Oṣelu tawọn Lai Muhammed yii naa ko daa

Spread the love

Awọn oloṣelu Naijiria ki i ni itiju rara. Wọn ki i ṣe ẹni to yẹ ka tẹle o, beeyan ba si lọgbọn lori daadaa, yoo yẹra fun awọn oloṣelu Naijiria, bi bẹẹ kọ, wọn yoo ṣi oluwa-rẹ lọna pa. Njẹ ẹni kan le sọ pe Lai Muhammed to ti fi ọpọlọpọ ọjọ ja lori Atiku Abubakar naa ni yoo pada waa maa tu aṣiri, ti yoo si maa ṣe tanadi rẹ bayii! Ṣugbọn iyẹn tilẹ kọ lọrọ to wa nilẹ yii, bi ko jẹ ipade awọn oniroyin ti minisita yii pe lọsẹ to kọja. Minisita naa pepade, ko si ri ọrọ gidi kan sọ nibẹ ju pe ki awọn ẹmbasi ilẹ Amẹrika ma fun Atiku ni fisa ati lọ si ilu wọn lọ. Tabi iru ọrọ wo ree. Pẹlu gbogbo iṣoro to n koju Naijiria lọwọlọwọ bayii, ohun kan ṣoṣo ti minisita to n ṣeto ikede fun Naijiria ri sọ ni pe ki Amẹrika ma fun Atiku ni fisa. Nitori kin ni! Lai Muhammed yii lo ti gbe iwe oriṣiiriṣii jade pe ole ni Atiku, o ji owo kan ko, o ṣe iwa ibajẹ ni gbogbo igba ti wọn fi n ṣejọba. Ṣugbọn titi di asiko yii, ati gbogbo bi EFCC ṣe n lọ sile ẹbi, ti wọn n lọ sile ara to, ti wọn si n fi imu awọn alatako fọn fere, wọn ko de ọdọ Atiku, koda, ko sẹni to gbọ ọ ri pe wọn n wa a. Bawo ni Lai yoo waa ṣe maa sọ kiri pe ole ni Atiku, nigba ti gbogbo ọmọ Naijiria mọ bi awọn EFCC ṣe n ṣe awọn ọmọ ẹgbẹ alatako ti wọn ba jaja gbọ pe wọn kowo jẹ. Bi EFCC ko ba gbe Atiku, ti ICPC ko mu un, ti Lai ko si le pe e lẹjọ ole jija funra rẹ gẹgẹ bii minisita ijọba, afi ki ọkunrin naa sinmi kantankantan sisọ jare. Bi Atiku ba jale, ki ijọba Buhari gbe e ka gbọ gbogbo ohun to ba ṣe. Lai yii naa lo sọ ninu ọrọ rẹ nigba kan pe Atiku ko le wọ Amẹrika nitori iwa ibajẹ to hu, ọkunrin naa si sọ pe oun fẹẹ lọ si Amẹrika bayii, o ni ki wọn fun oun ni fisa, awọn Lai tun ni ki Amẹrika ma fun un, ki wọn ranti awọn iwa ibajẹ ti wọn fẹsun ẹ kan an nibẹ. Iru ewo niyẹn. Awọn Lai ni wọn yoo sọ pe ade gun, awọn naa ni wọn yoo ni ade ko gun, awọn onikobokobo, kantankantan, rederede gbogbo

(14)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.