Ọlaoluwa jale n’Ibadan, ṣọọsi to n lọ naa lo ti ko wọn lẹru lọ

Spread the love

Bi wọ ba n sọ pe a ki i ja Ọlọrun lole, aṣipa owe leyi loju ọdọmọkunrin ẹni ọdun mẹtalelogun (23) kan, Ọlaoluwa Ọlaide, ẹni to ja ilẹkun ṣọọsi wọle n’Ibadan, to si ko pupọ ninu awọn ẹru ti wọn fi n jọsin nibẹ lọ.

Ileejọsin ọhun ti wọ n pe ni Jesus Christ of Latter Day Saint Church, to wa laduugbo Adegbayi, n’Ibadan, ni afurasi ole yii funra rẹ n lọ.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, o pẹ ti Ọlaoluwa ti n jale bẹẹ, ṣugbọn to n jọla Oluwa ṣaa pẹlu bi ọwọ ẹnikẹni ko ṣe ba a lati ọjọ yii wa. Afi lalẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, to lọ lọhun-un, nigba ti Ọlaoluwa ja Oluwa funra rẹ lole, ti Ọlọrun si fi i fun awọn agbofinro mu

Iwadii awọn ọlọpaa gẹgẹ bi ọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Aiọdun Odude, ṣe sọ fawọn oniroyin fidi ẹ mulẹ pe niṣe lỌlaoluwa ja ilẹkun ṣọọṣi ọhun wọle, to si ji awọn dukia ijọsin yii lọ raurau.

Ṣugbọn nibi to ti n giyanju lati ta awọn ẹru naa ni ẹnikan to da awọn dukia ṣọọsi ọhun mọ ti ka a mọ, to si yara lọọ ta awọn ọlọpaa lolobo. Afurasi ole yii ko si ti i kuro nibẹ ti awọn ọlọpaa fi kan an lara.

Diẹ ninu ẹru to ji ko ni ẹrọ amunawa ọnda nla kan, oriṣii ẹrọ kọmputa meji, ẹrọ itẹwe kan, ẹrọ agbohunsoke (maikirofoonu), ti ko lokun nidii kan ati ọpọlọpọ nnkan mi-in eyi ti diẹ ninu wọn jẹ tawọn ọmọ ijọ kan nileejọsin naa.

Lẹyin ti Ọlaoluwa ti jẹwọ ẹṣẹ, to si bẹbẹ pe ki ileeṣẹ ọlọpaa ṣiju aanu wo oun, CP Odude ti sọ pe ọwọ adajọ lafurasi ọdaran yii ti le ri oju aanu gba. O ni ni kete ti awọn ọlọpaa ba ti pari iwadii wọn lori ẹsun ole ti wọn tori ẹ mu un sọ satimọle lawọn yoo gbe e lọ si kootu.

(21)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.