Ọkọ iyawo ku ni igbeyawo ku ọla

Spread the love

Ajalu nla lo ṣẹlẹ si idile Babalọla, niluu Ogbomọṣọ, pẹlu bi ọmọ wọn, Damilare Babalọla, ṣe fo ṣanlẹ, to ku, lọjọ ti igbeyawo ẹ ku ọla.

Ọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii lo yẹ ki Damilare ṣe igbeyawo ibilẹ pẹlu afẹsọna ẹ, ki won too ṣe igbeyawo ṣọọṣi lọjọ Satide ijẹta, ṣugbọn ti iku pa ọkọ iyawo oju ọna naa lẹyin ijamba ọkọ to ni nirọlẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, eyi to sọ ọ dero ẹsẹ kan aye ẹsẹ kan ọrun.

 

Gẹgẹ bi ẹbi oloogbe ọhun kan ṣe fidi ẹ mulẹ, ọmọkunrin ọhun to ti n wo ajule ọrun lọọọkan tẹlẹ lo gbadun l’Ọjọruu, Wẹsidee, ti inu awọn ololufẹ ẹ si ti n dun, ṣugbọn to tun pada j’Ọlọrun nipe l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ keji, nileewosan ti wọn ti n tọju ẹ lasiko ti oun, afẹsọna rẹ ati idile awọn mejeeji ti n wo igbeyawo alarinrin ti wọn n gbero naa lọọọkan, ti ariya ọhun ko si ju wakati diẹ lọ mọ.

 

ALAROYE gbọ pe lati ilu Eko lọkọ ni ọkunrin to je ọmọ bibi ilu Ogbomọṣọ naa ti n pada siluu ẹ ti ijamba ọhun fi waye.

 

Damilare lo ti gboye keji ninu imọ ẹrọ nileewe imọ ẹrọ Ladoke Akintọla (LAUTECH), to wa niluu Ogbomọṣọ.

 

Ọjọ Jimọh to yẹ ko ṣegbeyawo ni wọn sinku ẹ gẹgẹ bi ọkan ninu awọn idile oloogbe ṣe fidi ẹ mulẹ.

 

Titi dasiko ti iroyin yii jade nidile ọkọ ati iyawo oju ọna ṣi wa ninu ọfọ, nitori gbogbo eto ni wọn ti fẹẹ pari tan fun igbeyawo ọhun ko too di pe ọkọ iyawo ku.

 

 

 

 

 

 

(22)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.