Ọkọ mi na mi pẹlu oyun ninu, o tun lu emi pẹlu ọmọ lẹyin- Nikẹ

Spread the love

Bi ile ọkọ ẹni ba kọ ni, ile baba ẹni a si gba ni. Ọrọ ko ri bẹẹ fun obinrin yadirẹsa kan, Nikẹ Sanusi, ẹni to sa lọ sile baba ẹ lẹyin ti ọkọ re lu u jade nile, ṣugbọn tawọn obi ẹ tun le e pada sibi to ti wa.

Nigba ti iya pa obinrin naa lori ti ẹmi ẹ si ti n bọ lọ lo gba kootu lọ, o ni kile-ẹjọ fopin si igbeyawo ọdun mẹrinla ti ko fi oun lọkan balẹ rara naa.

Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye nile ẹjọ, “Gbogbo igba lọkọ mi maa n na mi. Nigba ti mo wa ninu oyun ọmọ wa ẹlẹẹkẹta, o na mi lọjọ to ku ọjọ mẹẹẹdogun ti mo maa bimọ. Nigba ti mo bimọ yẹn tan, mo gbe e pọn sẹyin lọjọ kan, ọkọ mi tun na mi tọmọtọmọ lẹyin ti ọmọ yẹn pe ọmọ ọjọ mkọkanlelogoji (41). To ba n na mi bayii, yoo ri i daju pe oun mú ẹjẹ lara mi.

“Bo ṣe maa n na mi naa lo maa n gbe mi ṣepe. Niṣe lo n gbe mi ṣepe lọjọ ti wọn le ọmọ wa wale lati ileewe nitori pe a ko ri owo sukuu rẹ san.

“Oluwa mi, ẹmi mi ti fẹẹ pin, ẹyin nikan lẹ si le gbẹmi mi la. Mo fẹ kẹ ẹ tu wa ka. Ọkọ mi ti le mi jade nile ri ti mo sa lọọ ba awọn obi mi, ṣugbọn ti wọn tun da mi pada sibẹ, wọn ni gbogbo ohun ti oju obinrin ba n ri nile ọkọ lo gbọdọ maa fara dà.’’

Ọkọ Nikẹ, Haruna, jẹwọ pe loootọ loun maa n na iyawo oun, ṣugbọn ẹẹmeji pere loun lu u lati igba ti oun ti gbe e sile, oun ko si deede lu u bi ko ṣe nitori iwa palapala to kun ọwọ ẹ bamubamu.

Olujẹjọ paapaa sọ pe oun paapaa faramọ ki ile ẹjọ tu igbeyawo awọn ka nitori ohun buburu aye gbogbo lo pe si obinrin naa lara tan, o fẹran owo ju bo ṣe yẹ lọ, o n yan ale, o n jale, ko nifẹẹ oun, bẹẹ lẹru iyawo oun n ba oun pe ko ma lọọ fi majele sinu ounjẹ oun lọjọ kan.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, ‘Kò-sówó-kò-sífẹ̀ẹ́, làṣà ti iyawo mi maa n da lojoojumọ. Ti mo ba fun un lowo ileewe awọn ọmọ, nina lo maa n na an. O yọ ṣeeni goolu lọrun mi, o fi panda rọpo ẹ.

“O tun maa n jale bo ṣe wa yii, mi o le sọ iye igba to ti ji owo mi ninu ile. Mi o si mọ nnkan to n fi gbogbo owo ọhun ṣe, ẹẹmẹta lo jẹ awọn ajọ ayanilowo ni gbese to jẹ pe emi ni mo ba a san an.

“Iṣẹ ọdẹ ni mo n ṣe. Ti mo ba wa lẹnu iṣẹ alẹ, iyawo mi aa jade nile bo ṣe wu u lai sọ fun mi, aa waa purọ fun awọn ọmọ pe iṣọ oru loun n lọ. Ọmọ mi sọ fun mi lọjọ kan pe iya oun lọ oogun oorun sinu ounjẹ fun mi ki n baa le sun daadaa. Boya nitori ko le raaye lọ sọdọ ale rẹ nigba ti mo ba sun tan lo ṣe maa n fi oogun ourun sinu ounjẹ fun mi.”

Igbimọ awọn adajọ kootu Ọja’ba to wa ni Mapo, n’Ibadan, ti fopin si igbeyawo ọlọdun mẹrinla ọhun. Oloye Ọdunlade Ademọla paṣe fun olujẹjọ lati maa san ẹgbẹrun mẹwaa Naira loṣooṣu gẹgẹ bii owo ounjẹ awọn ọmọ meejeji ti wọn bi funra wọn. Ko si maa sanwo ileewe pẹlu eto ilera wọn loorekoore.

Olujẹjọ sọ pe oun ko lagbara lati maa sanwo naa nitori ẹgbẹrun mẹẹẹdogun pere loun n gba nibi iṣẹ loṣu, ṣugbọn ile-ẹjọ sọ pe dandan ni lati ṣan owo jijẹ mimu awọn ọmọ to bi.

(29)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.