

Ọrọ ti di fiimu agbelewo bayii ninu ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Eko, ipa pupọ lo pin si, ko si ṣe e wo tan lẹẹkan naa, diẹ diẹ leeyan yoo maa wo o. Apa kan ninu rẹ lo tun ṣẹlẹ ni ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ ta a wa yii, nigba ti Gomina ipinlẹ Eko lọwọlọwọ, Ọgbẹni Akinwumi Ambọde, sọ ogulutu ọrọ lasiko to pepade oniroyin sile ijọba, n’Ikẹja ni nnkan bii aago mẹta ọsan ọjọ yii.

Ṣe lati ọjọ Satide ni ariwo ti n lọ pe gomina fẹẹ ba awọn oniroyin sọrọ, aago meji ọsan ni wọn pe e, ṣugbọn eto naa to ọwọ aago mẹta ọsan ko too bẹrẹ. Nigba ti Ambọde si duro lori patako lati sọrọ, o ṣalaye awọn iṣẹ takun takun to ti ṣe sipinlẹ Eko lasiko ijọba rẹ, ati bo ṣe ko awọn ero to pọ, ti ko si ẹni to ko iru rẹ wa sinu ẹgbẹ oṣelu APC. O ni oun pinnu lati tun dupo gomina nitori pe oun ri i pe oun kun oju osunwọn, ati pe o ṣe pataki ki ẹgbẹ fun ẹni to ba ṣe daadaa, to si sin ẹgbẹ tọkantọkan lanfaani lati tẹ siwaju ninu iṣẹ to n ṣe.

Ọkunrin yii ni ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC to jẹ olufọkansin tootọ loun, ṣebi aṣọ ẹgbẹ APC ni wọn ri i ti oun wọ wa yii, oun ko si ni i lọkan lati kuro ninu ẹgbẹ naa, bẹẹ loun si dunnu si iṣejọba Buhari ati Oṣibajo pe ki wọn pada wọle sileejọba lẹẹkeji, ṣugbọn ti ẹgbẹ ko ba fa ẹni ti ko kun oju osunwọn kalẹ, o le ṣakoba fun erongba yii nipinlẹ Eko. O ni oun maa dije dupo gomina, bi ẹnikẹni ba si duro nidii ko fa wahala tabi ijangbọn kankan, awọn maa fi ọwọ ofin mu un.

Nigba ti ọkan ninu awọn oniroyin beere ọrọ lọwọ ẹ nipa bi yoo ṣe bori ọkan ninu awọn oludije, Ambọde ni alatako oun ti awọn fẹẹ jọ dije yii ki i ṣe ẹni ti o kunju osunwọn ti o le ba oun fori gbari. O ni, “Ṣe ẹni ti wọn mu fun pe o na ayederu owo dọla ni kilọọbu kan niluu oyinbo la fẹẹ sọ, to jẹ pe o lo bii oṣu meloo kan latimọle ki wọn too yanju ẹ to fi raaye jade. Akọsilẹ wa ni ọsibitu ijọba to wa ni Gbagada, ẹ lo sibẹ kẹ ẹ lọọ beere, lẹni to jẹ pe o gba itọju lẹyin to ni aisan ọpọlọ.’’

O bu ẹnu atẹ lu ipinnu ẹgbẹ pe ẹni ti ko ba ti ni kaadi ẹgbẹ ko ni i dibo, o ni bii igba teeyan kan fẹẹ di awọn ọmọ ẹgbẹ to fẹẹ dibo lọwọ lati ṣe ojuṣe wọn ni, nitori ọpọ ọmọ ẹgbẹ ni ko ni kaadi yii to jẹ pe iwe idanimọ pelebe to ni fọto wọn nikan ni wọn ni, iru eyi to wa lọwọ oun paapaa. O ni ko daa ki wọn sọ pe awọn to ba niru iwe yii ko lẹtọọ lati dibo.

Ọkunrin naa kọ lati dahun ibeere kan ti gbajumọ akọroyin nni, Dele Mọmọdu, bi i pe ṣe o ti lo gbogbo ọna lati pari ija pẹlu ọga rẹ ati wi pe pẹlu ogun ti wọn gbe ti i, kin ni yoo ṣe ti wọn ko ba fun un ni tikẹẹti, Ambọde ni oun ko ni i dahun ibeere yẹn, nitori ko si ogun l’Ekoo.

