Ọrọ hijaabu ni ISI: Adajọ gba awọn obi ati akẹkọọ nimọran lati gba alaafia laaye

Spread the love

Adajọ ile-ẹjọ giga kan ni ipinlẹ Ọyọ, Onidaajọ Ọladiran Akintọla, ti rọ gbogbo awọn ti ọrọ ẹjọ to wa ni kootu lori ọrọ hijaabu lilo nileewe International School, Ibadan (ISI), lati ṣe suuru, ki wọn si jẹ ki alaafia jọba.

 

Arọwa yii waye lasiko ti igbẹjọ ọrọ hijaabu ọhun waye nile-ẹjọ naa to wa laduugbo Ring Road, n’Ibadan lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja.

 

Ta o ba gbagbe, lọjọ kejila, oṣu kọkanla, ọdun 2018 to kọja yii, lọrọ hijaabu lilo di wahala ni ISI, nigba ti diẹ ninu awọn akẹkọọ to jẹ musulumi nileewe to wa ninu ọgba Fasiti Ibadan naa wọ hijaabu lọ sileewe, tawọn obi wọn si tẹle wọn debẹ lati ṣatilẹyin fun wọn, eyi ti ko dun mọ awọn alaṣẹ ISI ninu, to si mu ki wọn ti ileewe naa pa ko too di pe wọn ṣi i pada lẹyin ọsẹ kan.

 

Awọn obi awọn akẹkọọ to jẹ Musulumi ni wọn gbe ọrọ yii lọ si kootu, wọn ni ki ile-ẹjọ paṣẹ fun awọn adari ISI lati fun awọn ọmọ awọn lanfaani lati maa bori lọ sileewe ni ibamu pẹlu ilana ẹsin awọn, ṣugbọn ti awon alaṣẹ ileewe naa ti wọn jẹ olujẹjọ ninu ẹjọ naa n tako o ni kootu, wọn ni ori bibo ko si ninu ilana imura awọn akẹkọọ nileewe awọn.

 

Nigba to n rọ awọn ti ọrọ kan lori ẹjọ naa, eyi to bẹrẹ ninu oṣu kejila, ọdun to kọja yii, lati gba alaafia laye, Onidaajọ Akintọla ṣalaye pe o ṣe pataki fun wọn lati ri ara wọn gẹgẹ bii ọmọ iya kan naa.

 

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “gbogbo wa gbọdọ ri ara wa bii nnkan kan naa, nitori eeyan jọ ni gbogbo wa, Ọlọrun kan naa lo si da wa. Nigba ta a jọ jẹ eeyan ni kaluku wa too yan ẹsin to wu u, yala Musulumi, Kirisitẹni tabi ẹlẹsin yoowu ta a baa jẹ. Oju ọmọ eeyan ti gbogbo wa jọ jẹ yẹn lo yẹ ka fi maa ba ara wa ṣaṣepọ pẹlu ifẹ, ki alaafia le maa jọba lawujọ wa.”

 

Awọn ẹlẹsin abalaye to lọmọ ni ISI ti rọ ile-ẹjọ lati gba awọn naa laye lati jẹ ọkan ninu awọn ti yoo le sọ tẹnu tiwọn naa lori ọrọ to wa nilẹ yii, ti ile-ẹjọ si gba bẹẹ fun wọn.

 

Ṣaaju lagbẹjọro awọn ISI to jẹ olujẹjọ lori ẹjọ yii, Amofin-agba Babatunji Ajibade, ti rọ ile-ẹjọ lati faaye gba gbogbo awọn to ba fifẹ han lati da si ọrọ ẹjọ yii lati le jẹ ki idajọ ododo waye.

 

Ṣugbon agbẹjọro awọn olupẹjọ, Amofin-agba Wahab Ẹgbẹjọbi, ti waa rọ adajọ lati parọwa fun ẹni gbogbo ti ọrọ ẹjọ yii ba kan lati mu akọsilẹ awijare wọn wa lọjọkọjọ ti igbẹjọ yoo ba tun waye lati dena fifi akoko ṣofo.

 

 

Nigba to n sun igbẹjọ ọhun si Ọjọruu, Wẹsidee, ogunjọ, oṣu keji, ọdun 2019 yii, Onidaajọ Akintọla rọ tọtun tosi awọn agbẹjọro naa lati ṣakọsile ohun ti gbogbo wọn ba fẹ wa si kootu lọjọ ti igbẹjọ yoo naa yoo tun waye, ki wọn si ri i daju pe ọna ti alaafia yoo gba jọba lo wa lookan aya onikaluku wọn.

 

 

(3)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.