Oṣu kan ni Yusuf yoo lo lẹwọn, atimọle ọlọpaa lo ti sa

Spread the love

Oṣu kan gbako ni Atiku Yusuf yoo lo latimọle ọgba ẹwọn latari pe o sa ni atimọle awọn ọlọpaa.
Ajọ Akoroyinjọ Naijiria (NAN), jabọ pe Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja, ni awọn ọlọpaa wọ afurasi ẹni ọdun mejidinlọgbọn naa lọ si kootu Majisreeti to wa l’Ọgba, ti wọn si fi ẹsun ole jija ati sisa nitimọle ọlọpaa kan an.
Agbefọba to moju rẹ ba kootu, Abiọla Adewale, sọ pe ọjọ kọkanlelogun, oṣu keji, ọdun yii, ni olujẹjọ huwa naa ni teṣan Shogunlẹ. O ni ni ogunjọ, oṣu keji, ni ọwọ tẹ Atiku, nibi to ti n ji ọkada gbe ni nnkan bii aago mẹta aarọ, ti awọn meji mi-in ti wọn jọ huwa naa si sa lọ.
Agbefọba naa ni lasiko iwadii awọn, ti olujẹjọ si fi wa ni atimọle ni o tun ti gbiyanju lati sa lọ ko too di pe awọn ọlọpaa teṣan mu un kalẹ.
Adajọ W.A Salami lo gbọ ẹjọ naa, o si gbe idajọ kalẹ lẹyin ti olujẹjọ ti gba pe loootọ loun jẹbi awọn ẹsun naa.
O ni ti Yusuf ko ba fẹẹ ṣẹwọn, o le ṣiṣẹ oṣu meji sin ilu.

(12)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.