Ọwọ ọlọpaa tẹ mọkanla ninu awọn tọọgi to dana sunle n’Ibadan

Spread the love

Nitori rogbodiyan to ṣẹlẹ laduugbo Idi-Arẹrẹ, n’Ibadan, ninu eyi ti awọn janduku ti dana sun ile rẹpẹtẹ ati ọpọlọpọ ṣọọbu, eeyan mọkanla lọwọ awọn ọlọpaa ti tẹ bayii.

 

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, SP Adekunle Ajiṣebutu, lo fidi eyi mulẹ nigba to pe sori eto ori redio aladaani kan n’Ibadan lati jẹ ki awọn araalu mọ ibi ti nnkan de duro lori iṣẹlẹ ọhun to waye loru ọjọ Abamẹta, Satide, mọju ọjọ Aiku, ọjọ Sannde ọhun.

 

Awọn dukia olowo iyebiye to ṣofo yii ko ṣẹyin ijamba ina to ṣẹlẹ latari ija igboro to waye laarin awọn ikọ awọn ọmọ iṣọta meji kan, eyi ti ọkan ninu wọn n jẹ One Million Boys, ti ikọ keji si jẹ akojọpọ awọn tọọgi lati awọn adugbo bii Oke-Ado, Kòsódò, Ọ̀rányàn, Aṣaka, ati bẹẹ bẹẹ lọ loru ọjọ buruku eṣu gbomi mu naa.

 

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, o tọjọ mẹta kan ti ija ọhun ti bẹrẹ, tọjọ Sannde yii kan jẹ ikọlu to waye latọwọ awọn ikọ keji lati gbẹsan lara awọn ikọ One Million Boys ni.

 

Lẹyin ti wọn ti fi ada ati apola igi ba awọn mọto ti wọn wa gunlẹ si oju titi Idi-Arẹrẹ si Ṣakapena jẹ lawọn ọmọ iṣọta naa tun ki ina bọ awọn ile to wa lẹgbẹẹ titi ibẹ, ati-ile ati-ṣọọbu to si jona guruguru ko din ni ogoji.

 

Boya nitori pe laarin oru niṣẹlẹ ọhun waye ni ko jẹ ka gbọ iroyin pe oku ku ninu iṣẹlẹ naa, ṣugbọn boya leeyan ti yoo farapa nibi ija yii yoo mọ ni meji mẹta bo tilẹ jẹ pe a ko ti i rẹni fidi eyi mulẹ.

 

Bakan naa lawọn olubi eeyan yii lo oore-ọfẹ asiko iṣẹlẹ yii lati ji ọpọlọpọ ọja ko ninu awọn ṣọọbu to wa lagbegbe naa. Diẹ ninu awọn ìsọ̀ ọhun lo si jẹ ibi ti wọn ti n ta awọn ohun eelo to n lo ina ninu ile, aṣọ, oogun oyinbo, nnkan tẹnu n jẹ loriṣiriṣii atawọn ṣọọbu mi-in ti wọn jẹ oniṣẹ ọwọ.

 

Olugbe adugbo Idi-Arẹrẹ kan ṣalaye fakọroyin wa pe, “nigba ti awọn tọọgi yẹn n dana sun awọn ile ati ṣọọbu, awọn eeyan pe awọn panapana ni Mọlete lati waa pa ina yẹn, ṣugbọn niṣe lawọn tọọgi yẹn tun duro sibẹ, wọn ni awọn maa wo baba nla ẹni to maa waa pana yẹn.

 

“Nigba ti awọn panapanna de, niṣe ni wọn doju ija kọ wọn, wọn ṣe ọkan ninu wọn leṣe. Ohun ti ko si jẹ ko ṣee ṣe fun awọn panapana lati ri ina yẹn pa niyẹn”.

 

Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, Ajiṣebutu ti i ṣe agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ sọ pe alaafia ti n jọba lawọn agbegbe ti rogbodiyan ọhun ti waye bayii, nitori lọgan ti iroyin iṣẹlẹ yii ti de si etiigboọ awọn agbofinro ni CP Abiọdun Odude ti i ṣe ọga agba awọn ọlọpaa ni ipinlẹ naa ti paṣẹ pe ki awọn agbofinro lọọ pana ija naa kiakia.

 

 

O fi kun un pe igbesẹ ti n lọ lọwọ lati gbe awọn mọkọọkanla tọwọ tẹ ọhun lọ sile-ẹjọ lẹyin ti awọn agbofinro ba pari iwadii wọn lori ọrọ yii.

 

Lati le ri i pe alaafia jọba nigboro ilu Ibadan ati agbegbe ẹ, Olubadan tilẹ Ibadan, Ọba Saliu Adetunji, (Aje Ogungunnusọ Kin-in-ni), paapaa ti ranṣẹ pe awọn Mọgaji to jẹ olori awọn agbegbe ti laasigbo ọhun ti waye fun ifikunlukun lori iṣẹlẹ naa.

Ni deede aago mejila ọjọ Iṣẹgun, Tusidee oni, nipade ọhun yoo waye. Awọn Mọgaji adugbo ti Ọba Adetunji ranṣẹ pe ni Mọgaji Ọja’gbo, Bẹyẹrunka, Labiran, Idi-Arẹrẹ si Asuni, Aṣaka, Isalẹ Osi, Oopo-Yeọsa ati Mọgaji Olorisa Oko nigboro Ibadan.

 

Ninu atẹjade ti agbenusọ fun ọba naa, Ọgbẹni Adeọla Ọlọkọ, fi ṣọwọ sawọn oniroyin lo ti sọ ọ di mimọ pe Olubadan lo pe ipade ọhun lati jọ jiroro lori ọna ti awọn aṣaaju agbegbe kọọkan nigboro Ibadan fi maa dena iru iṣẹlẹ bẹẹ lọjọ iwaju.

 

 

(9)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.