Ọwọ tẹ awọn afurasi gbọmọgbọmọ meji to n dibọn bii were n’Ibadan

Spread the love

Pẹlu bi ọwọ awọn araadugbo Agbowo, n’Ibadan ṣe tẹ eeyan meji ọtọọtọ ti wọn fura si gẹgẹ bii gbọmọgbọmọ to n dibọn bii were laduugbo ọhun, afi ki awọn mẹkaniiki atawọn ti ki i baa mura daadaa kiyesi irin ẹsẹ wọn lagbegbe naa, ati kaakiri igboro Ibadan.
Lalẹ ọjọ jọ̣ Iṣẹgun, Tusidee, to kọja laṣiiri ọkunrin kan ti wọn ti maa n fi oju were wo laduugbo naa tu si awọn olugbe ibẹ lọwọ pe o kan n ṣe bii were bẹẹ lasan ni, niṣe lo maa n ji awọn ọmọde gbe, to si maa n ta wọn fawọn olubi eeyan to n lo ọmọ eeyan lati di ẹni pataki laye.
Ọkunrin yii lo maa n jokoo si idi okuta kankéré nla kan to wa nitosi ẹnu ọna abawọle keji si ileewe Fasiti Ibadan (UI), ti wọn n pe ni UI Second Gate, ti ko si si ẹni to yọ ọ lẹnu ri nitori gbogbo aye ro pe were ni, afi lalẹ ọjọ naa ti awọn araadugbo ọhun ri i to ko sinu aṣọ daradara kan bayii, ti aṣirii ẹ si tu nigba ti awọn to mọ ọn daadaa pe e nija, ṣugbọn to bẹrẹ si i bẹ wọn pe ki wọn jọwọ, daṣọ aṣiri bo oun.
Lẹyin ti wọn fi lilu da sẹria fun un ni wọn fa a le awọn ọlọpaa teṣan Sango, n’Ibadan lọwọ.
Ko ju wakati bii meloo kan lọ sigba naa, iyẹn laaarọ Ọjọruu, Wẹsidee, to kọja ni wọn tun ba obinrin kan ti oun naa mura bii were lọgangan ibi ti afurasi gbọmọgbọmọ to n dibọn bii were yii maa n jokoo si. Nigba ti ọwọ iya si ba oun paapaa lo jẹwọ pe ki wọn ṣe oun jẹẹjẹ, oun ki i ṣe were.
Olugbe adugbo ọhun kan ti iṣẹlẹ naa ṣoju ẹ, Akinọla Ọlabisi, sọ pe “kòtò kan wa labẹ okuta yẹn, ajaku ilẹkun onipako kan naa si wa nibẹ to maa n da bo koto yẹn lori. Nigba ta a pada lọọ wo ibi ti ọkunrin to n ṣe bii were yẹn maa n duro si la ba obinrin yẹn naa ninu koto yẹn ti oun naa mura bii were.
Ọgbẹni Ọlabisi tẹsiwaju pe nigba ti ọwọ iya ba ọkunrin yẹn lo jẹwọ pe oun ki i ṣe were, ọgbọn ti oun n da lati maa ri ọmọ ji gbe niyẹn. O ni ọ́mọ meje loun ti ri ji gbe lati igba ti oun ti n ṣe e, ọmọọleewe si ni gbogbo wọn.
O ni oogun loun fi maa n mu awọn ọmọ. Bi ọwọ oun ba si ti ba ọmọ kan loun yoo foonu awọn to ran oun niṣẹ, oun ko si mọ ibi ti wọn maa n gbe awọn ọmọ naa lọ lẹyin ti oun ba ti fa wọn le wọn (awọn ọga ẹ) lọwọ. Bẹẹ ni Tayọ sọ fakọroyin wa.
ALAROYE gbọ pe ọkan ninu awọn atẹranṣẹ ti wọn ba lori ẹrọ ibanisọrọ Sẹkinat fi han pe ẹnikan fi ẹgbẹrun lọna igba Naira (N200,000), ranṣẹ si i, o si ṣee ṣe ko jẹ ọkan ninu awọn to n ta awọn to n ji gbe fun lẹni naa, ati pe owo ẹmi eeyan to ji gbe ni wọn san fun un.
Bakan naa ni wọn tun ba aago ti wọn fi goolu ṣe ninu ẹru to wa ninu koto ti awọn ọbayejẹ eeyan yii n fara pamọ si. Lara nnkan ti wọn tun ba nibẹ ni risiiti ti wọn fi ra nnkan nileetura igbalode kan to wa laduugbo Sango, n’Ibadan, pẹlu awọn ike ti awọn onileetura ọhun maa n ta ounjẹ si fawọn onibaara wọn.
Nigba to n fidi iroyin yii mulẹ, agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, SP Adekunle Ajiṣebutu, sọ pe loootọ lawọn afurasi ọdaran meji kan, ọkunrin kan, obinrin kan wa, lahaamọ awọn ọlọpaa fun ẹsun ijinigbe, ṣugbọn ko si ẹri to fidi ẹ mulẹ pe ajinigbe ni wọn n ṣe.
O ni ninu iwadii awọn, awọn ọlọpaa ti ṣayẹwo fun awọn mejeeji, wọn si ri i pe ọlọdẹ ori ni wọn, ko si eyi to gbadun ninu wọn. SṢugbọn iwadii ṣi n tẹsiwaju lori awọn mejeeji.

(114)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.