Oṣiṣẹ to le ni ẹgbẹrun kan gba igbega nipinlẹ Kwara

Spread the love

Ọsẹ yii ni awọn oṣiṣẹ ijọba bii ẹgbẹrun kan aabọ le mọkanla, (1,511) to wa laarin ipele keje si ikẹtadinlogun ti Gomina Abdulfatah Ahmed buwọ lu orukọ wọn fun igbega

yoo maa tẹwọ gba iwe igbega wọn.

Alaga ileeṣẹ ijọba to n mojuto ọrọ awọn oṣiṣẹ nipinlẹ Kwara, Alhaji Adelọdun Ibrahim, ṣalaye pe awọn oṣiṣẹ to din ni ẹgbẹrun meji, (1,658) lo kopa ninu idanwo igbega naa, nibi ti awọn to le ni ẹgbẹrun kan aabọ ti yege fun igbega.

Ibrahim sọ pe ijọba ipinlẹ Kwara maa n ṣe igbega fawọn oṣiṣẹ lọdọọdun, ko si si ọdun kan ti ko waye lati 2003.

“Mo fẹẹ fi gbogbo igboya sọ pe pẹlu igbega to waye lọdun yii, o fi han bi ijọba ṣe mu ọrọ awọn oṣiṣẹ lọkun-un-kundun. Fun idi eyi, ohun iwuri lo jẹ fun ijọba pe a o ni ajẹsilẹ lori igbega awọn oṣiṣẹ”. Alhaji Ibrahim lo sọ bẹẹ.

Ibrahim lu Gomina Ahmed lọgọ ẹnu bo ṣe buwọ lu igbega awọn oṣiṣẹ naa lai fi akoko ṣofo rara.

O waa ke si awọn oṣiṣẹ ijọba nipinlẹ Kwara lati fi ẹmi imoore han nipa ṣiṣe iṣẹ wọn takuntakun lai ṣe imẹlẹ.

 

 

 

 

(16)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.