Ṣugbọn ọrọ naa ko tan sibi ti gomina yii sọ ọ si, nitori ọkan ninu awọn adari ipolongo fun Jide Sanwoolu naa kọ ọrọ kan sori ẹka ayelujara ni Sannde yii kan naa. O ni latigba tawọn ti n ṣe ipolongo awọn, awọn ko bu Ambọde, ohun ti awọn fẹẹ ṣe lawọn n sọ, ṣugbọn pẹlu bi o ṣe waa bọ sita to lanu bu alatako rẹ to jẹ oludije awọn, o tanna wa ọrọ ni.

Ko si pẹ sigba naa ti awọn alatilẹyin Sanwoolu naa fi gbe atẹjade kan jade, nibi ti wọn ti ṣalaye pe ko si ooto kankan ninu ọrọ ti Ambọde sọ, wọn ni ọrọ oṣelu lasan ni.

Bakan naa ni Babajide Sanwoolu funra ẹ sọ pe oun ko ni ohunkohun ti oun fẹẹ sọ nipa ọrọ yii, nitori oun ko ni i maa pẹlu ọbọ jawura. O ni ohun ti o kan oun ju bayii ni bi oun yoo ṣe gbajumọ ipolongo oun.

Bakan naa ni Aṣaaju ẹgbẹ naa, Bọla Tinubu, ti fi atilẹyin rẹ han fun Ambọde. Lasiko to n sọrọ ni Sannde ọsẹ yii, o ni, o jọ ohun idunnu ati iwuri foun pe ọkan ninu awọn oludije naa jẹ ẹni to ti di ipo pataki mu lasiko iṣejọba oun, lasiko ijọba Faṣọla ati ti Ambọde yii paapaa.

O ni ta a ba n sọrọ nipa iriri ati imọ, o jẹ ẹnikan ti Ọlọrun fi gbogbo rẹ jinki. Tinubu ni bi iru awọn eeyan bayii ba wa lori akoso ijọba, ohun gbogbo yoo lo bo ṣe yẹ.

Bẹẹ lo tun fi aidun rẹ han si ipo ti gbogbo nnkan wa nipinlẹ Eko bayii. O ṣalaye pe ‘Awọn eto ati agbekalẹ ta a ni, ta a si n lo gẹgẹ bii atọna fun idagbasoke ipinlẹ yii, eyi ti emi pẹlu ijọba Faṣọla ṣamulo ni ijọba to wa lode lonii ko lo, wọn ti yẹsẹ kuro lori rẹ.’

O waa rọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC lati ri i pe wọn lo anfaani ibo abẹle yii lati ṣe atunṣe to yẹ, ki ohun gbogbo too bajẹ koja bo ṣe yẹ.

Ṣe o ti pẹ ti ọrọ yii ti n ja ran-in ran-in nilẹ, ti wọn si ti n gbe e kiri pe ọkunrin naa ko ni i pada sipo gomina lẹẹkeji nitori pe o ṣẹ awọn alagbara ninu ẹgbẹ APC nipinlẹ Eko. Bakan naa ni ariwo gbalu nigba naa pe Ọgbẹni Jide Sanwoolu ni wọn fẹẹ lo. Ere ni awọn eeyan kọkọ pe ọrọ naa, ṣugbọn nigba ti awọn agbaagba ẹgbẹ jade, ti wọn si ni Sanwoolu lawọn maa dibo fun lẹyin ti ọkunrin naa ti gba fọọmu lati dije dupo naa  ni wọn mọ pe ọrọ naa ti kuro ni ṣereṣere.

Lẹyin eyi ni Aṣiwaju Bọla Tinubu to jẹ olori wọn nipinlẹ Eko si fọba le e pe oun ko ni ẹnikẹni ti oun n ṣatilẹyin fun, o ni awọn ọmọ ẹgbẹ lo maa yan oludije wọn, ẹni ti wọn ba si yan naa lo maa gbapoti lati ṣoju ẹgbẹ.

Ambọde naa kọkọ pe ọrọ ọhun lọwẹ, ṣugbọn nigba to bẹrẹ si i laro ninu loun naa bẹrẹ si i yan ẹlẹbẹ kaakiri pe ki wọn ba oun bẹ ọga oun ko fori gbogbo ẹṣẹ ti oun ba ṣẹ ji oun. Ṣugbọn o jọ pe Aṣiwaju ti pinnu ohun to fẹẹ ṣe lọkan, ko si ṣetan lati yi ipinnu yii pada. Bẹẹ ni Aarẹ Muhamadu Buhari ranṣẹ si i, ẹgbẹ awọn gomina naa da si i, awọn lookọlookọ niluu Eko paapaa, ṣugbọn ibi kọọ naa lo fi n lelẹ.

