oṣa ifura ni yoo pa lagbaja …

Spread the love

Yoruba pẹlu oriṣiiriṣii ọrọ nla nla. Wọn aa ni, ooṣa ifura ni yoo pa lagbaja. Bẹẹ ifura ko ni ooṣa kan o, ohun ti kaluku ba ṣe naa ni yoo maa da sẹria fun un. Yoruba lo sọ pe ẹni to ba ṣe ohun itufu naa ni i kiyesikule, bẹẹ ni aṣebajẹ ni i tẹsẹ mọrin, aṣebuburu ni wọn n ki pe o ku ifura. Ohun ti gbogbo awọn ti wọn n ba Aarẹ Muhammadu Buhari ṣiṣẹ lọwọlọwọ bayii n ṣe lori ọrọ Alaaji Atiku Abubakar ti wọn jọ du ipo aarẹ Naijiria ninu ibo ta a di kọja yii ko yatọ si ẹni ti ooṣa ifura n yọ lẹnu. Awọn funra wọn ni wọn n fun Atiku ni okiki ti ko tọ si i. Bi ṣọja ṣe n pariwo pe Atiku lo fẹẹ dajọba ru, tabi o fẹẹ fi tipa gbajọba, bẹẹ ni awọn DSS n sọ, bẹẹ lawọn ọlọpaa n wi, awọn minista si ni ki wọn da ọrọ naa da awọn. Ibeere ni pe ki lo de ti Atiku kuku lagbara to bẹẹ, ṣe awọn ọlọpaa lo ni ni abi awọn ṣọja tirẹ, ṣebi ọwọ ijọba apapọ ni gbogbo agbara wa. Ṣugbọn koko to wa nibẹ ni pe ara n fu ijọba Naijiria, ifura naa si ti di arun si wọn lara. Awọn naa mọ pe awọn ṣe awo kan ti ko dara lasiko ibo to kọja yii, wọn mọ pe ki i ṣe ohun ti awọn ọmọ Naijiria beere ni wọn fun wọn. Bi ko ba jẹ bẹẹ, ki lo le ninu ọrọ to wa nilẹ yii. Bi a ba dibo, ti Atiku ba ni oun ri eru ti wọn ṣe foun nibi kan, tabi pe Buhari ko wọle, eru lo ṣe, niwọn igba ti ohun gbogbo ni akọsilẹ, eyi ko yẹ ko ko wahala ba ẹnikẹni. Ṣebi INEC lo ṣeto idibo naa, ijọba lo si ni INEC, ki i ṣe Atiku, ohun gbogbo si wa lọwọ wọn lati le gbe kalẹ pe bayii ni awọn ṣe ṣeto idibo naa si. Bi ika ba rojọ, ki i ṣe ika naa ni yoo da a, bi Atiku ba fẹẹ purọ mọ Buhari tabi to fẹẹ ba a lorukọ jẹ, gedegbe ni aṣiri rẹ yoo tu si ọwọ awọn to fẹẹ dajọ, gbogbo araalu yoo si ri i pe aferu-gbabukun ẹda kan ni. Ṣugbọn awọn ti wọn n ba Buhari ṣiṣẹ gan-an ni wọn n sọ ọ lẹnu, nitori o ṣee ṣe ko ma ran wọn ni awọn iṣẹ ti wọn n ṣe yii, o ṣee ṣe ko jẹ ẹru ohun ti awọn n jẹ lẹnu ni wọn ko fẹ ko bọ lọwọ awọn, tabi aburu ti wọn ti ṣe ti wọn fẹẹ bo mọlẹ lo n ba wọn ti wọn fi n bẹwu silẹ ti wọn gbe apẹrẹ wọ bẹẹ yẹn. Nigba ti eeyan ba ṣe aburu ti ko si fẹ ki aṣiri oun tu lo maa n huwa ti awọn eeyan ijọba apapọ n hu yii, o ni nnkan mi-in ninu. Ki i ṣe Naijiria nikan ni wọn ti n ṣeto idibo lagbaaye, nibikibi ti wọn ba si ti ṣeto idibo, ti ẹni to kopa ninu ibo naa ba ni esi idibo ọhun ko tẹ oun lọrun, oun n lọ sile-ẹjọ, ko sẹni ti i sọ pe ko ma lọ, bẹẹ ni ko sẹni ti yoo maa halẹ mọ ọn pe awọn yoo pa a, awọn yoo ba a niwa jẹ. Ati pe ni Naijiria yii naa, ki i ṣe akọkọ ti wọn yoo dibo aarẹ ti ẹni ti ko wọle yoo gba ile-ẹjọ lọ ree, ko si si igba kan to kuku buru fawọn ti wọn n ṣejọba to bayii, ti wọn yoo maa pariwo, ti wọn yoo maa dẹ oriṣiiriṣii okun silẹ fun ẹni to ba ọga wọn dije. Aarẹ Buhari yii naa dupo lẹẹmẹta ọtọọtọ ti ko wọle, gbogbo ẹẹmẹta yii naa lo si gba ile-ẹjọ lọ. O lọ sile-ẹjọ laye Ọbasanjọ, o lọ laye Yaradua, o si lọ laye Jonathan. Niṣe ni ko sẹni kan to bẹrẹ ariwo pe o fẹẹ fipa gbajọba, ti ko si si olori ijọba kan ninu awọn mẹtẹẹta to ni oun yoo ti i mọle, tabi wa ọran kan si i lẹsẹ. Ki lo waa de to jẹ oun to lọ sile-ẹjọ lẹẹmẹta pẹlu olori ijọba mẹta lawọn ọmọ ẹyin tirẹ waa n ṣe aburu bayii, ti wọn si n ko araalu lọkan soke, ti wọn n pa oriṣiiriṣii irọ ohun ti ko ṣẹlẹ kiri. Bi Atiku ba fẹẹ fi tipa gbajọba, iyẹn ko la ariwo lọ, ki awọn agbofinro sun mọbẹ, ki wọn si mu un, ki wọn ko ẹri silẹ lati fi ba a ṣẹjọ, ki wọn si fiya to ba tọ jẹ ẹ. Ṣugbọn gbogbo ariwo iranu ti wọn n pa kiri yii ko mu laakaye kankan lọwọ, wọn kan n fi Buhari wọlẹ, wọn si n fi ara wọn han bii alailọpọlọ ni. Bi iṣẹ yii ko ba ka yin lara, ẹ wa nnkan mi-in ṣe o jare.

(15)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.