Ọṣinbajo ṣepade pẹlu Olu Ilaro atawọn oloṣelu

Spread the love

Ijọ ẹlẹsin Islam nni, Ahmadiyyah Muslim Jamat, lo n ṣe ipagọ ọlọdọọdun wọn niluu Ilaro. Ẹlẹẹkẹrindinlaaadọrin iru ẹ ni wọn n ṣe lọwọ ti wọn fi Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo ṣe alejo pataki. Ibẹ ni Igbakeji Aarẹ gba de ọdọ Olu Ilaro lọjọ Satide ijẹrin yii, ni wọn ba jọ tilẹkun mọri ṣepade pẹlu awọn oloṣelu kan.

Nibi ipagọ awọn Ahmadiyyah ti wọn n pe ni JALSA SALANA, to waye ni Ahmadiyyah Conference Ground, Owode, Ilaro, laarin ọjọ kẹrinla si ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kejila yii, ni Ọṣibajo ti ṣalaye bi inu rẹ ṣe dun to lati wa si Ilaro, o ni ilu naa ni wọn ti bi iya oun.

 

O gboriyin fawọn Ahmadiyyah fun bo ṣe jẹ pe ifẹ, alaafia ati iṣọkan ọmoniyan ni wọn gbe dani lati ayebaye, ti wọn ko si rẹyin ninu ipolongo naa. O ni bi wọn ba n ba a lọ bayii,  Ọlọrun funra rẹ yoo bukun fun Naijiria lọjọ kan, yoo si ba wa tun awọn ohun to ti bajẹ ṣe.

 

Olori Ahmadiyyah ni Naijiria, Dokita Mash’ hud Adenrele Fashọla, dupe lọwọ Igbakeji Aarẹ wa, o si gbe ami-ẹyẹ nla kan fun un  fun jijẹ oloṣelu toootọ, olufọkansin ti ko fi ti ẹlẹya mẹya ṣe.

 

Ọpọ oloṣelu lo wa nibi ipade yii, lara wọn ni olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun, Suraj Adekunbi, Oloye Tolu Ọdebiyi( olori ijọba ipinlẹ Ogun to fiṣẹ silẹ lẹnu ọjọ mẹta yii), Sẹnetọ Babafẹmi Ojudu. Koda, Triple A, Adekunle Akinlade, naa wa, gbogbo wọn lo jọ ṣẹyẹ fun Ọṣibajo.

Ṣugbọn kete ti Ọṣinbajo kuro nibi eto yii to gba aafin Olu Ilaro, Ọba Kẹhinde Olugbenle, lọ, awọn kan ko tẹle e lọ si aafin naa ninu awọn oloṣẹlu yii, ibi ipade Ahmadiyyah ni wọn ti ba tiwọn lọ.  Ọkan ninu awọn bẹẹ si ni Adekunle Akinlade. Koda, ọkan pataki ninu ọmọ ile igbimọ aṣofin Ogun to ba wọn de aafin ọhun, to si fẹẹ wọle sibẹ lati darapọ mọ ipade ọba naa ati Ọṣinbajo ko raaye wọle, niṣe ni awọn ẹṣọ oju ọna ko jẹ ki ọkunrin ti a forukọ bo laṣiiri naa wọle rara, wọn da a pada loju ọna ni. CP Iliyasu Ahmed ti i ṣe ọga ọlọpaa ipinlẹ yii naa jokoo sinu ọgba aafin ni, ko wọle rara.

ipade ti wọn tilẹkun mọri ṣe naa gba wọn to iṣẹju marundinlaaadọta, oye si foju han pe ọrọ oṣelu naa lo da le lori, paapaa, idibo ọdun to n bọ.

 

 

 

(3)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.