Ọjọgbọn gba awọn akẹkọọ-gboye nimọran lati ma ṣe maa waṣẹ kiri

Spread the love

Alaga igbimọ alakooso ileeewe gbogboniṣe, The Polytechnic, Ibadan, Ọjọgbọn Isaac Adebayọ Adeyẹmi ti rọ awọn akẹkọọ to ṣẹṣẹ kẹkọọ jade nileewe naa lati ma ṣe maa waṣẹ lọ sibikibi.

 

Nibi ayẹyẹ ikẹkọọ-gboye alakanpọ awọn akẹkọọ Poli Ibadan, eyi to jẹ ẹlẹẹkejilelọgbọn (32), ati ẹẹkẹtalelọgbọn (33), iru ẹ to waye ni papa iṣere nla ileewe naa lọjọ Ẹti, (Furaidee), to kọja lo ti sọrọ yii.

 

Adeyẹmi sọ pe nnkan bii miliọnu mẹfa ọdọ lorileede yii ni wọn n fẹsẹ̀ gbálẹ̀ kiri igboro, nitori naa, o san ki awọn to ṣẹṣẹ kẹkọọ gboye ọhun funra wọn ronu ohun ti wọn maa ṣe ti yoo maa mowo wa fun wọn dipo ki awọn naa tun lọọ darapọ mọ awọn to n waṣẹ nigboro lọ.

 

O ṣalaye pe “lara ẹkọ ta a kọ yin nileewe yii ni lati maa lo ọpọlọ ati ọwọ́ yin. Iwọnyi lẹ ni lati maa lo deede titi ti ẹyin paapaa yoo fi di ẹni to n gba awọn eeyan siṣẹ dipo ẹni to n waṣẹ.”

 

Nigba to n ṣapejuwe Poli Ibadan gẹgẹ bii ileewe to ta awọn ileewe giga ẹgbẹ ẹ ti wọn jọ jẹ tijọba ipinlẹ kaakiri orileede yii yọ, ọga agba ileewe ọhun, Ọjọgbọn Ọlatunde Fawọle, rọ awọn akẹkọọ naa lati maa fi iwa rere wọn tubọ gbe ogo ileewe ọhun yọ.

 

Ẹgbẹrun marundinlọgọrun-un-o-le-mọkandinlaaadọta (9,549), lo kẹkọọ gboye nileewe ọhun gẹgẹ bi Fawọle ṣe fidi ẹ mulẹ. Pupọ ninu wọn lo gboye ọjẹ wẹwẹ (ND) nigba ti awọn yooku gboye agba ọjẹ (HND).

 

Ayẹyẹ ikẹkọọ-gboye ko waye ni Poli Ibadan lati ọdun mẹta sẹyin. Eyi lo mu ki wọn ṣe tọdun yii lalakanpọ. Awọn to ti jade nileewe ọhun laarin ọdun 2015 si 2016, atawọn to paari laarin ọdun 2016 si 2017 ni wọn si ṣe e fun.

 

Igbakeji gomina ipinlẹ Ọyọ, Ọtunba Moses Alake Adeyẹmọ, gboṣuba fun awọn alaṣẹ ileewe yii fun bi wọn ṣe n ta awọn ẹgbẹ wọn yọ jakejado orileede yii, bẹẹ lo  tun jẹjẹẹ atilẹyin ijọba fun wọn.

 

 

(4)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.