Oṣisẹ kọsitọọmu foko pa awon egbe e meji lona Badagry

Spread the love

Oṣiṣẹ kọsitọọmu meji kan, Usman ati Kabiru, ni wọn padanu ẹmi wọn nibi ijamba mọto to waye lọjọ Abamẹta, Satide, to kọja yii loju ọna Eko si Badagry.

 

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, afi bii eedi lọrọ naa, nitori ẹni to ṣokufa ijamba mọto naa, oṣiṣẹ kọsitọọmu loun naa. Inu mọto Toyota Kamri ti nọmba ẹ jẹ YLA 121 BJ, ni wọn wa nibi ti wọn ti maa n da awọn ọkọ duro, nigba ti mọto akẹgbẹ wọn yii, iyẹn Toyota ti nọmba tiẹ jẹ YAB 366 JY gba a lojiji.

 

Loju ẹsẹ la gbọ pe awọn oṣiṣẹ kọsitọọmu naa jade laye nigba ti akẹgbẹ wọn to ni mọto keji wa ni ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun, nibi to ti n gba itọju ni ọsibitu jẹnẹra to wa niluu Badagry.

Ọkan lara awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju ẹ ti wọn ba wa sọrọ sọ pe fifọ ti taya mọto naa fọ lojiji lo ṣokunfa ijamba ọhun. O sọ pe ni nnkan bii aago mẹjọ ku iṣẹju mẹẹẹdogun ni iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ, bi taya mọto naa ṣe fọ ni dẹrẹba to wa mọto keji lọọ ṣẹri mọ mọto awọn eeyan ẹ.

 

Loju ẹsẹ tijamba naa waye ni Ọgbẹni Fatai Bakare ti ṣaaju ẹṣọ oju ọna, iyẹn FRSC, lọ sibi tijamba naa ti ṣẹlẹ, awọn gan-an ni wọn gbokuu awọn eeyan naa lọ si mọṣuari.

 

Saidu Abdulai to jẹ agbẹnusọ fawọn kọsitọọmu ni Sẹmẹ naa ti fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o sọ pe ibi kan naa lawọn mẹtẹẹta ti n ṣiṣẹ. Kayefi si ni ijamba naa jẹ fawọn. O ni awọn ti n gbe igbesẹ to yẹ lori awọn to ku ati ẹni to wa nibi to ti n gba itọju.

 

(31)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.