Nigba to tun ya ni wọn sọ pe awọn yoo gbe ọrọ naa lọ si ọdọ igbimọ to maa n gbọ awọn ẹjọ to ba takoko nipinlẹ Eko ti wọn n pe ni *** (GAC). Lẹyin ọpọlọpọ ijokoo, awọn igbimo naa fẹnuko lọsẹ to kọja pe afi ki gbogbo apọn to ba fẹẹ dije dupo gomina l’Ekoo  kopa nibi eto idibo abẹle. Wọn si fọba le e ni Satide ọsẹ to kọja nigba ti wọn kede pe awọn ti fẹnuko pe Ọgbẹni Jide Sanwoolu lawọn maa dibo fun ni asiko ti ibo abẹle ba waye.

Ẹnikan yọ ọ sọ fun ALAROYE pe awọn ẹgbẹ naa ti kọkọ ṣepade pẹlu Ambọde, nibi ti wọn ti ni ki o juwọ silẹ fun Sanwoolu lati gba ipo naa, ṣugbọn ti gomina yii ni ko si ohun to jọ ọ. O ni oun ti ṣetan lati koju rẹ lasiko idibo abẹle, dipo ti oun yoo fi juwọ silẹ fun un. Eyi si wa lara wahala ti wọn ko ri yanju ti wọn fi tun sun ibo naa si ọjọ Aje ọsẹ yii, dipo ọjọ Aiku, Sannde to yẹ ko ti waye ṣaaju.

Eyi la gbọ pe ko dun mọ awọn agba ẹgbẹ ninu, wọn si ri igbesẹ gomina ọhun gẹgẹ bii afojudi. Idi ni pe gbogbo awọn alaga kansu mẹtadinlọgọta to wa nipinlẹ Eko lo ti fọwọ si Sanwoolu, bakan naa ni awọn ọmọ ileegbimọ aṣofin mẹrinlelaaadọta ti fara mọ ọn ninu awọn mẹtadinlọgọta.

ALAROYE tiẹ yọ ọ gbọ pe wọn ti n dunkooko mọ gomina naa pe bi ko ba fi jawọ lori pe oun fẹẹ dije dupo nibi eto idibo abẹle ọhun, bi ibo naa ba ti n kasẹ nilẹ ni awọn aṣofin yoo yọ ọ kuro nipo gomina. Gẹgẹ bii owe Yoruba pe bi eeyan n gunyan fun gbogbo ilu jẹ, yoo ni ọta tirẹ, beeyan si n sọko siluu, yoo ni ọrẹ tirẹ, awọn kan dide, wọn ni ọrẹ Ambọde ati alatilẹyin rẹ ni awọn. Awọn ri iṣẹ takuntakun ti gomina yii n ṣe, afi ko si pada si ori aleefa gẹgẹ bii gomina.

Ni Sannde ọsẹ yii ni ọgọọrọ awọn eeyan naa ṣe iwọde wọọrọwọ, ti wọn fi pẹtu si awọn tọrọ kan pe ki wọn jeburẹ, ki wọn fa Ambọde kalẹ ko maa ba iṣẹ rere ẹ to n ṣe lọ. Lati ile ijọba n’Ikẹja ni wọn ti wọde lọ si ibi ti wọn n pe ni Gani Fawẹhinmi Freedom Park ni Ọjọta.

Ko ti i sẹni to mọ ibi ti ọrọ naa yoo ja si nitori bawọn kan ṣe n sọ pe wọn ti sun gomina naa kan ogiri lo jẹ ko sọ awọn ọrọ to sọ lawọn kan n sọ pe ko ba ma sọ awọn ọrọ to sọ naa nitori bii igba to fẹẹ gbegidina ara rẹ ninu eto oṣelu ni nitori ẹni to n ba tayo naa maa pa a layo, wọn si maa fi oju rẹ gbolẹ kẹyin ni.

Oni ti i ṣe ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ni ireti wa pe eto idibo abẹlẹ lati yan ẹni ti yoo ṣoju ẹgbẹ APC ninu eto idibo ọdun to n bọ yoo waye, leyin ti wọn ti sun un siwaju fun ọpọlọpọ igba.

Esi naa ni yoo sọ igbesẹ ti Ambọde yoo gbe ti awọn ọmọ ẹgbẹ ko ba fibo da a pada lati dije.

(62)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.