Ọlọkada jẹ gbese, lo ba binu para ẹ n’Ibadan

Spread the love

Iyalẹnu lo jẹ fawọn olugbe adugbo Gangansi, lọna Alakia, n’Ibadan, pẹlu bi ọlọkada kan to n jẹ Abass ṣe mọ-ọn-mọ gbẹmi ara ẹ, niṣe lo pokunso sinu yara ẹ.
Awọn alabaagbe ẹ ninu ile naa ni wọn ri oku ẹ laaarọ ọjọ keji, iyẹn Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja, nibi to so ara ẹ kọ si loke aja ni yara, ti wọn si kegbajare pe awọn araadugbo.
Nibi ti wọn ti n wo oku ẹ tiyanutiyanu, ti wọn si n ronu ohun to le fa ki baba to to ẹni aadọta ọdun yii ṣeku para ẹ ni wọn ti ri idahun si ibeere naa. Wọn ri alaye ti Abass funra ẹ ṣe sinu iwe pelebe kan to fi si ẹgbẹ ibi to pokunso si.
Ohun to kọ sinu iwe ọhun ni pe ki ẹnikẹni ma ṣe da ara ẹ laamu nipa iku oun, awọn ti oun jẹ ni gbese ti pọ ju, eyi lo mu ki oun pinnu lati fi iku gba ara oun silẹ lọwọ ẹsin to ṣee ṣe ki awọn olowo oun fi oun ṣe nile aye.
Awọn alabaagbe Abass ninu ile ọhun fidi ẹ mulẹ pe ni nnkan bii aago meje aabọ Ọjọru, Wẹsidee, to kọja, lọkunrin naa ti ti ibi iṣẹ de, to si wọ inu yara ẹ lọ bii ẹni to fẹẹ lọọ sun lai mọ pe o ti ni in lọkan lati para ẹ sinu ile.
Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, bo tilẹ jẹ pe baba ọlọkada yii niyawo, to si ṣabiyamọ lọkunrin ati lobinrin, sibẹ, oun nikan lo n da gbe, ẹgbọn ẹ lo si kọ ile ọhun.
Ọsan Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja la gbọ pe awọn agbofinro lọọ ja oku ọkunrin naa lulẹ, ko too di pe awọn mọlẹbi ẹ ṣeto bi wọn ṣe sin in.
Awọn to sọrọ nipa oloogbe naa ṣapejuwe ẹ gẹgẹ bii eeyan jẹẹjẹ. Wọn ni idi to ṣe waa para ẹ nitori gbese to jẹ ko gba ibi kankan ye awọn.

(9)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.